O ṣẹlẹ, ọba alaye meji wọ ara wọn lọ si kootu ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Sisin fiimu bii aṣa awọn oloyinbo ti ko ṣee wo tan ni ọrọ awuyewuye ija ilẹ to n lọ lọwọ nile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ilọrin, laarin Ẹlẹ́jù, tilu Ẹ̀jù, Ọba Mathew Idowu Ajiboye, ati Ọlọ́bà ti Ìsàlẹ̀-Ọ̀bà, Ọba Alaaji Maroof Afọlayan Adebayọ, da bayii pẹlu bi fọnran fidio ṣe ṣafihan bi awọn olupẹjọ, Ọba Ajiboye, ṣe ran awọn janduku ki wọn maa lu Ọlọ́bà, ti wọn si n yẹyẹ rẹ lasiko ti adajọ ni oun fẹẹ wo fọnran fidio ọhun.

Ninu fọnran fidio naa ni awọn janduku ti lọọ ka Ọlọ́bà atawọn alatilẹyin rẹ mọle, ti wọn si bẹrẹ si i pariwo, wọn n lu u, lori ẹsun pe oun lo wa nidii rogbodiyan to n waye ninu ilu.

ALAROYE gbọ pe niluu Ẹ̀jù kan naa ni awọn mejeeji wa tẹlẹ, ṣugbọn nigba to ya ni awọn Ọlọ́bà ya kuro lara Ẹ̀jù, ti wọn si n jẹ Ọlọ́bà ti Ìsàlẹ̀-Ọba, leyii ti wọn ni awọn ti da duro, ti wọn si ni ọba tiwọn.

Ohun ti a gbọ pe o ṣokunfa awuyewuye ọhun ni pe Ẹlẹ́jù tilu Ẹ̀jù, Ọba Matthew Idowu Ajiboye, ta ilẹ baba awọn Ọlọ́ba, to si ni ọba oun ba lori ohun gbogbo. Ṣugbọn awọn Ọlọ́ba yari pe awọn ki i ṣe ara Ẹ̀jù mọ, ni wahala ba bẹrẹ.

Ọba Ajiboye, wọ Ọlọ́bà lọ sile-ẹjọ, ṣugbọn ẹri fidio tu aṣiri bi Ọba Ẹ̀jù ṣe ni ki wọn maa lu Alaaji Maroof Afọlayan to jẹ Ọlọ́bà, ti wọn si fa a laṣọ ya, leyii ti wọn ni o ta ko ofin ilẹ wa.

Bakan naa ni fidio tun ṣe afihan bi wọn ṣe ni ki olori ẹbi ile-Ọlọ́bà, iyẹn Rahmọn Ọmọniyi, dọbalẹ pẹlu tipatipa, ti wọn si n ṣọrọ buruku si i.

Lẹyin ti wọn wo fidio ọhun tan ni Onidaajọ Muhammad Adams, gba fidio naa wọle gẹgẹ bii ẹri, o sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.

Leave a Reply