O ṣẹlẹ, ile-ẹjọ sọ ọga ọlọpaa patapata sẹwọn oṣu mẹta

Faith Adebọla, Eko

Aṣe loootọ lọrọ ti wọn maa n sọ pe ko sẹni ti ida ofin o le ṣa, amọ lọtẹ yii, olori agbofinro ni pampẹ ofin mu, ile-ẹjọ giga ijọba apapọ kan niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, ti da ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, IG Usman Alkali Baba, lẹbi, wọn ni ki wọn gba kaki ọlọpaa lọrun ẹ, ki wọn paarọ ẹ si aṣọ awọn ẹlẹwọn, ko si lọọ faṣọ penpe roko ọba foṣu mẹta.

Adajọ M. O. Ọlajuwọn lo gbe idajọ agbọ-ṣe-haa ọhun kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii, ẹsun ti wọn ka si ọga ọlọpaa naa lọrun to fi rẹwọn he ni pe o kọti ọgbọyin si idajọ ile-ẹjọ ọhun, eyi ti wọn gbe kalẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa apapọ ilẹ wa lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2011, iyẹn ọdun mọkanla sẹyin.

Ohun to tun yaa-yan lẹnu ninu ẹjọ ọhun ni pe, adiẹ n jẹfun ara wọn, ọlọpaa ti wọn ti fẹyin ẹ ti ni tipatipa kan, Ọgbẹni Patrick Okoli, lo pẹjọ naa, oun lo wọ ileeṣẹ ọlọpaa ati ọga wọn patapata re kootu, latari ẹsun pe iwa aigbatẹniro ati aiṣedajọ-ododo ni bi wọn ṣe gbaṣọ ọlọpaa lọrun oun lori ẹsun toun ko jẹbi ẹ, ti wọn kọkọ ni koun lọọ rọọkun nile na, to si jẹ lẹyin naa, riri toun maa ri i ni pe wọn gbaṣẹ ọlọpaa lọwọ oun ni tulaasi, wọn fun oun ni ifẹyinti kan-n-pa.

Ẹjọ yii nile-ẹjọ naa gbọ, ti wọn si ṣedajọ lori lọdun mọkanla sẹyin, ifa idajọ naa si fọre fun olupẹjọ yii, wọn da ileeṣẹ ọlọpaa lẹbi, wọn ni ki wọn yaa fawe ti wọn fi yọ Patrick niṣẹ lọran-an-yan ya loju-ẹsẹ, ki wọn jẹ ko maa ṣiṣẹ ẹ lọ.

Wọn tun ni kileeṣẹ ọlọpaa san miliọnu mẹwaa Naira (N10 million) fun un gẹgẹ bii owo gba-ma-binu fun abuku ti wọn ti fi kan an, tori bi wọn ṣe lawọn yọ ọ niṣẹ ti ta epo saṣọ ala olupẹjọ naa, bẹẹ ni wọn ti ko inira ba oun atawọn mọlẹbi ni gbogbo asiko ti ariyanjiyan naa fi n lọ, tori ọdun 1993 ni wọn ti gbaṣẹ lọwọ ọkunrin naa lọna aitọ.

Idajọ yii nile-ẹjọ naa lawọn ọlọpaa kọti ikun si latọjọ yii, bẹẹ ki i ṣe pe wọn o ri iwe aṣẹ tile-ẹjọ pa, bẹẹ ni ko si ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan ni kootu, ọdun si ti gori ọdun, sibẹ ti olupẹjọ ọhun ko r’ẹjẹ ko r’omira.

Eyi lo mu ki kootu naa gbe idajọ mi-in kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, Adajọ Ọlajuwọn ni ẹnikan o ga kọja ibawi, ofin o si mọ ẹni-ọwọ, o ni ki wọn lọọ mu ọga patapata ileeṣẹ ọlọpaa to wa nibẹ lọwọlọwọ, ki wọn la a mọ gbaga foṣu mẹta na, bi wọn ba ṣiṣẹ lori aṣẹ ile-ẹjọ naa koṣu mẹta yii too pe, wọn le tu u silẹ, amọ to ba ṣi jẹ pe bakan naa lọmọ ṣe ori toṣu mẹta akọkọ fi pe, ki wọn jẹ ko maa ṣẹwọn ẹ niṣo niyẹn.

Bẹẹ ni Alkali Baba, ọga agba patapata fimu kata ofin o.

Leave a Reply