O ṣẹlẹ, adajọ ni ki wọn lọọ mu ọga ọlọpaa patapata ju satimọle

Faith Adebọla

Aparo kan o ga’ju kan lọ, afeyi to ba gori ebe, adajọ ile-ẹjọ giga kan to n ri si ọrọ ajọṣe ileeṣẹ atawọn oṣiṣẹ, eyi to fikalẹ siluu Abuja, Onidaajọ Oyebiọla Oyewunmi, ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa lọọ fi pampẹ ofin gbe ọga wọn agba patapata, IGP Usman Alkali Baba, ati igbakeji rẹ to jẹ akọwe ileeṣẹ ọlọpaa apapọ, AIG Hafeez Inuwa, o ni ki wọn sọ awọn mejeeji si gbaga titi tile-ẹjọ yoo fi peroda lori ọrọ wọn.

Adajọ paṣẹ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa yii, nigba tawọn ọlọpaa kan tileeṣẹ naa fẹyin wọn ti ni tipatipa, amọ ti kootu ṣedajọ pe ifẹyinti kan-n-pa ti wọn fawọn agbofinro yii ko tọna pẹẹ, ko si bofin mu, wọn ni ki wọn gba wọn pada sinu iṣẹ ọlọpaa ti wọn wa tẹlẹ, kileeṣẹ ọlọpaa si san gbogbo owo-oṣu wọn latigba ti wọn ti yọ wọn niṣẹ.

Ile-ẹjọ lawọn o ri aburu kan tawọn olupẹjọ yii ṣe, ileewe lati le mu imọ ati oye wọn nidii iṣẹ ọlọpaa pọ si i ni wọn lọ, ewo waa ni ti gbigbaṣẹ lọwọ ẹni lọna abaadi yii, wọn ni aṣa ọhun ko bofin mu rara.

Amọ kaka ki ileeṣẹ ọlọpaa mu aṣẹ ile-ẹjọ yii ṣẹ, wọn ko ṣe bẹẹ. Eyi lo mu kawọn olupẹjọ naa, nipasẹ lọọya wọn, tun kọri sile-ẹjọ ohun laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa yii, lati lọọ fẹjọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa sun.

Ifisun yii lo bi Onidaajọ Abilekọ Oyewumi ninu, to fi wo o pe ko sẹni to ga ju ofin lọ, ko si sẹni ti ko le dero ẹwọn ti tọhun ba ti tẹ ofin loju, n ladajọ naa ba paṣẹ pe ki wọn lọọ gbe ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ati igbakeji rẹ ọhun sọ satimọle, tori iwa irufin ni fẹnikẹni lati mọ aṣẹ ile-ẹjọ loju, o ni aika idajọ si lo jẹ pẹlu bi wọn ṣe kọ lati ṣẹtọ pẹlu awọn olupẹjọ naa.

Leave a Reply