Nijọ wo la fẹẹ bọ ninu idaamu epo bẹntiroolu nilẹ yii na!
Eelo ni wọn n ta bẹntiroolu, epo mọto bayii o. Boya ọgọjọ naira ni lita kan, bọya naira mọkanlelọgọjọ ni o, ko sẹni to le sọ pato. Bi ẹnikẹni ba sọ pe ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria bayii ye oun, tọhun yoo jẹ oloṣelu, tabi ẹnikan to fẹran lati maa tan ara rẹ jẹ. Lojoojumọ lohun gbogbo n dorikodo: bi o yiju sibi yii, ọran; bi o yiju sọhun-un, ijangbọn ni. Gbogbo ohun tijọba yii ṣeleri pata lo fọ yanga loju wa bayii, gbogbo ohun ti wọn ni awọn yoo ṣe ni wọn ko ṣe, eyi ti wọn si ni awọn yoo tun ṣe, wọn tubọ n ba a jẹ si i ni. Bo ba jẹ ileri ti awọn araabi yii ṣe ni, ko yẹ ka wa nibi kan ki epo bẹntiroolu maa jẹ wa niya, tabi ki owo ti wọn yoo maa ta a ni Naijiria wọn ju iye ti wọn n ta a nibomi-in lọ. Nigba to jẹ awa la ṣe e, ọdọ wa ni wọn ti n wa a, bawo ni epo yoo ṣe wọn lọdọ wa. Ṣugbọn ohun to n ya gbogbo aye lẹnu ni pe awa ọmọ Naijiria ti a wa ninu awọn orilẹ-ede ti a ni epo bẹntiroolu ju lọ lagbaaye, awa naa ni iya kinni naa n jẹ ju lọ. Nigba tiijọba yii n bọ, lara ileri ti wọn ṣe ni pe iya kinni naa ko ni i jẹ wa mọ, bẹẹ ni ki i ṣe pe a oo maa ri epo naa ra kaakiri kọ, owo ti yoo jẹ ko ni i jẹ inira fun wa. Nigba ti wọn n sọrọ yii, iye ti wọn n ta epo yii jẹ naira mẹtadinlaaadọrun-un (N87), ṣugbọn bi a ti n sọrọ yii, owo epo naa ti fẹẹ bọ si ilọpo meji, nitori bii naira mejilelọgbọn (N162) ni wọn n ta a lawọn ibi kan. Ki lo le fa iru eleyii! Ko si ohun to n fa a ju iwa awọn aṣaaju wa lọ, iwa ti Aarẹ Muhammadu Buhari leri pe oun yoo parẹ, ṣugbọn to jẹ bo ṣe de tan, niṣe ni iwa naa n buru si i. Ko si bi epo ko ṣee ni i wọn ni Naijiria. Nigba to ṣe pe bo tilẹ jẹ awa la n wa a lati inu ilẹ, nigba ti a ba wa a tan, ilu oyinbo ni a oo gbe e lọ lati fọ ọ, awọn oyinbo ti wọn ba fọ epo naa ni wọn yoo ṣẹṣẹ gbe e pada wa fun wa, ti wọn yoo si ta a ni ibamu si iye ti wọn ba n ra dọla lagbaaye. Ki lo de ti Naijiria ko le fọ epo ti awọn ọmọ Naijiria yoo lo, ti wọn yoo si tun ri i ta sẹyin odi! Ko si ohun to fa a ju iwa ibajẹ, ikowojẹ ti iru rẹ ko si nibi kan laye yii mọ, ati iwa imọtara-ẹni-nikan to ṣoro gan-an lati gbagbọ pe awọn ẹda kan yoo ni iru rẹ. Ki i ṣe pe a ko ni ileeṣẹ to n fọ epo bẹntiroolu, ṣugbọn eyi ti awọn ijọba ologun aye Yakubu Gowon ati tawọn ṣọja mi-in ti ṣe naa lo wa nibẹ, lọdọọdun ni wọn si n tun un ṣe, ti atunṣe naa ko gbeṣẹ. Nidii eyi ni wọn ṣe fawọn kan ni lansẹnsi pe ki wọn maa ra epo bẹntiroolu wa lati oke-okun, ọwọ awọn yii si ni agbara wa, awọn ni wọn n ṣe wa bo ṣe wu wọn, nitori awọn ijọba wa fun wọn ni agbara ti ko tọ si wọn. Ko si orilẹ-ede mi-in ti wọn ti n ṣe eyi, ti Naijiria nikan ni. Ki Buhari too de si ilu yii bii olori wa tuntun, ọpọ alaye lo ṣe nipa ọrọ owo-epo yii, eyi to fi han pe oun naa mọ bi nnkan ti n lọ, ṣugbọn iyanu buruku lo jẹ pe latigba to ti de, kaka ki ewe agbọn dẹ lọrọ naa, koko lo n le. Awọn ti wọn n ko owo jẹ, awọn ti wọn n gba owo ijọba lai taja fun wọn, awọn ti wọn n gba owo-epo bẹntiroolu ti wọn ko gbe wọle ati awọn eeyan raurau bẹẹ lo n ba nnkan jẹ, eyi to si buru ju ni pe bi wọn ti wa ninu awọn ijọba to kọja lọ, bẹẹ ni wọn pọ ninu ijọba Buhari yii bii nnkan. Koda ti ijọba Buhari yii fẹrẹ le ju tawọn ti wọn ti wa tẹlẹ lọ. Ibeere ni pe kin ni Buhari n ṣe fawọn ti wọn n ko owo epo jẹ! Lọjọ wo ni Buhari fẹẹ pese ile-ifọpo ti wọn yoo ti maa fọ epo ti yoo to gbogbo ọmọ Naijiria i lo gẹgẹ bo ti ṣeleri nigba to fẹẹ gbajọba. Lọjọ wo ni Buhari yoo mu nnkan dẹrun fawọn ọmọ Naijiria, awọn ohun to n ṣẹlẹ yii ko daa o!
Ẹyin funra yin lẹ oo pa Buhari
Awọn oponu kan wa nilẹ yii, awọn ọlọpọlọ kukuru, alaimọkan. Loju tiwọn, awọn lawọn n gbeja Buhari, tabi pe awọn lawọn n ṣe ẹgbẹ oṣelu APC, bi wọn ko ba si mura, awọn funra wọn ni wọn yoo pa Buhari. Nigba ti ijọba ba wa, ko si ohun to dara bii ki awọn ti wọn ba sun mọ awọn olori wọn ba wọn sọ ootọ ọrọ. Gbogbo ẹnikẹni to ba sun mọ olori ijọba ti ko le ba a sọrọ, iru awọn bẹẹ yoo pada pa olori orilẹ-ede bẹẹ ni, bi wọn ko ba pa a sọrun, wọn yoo pa a saye. Ohun to ṣe ni laaanu ni pe awọn ti wọn n tẹle Buhari, paapaa, ọpọ awọn eeyan ti wọn wa ninu APC, ki i ba baba naa sọ ootọ ọrọ, koda, ko maa wọ inu igbo lọ, ko si maa gbe gbogbo ọmọ Naijiria wọbẹ lọ. Wọn yoo sọ pe ohun to n ṣe lo dara ju lọ, ati pe awọn ko ri iru eeyan daadaa, to si kun oju oṣuwọn bẹẹ ri laye awọn. Bẹẹ ohun to n ṣẹlẹ yii ko daa, awọn naa si mọ. Boya oṣelu ni wọn wa n ṣe ni o, boya ọrọ ẹsin lo si bo wọn loju, boya aigbọn si ni, ko sẹni to mọ rara. Ti ọrọ owo-epo yii tilẹ baayan ninu jẹ, nitori awọn kan ti jade pe bi awọn ijọba agbaye ti n ṣe ni Buhari ṣe, lati jẹ ki awọn kan maa diye le owo-epo naa bo ba ṣe wu wọn. Awọn yii ko ranti sọ fun awọn eeyan pe awọn ijọba orilẹ-ede aye ti wọn n mẹnuba yii yoo ti ri i pe owo-oṣu awọn eeyan awọn ba iye ti wọn yoo maa ra epo mọto mu. Wọn ko jẹ fi owo kun owo-epo lẹẹmẹta lẹẹmẹrin laarin ọdun diẹ, to si jẹ owo-oṣu wọn ko le kọbọ kan si i. Awọn ko jẹ fi biliọnu mẹwaa tun ileeṣe-ifọpo ṣe laarin ọdun kan ki ileeṣẹ ifọpo naa ma si fọ epo koroba kan ṣoṣo bayii gẹgẹ bi ileeṣẹ NNPC ti n ṣe. Awọn ko ni i fi titi wọn silẹ lai ṣe, wọn ko si ni i fi ọsibitu wọn silẹ lai le tọju alaisan, wọn yoo ti ṣe ohun gbogbo letoleto ki wọn too fi owo kun owo-epo wọn. Gbogbo ohun to yẹ ki ijọba Buhari ṣe ni wọn fi silẹ ti wọn ko ṣe, eyi lo si jẹ ko jẹ nigbakigba ti wọn ba ni awọn fi kun owo-epo bayii, inira to n ba gbogbo ilu ki i ṣe kekere. Ki waa ni awọn kan jokoo ti wọn n kan saara si ijọba to n ni mẹkunnu lara si, kin ni wọn n ri jẹ ninu ijọba yii to bẹẹ ti laakaye wọn fi parẹ mọ wọn ninu! Tabi ọpọlọ wọn ko pe tẹlẹtẹlẹ ni. O ma ṣe o. Ẹ ba Buhari sọ ootọ ọrọ, ijọba rẹ n ni ilu lara; ẹ ba a sọ ootọ ọrọ, ko ma jẹ funra yin lẹ oo pa baba naa saye!
Ẹ ma tun jẹ kawọn dokita daṣẹ silẹ o
Awọn oṣiṣẹ ijọba gbogbo n leri bayii, wọn ni awọn yoo daṣẹ silẹ nitori ohun ti ijọba n ṣe lori ọrọ owo-epo bẹnitiroolu, wọn ni gbogbo eyi ti wọn n ṣe yii, awọn ni iya rẹ yoo jẹ ju lọ. Nigba ti owo-epo ba ti lọ soke, o daju pe owo mọto yoo lọ soke si i, bẹẹ ni owo ọja gbogbo yoo lọ soke, nigba ti owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ko si le, inira yoo pọ fun wọn, nitori owo wọn ko ni i too na mọ. Awọn ẹgbẹ awọn olukọ fasiti naa ni awọn paapaa ko fara mọ ọn, awọn naa si le bẹrẹ iyanṣelodi tawọn naa. Gbogbo awọn wọnyi lo ṣee fi ewe mọ, bi awọn oṣiṣẹ ba daṣẹ silẹ, ti awọn olukọ fasiti naa daṣẹ silẹ, lori ijokoo naa lawọn eeyan yoo ti yanju ẹ, ti kaluku yoo si pada sẹnu iṣẹ wọn. Eyi ti ko dara ko ṣẹlẹ ni ti awọn dokita o. Ohun yoowu to ba fa ibinu, ti gbogbo dokita ilẹ yii fi leri pe awọn yoo da iṣẹ silẹ, ki ijọba tete yanju ẹ ni, ki wọn fi igberaga, ko-kan-wa, tabi ohun yoowu ti wọn ba n ṣe silẹ, ki wọn gbaju mọ ti awọn dokita yii, ki wọn si ri i pe awọn fori ẹ ti sibi kan. Ohun to ṣe gbọdọ ri bẹẹ ni pe ọwọ awọn eeyan yii ni eto alaafia gbogbo araalu wa, bi ko ba si si alaafia, ko sẹni to le ṣe ohunkohun. Ẹni to ba ni alaafia ni i ṣejọba, ẹni to ba ni alaafia ni i lọ sibi iṣẹ, ẹni to ba si ni alaafia naa ni i da iṣẹ silẹ. Bi ohun gbogbo ba fẹẹ lọ deede, ti ijọba yoo si fi ifẹ gidi han si gbogbo araalu, afi ki wọn ri i pe awọn dokita yii ko da iṣẹ silẹ, nitori idaṣẹ silẹ wọn lewu ju tẹlomi-in lọ. Ẹ ma jẹ ki wọn daṣẹ silẹ o, ẹ yaa tete pe wọn pada.
Ẹ gbọ ẹjo buruku ti Ghana ro mọ wọn lẹsẹ
Ko si ohun ti eeyan le ṣe, iwa to ba ti mọ-ọn-yan lara, koda, ki tọhun lọ si igberi okun, ko tun de igberi ọsa, iwa naa ni yoo maa hu nibẹ, ko si sohun teeyan le ri ṣe si i. Ijọba Naijiria lawọn n binu si ijọba ilẹ Ghana, ni wọn ba binu rangbọnda, ni Lai Muhammed ti i ṣe minisita fun eto iroyin ba gbe iwe aramanda kan lati fi kilọ fun ijọba ilẹ Ghana, o ni wọn n gun Naijiria garagara, bi wọn ko ba si jawọ, wọn yoo ri pipọn oju ijọba awọn. Ohun meji ni ijọba Naijiria n tori ẹ binu si wọn ni Ghana, akọkọ ni pe wọn wo ile to n ṣoju ijọba Naijiria ni Ghana. Naijiria lo kọ ile naa, nibẹ ni wọn si n lo bii ileeṣẹ to n ṣoju wọn. Lojiji lawọn kan wo ile naa ni bii oṣu meji sẹyin, ọrọ naa ka Naijiria lara. Lọna keji, ijọba Ghana ni ki awọn oniṣowo ọmọ Naijiria to ba wa ni Ghana san miliọnu kan owo dọla ti Ghana ki wọn too le maa ba iṣẹ wọn lọ nibẹ, bi bẹẹ kọ, awọn yoo ti ṣọọbu wọn pa. Iru ẹgbin wo lo ta le wa yii! Ohun tijọba Naijiria n wi ree, ni wọn ṣe kọwe ibinu si Ghana. Ṣugbọn ijọba ilẹ Ghana ko binu, suuru ni wọn fi ṣe alaye fun wọn. Wọn ni ile ti wọn sọ pe wọn wo yii, awọn kọ lawọn wo o, nitori ijọba Naijiria ko beere ilẹ lọwọ awọn, awọn ko si fun wọn nilẹ, ọwọ awọn ọmọ onilẹ ni wọn ti lọọ rẹnti ilẹ wọn, wọn ko si fọrọ naa to ijọba leti. Adehun ti wọn jọ ṣe pẹlu awọn ọmọ onilẹ ni pe wọn yoo lo ilẹ naa fun ọdun mẹwaa pere, wọn yoo si maa sanwo fun wọn. Bii ogoji ọdun sẹyin ni adehun naa ti pari, ijọba Naijiria ko san owo fun awọn onilẹ ti wọn gba ilẹ lọwọ ẹ, wọn ko si kuro lori ilẹ, ohun to si fa ija laarin awọn ati awọn ọmọ onilẹ niyi, ko si ohun to kan ijọba Ghana. Ṣe iru ẹ ṣee gbọ! Pe Naijiria lọ si ilu oniluu, wọn ralẹ nibẹ, wọn ko san rẹnti mọ fun ogoji ọdun, onilẹ wole wọn, wọn bẹrẹ si i pariwo. Ni gbogbo aye, ijọba orilẹ-ede kan ni yoo fun ijọba orilẹ-ede mi-in ni aaye ti wọn yoo kọle wọn si nibẹ, orilẹ-ede kan ko ni i ra ilẹ lọwọ aladaani, afi ti Naijiria yii nikan. Ni ti awọn ti wọn fẹẹ gbowo lọwọ wọn, wọn ni awọn ṣe bẹẹ nitori ọpọlọpọ awọn ti wọn wa ni Ghana ti wọn jẹ ọmọ Naijiria yii, iṣẹ buruku ni wọn n ṣe, iwa ọdaran ni wọn n hu, awọn si ti sọ ọ laimọye igba fun ijọba Naijiria, ṣugbọn to jẹ ti awọn ba ti wa laimọye igba, ẹni to yẹ ko da awọn lohun ko ni i da awọn lohun, nigbẹyin, wọn yoo dẹ ọmọ kekere lẹnu iṣẹ ọba kan si awọn, gbogbo ẹjọ ti awọn ba si fi sun, ibẹ ni yoo pari si, ijọba Naijiria ko ni i ṣe nnkan kan. Ghana ni o ya awọn lẹnu pe ijọba wa le maa binu bayii lori ọrọ ti awọn ti sọ titi ti wọn ko da awọn lohun lẹẹkan. Ninu gbogbo ohun to wa nilẹ yii, iṣe ile lo ru Naijiria deta yii, ohun ti wọn n ṣe nile naa ni wọn lọọ ṣe nita. Nigba to jẹ ọwọ awọn agbero ọmọ onilẹ ni gbogbo eeyan ti n ralẹ, to si jẹ bo o lọọ fẹjọ sunjọba, o ko ni i ri eeyan gidi ba sọrọ, afi ẹni ti owo ba wa lọwọ ẹ, ohun to gbe wọn de Ghana ree, iyẹn naa lo si sọ Naijiria di ẹni abuku loju aye. Gẹgẹ bii iṣe wọn, wọn ko tun le wadii ọrọ ki wọn too maa kọwe ibinu, iyẹn ni Ghana ṣe fi wọn wọlẹ ni gbangba ode. Nigba wo lawọn ijọba tiwa ni Naijiria yoo ṣe ohun ti gbogbo aye n ṣe! Abi bi nnkan wa yoo ṣe maa lọ naa niyi ni! Ta ni yoo ba wa tun ilẹ yii ṣe! Eleyii ma waa ga o!