Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Igbadun iṣẹju diẹ ti ran gbajugbaja babalawo kan, Fadayọmi Kẹhinde, ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ejiogbe, n’Ikẹrẹ-Ekiti lọ sọrun ọsan ganagan, o si ti gba ibi to gba wa saye lọ sọrun pẹlu bo ṣe pade iku ojiji lẹyin to ṣe tibitibi pẹlu ale rẹ to gbe lọ si oteẹli kan niluu naa.
Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye fun akọroyin wa pe ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji yii ni oun ati ọrẹbinrin rẹ ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ wọ inu ile itura naa lọ lati lọọ ṣe ere ifẹ. Ohun to buru ninu ọrọ yii ni pe wọn ni iyawo ojiṣẹ Ọlọrun kan ni obinrin ti babalawo naa n yan lale to gbe lọ sotẹẹli to fi pade iku ojiji yii.
ALAROYE gbọ pe o ti to bii ọdun meji sẹyin ti babalawo ati iyawo pasitọ yii ti n mu nnkan funra wọn. Ẹni kan to n gbe
niluu naa sọ pe okunrin yii jẹ Ọlọrun nipe lẹyin to ṣe ere ifẹ pẹlu obinrin ti wọn ti le ni magun yii tan.
A gbọ pe bi obinrin yii ṣe ri i pe babalawo naa ti ṣubu lulẹ, to si daku lọ rangbanjan lo pariwo. Ariwo yii ni manija ileetura naa gbọ to fi sare pe awọn eeyan ti wọn wa nitosi lati waa wo ohun to ṣẹlẹ, ti wọn sì gbe ọkunrin yii digba-digba lọ si ileewosan kan.
Nigba to n sọrọ lori ìṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe loootọ loun ti gbọ nípa iṣẹlẹ naa. O fi kun un pe iwadii ti bẹrẹ, o sì ṣeleri pe awọn ọlọpaa yoo ri okodoro iku to pa babalawo naa.
Bakan naa ni Alukoro yii sọ pe obinrin ọhun ti wa ni atimọle, wọn si ti gbe oku okunrin naa lọ si ile igbokuu-pamọ si titi ti iwadii yoo fi pari lori ọrọ naa.
ALAROYE gbọ pe awọn ọdọ ilu ti fi ibinu dana sun ṣọọṣi ọkọ obinrin yii.