O ṣẹlẹ! Nitori gbese owo mọto, Portable sa fawọn ọlọpaa, lo ba fo geeti sa lọ

Jọkẹ Amọri

Afi ki gbogbo awọn ọrẹ, alatilẹyin, ololufẹ ati ojulumọ ọmọkunrin olorin to maa n pe ara rẹ ni idaamu adugbo nni, Habib Okikiọla Ọlalọmi, ti gbogbo eeyan mọ si Portable maa ba a dupẹ o, diẹ bayii lo ku ki Portable fi ‘baba ọmọ ẹ’, iyẹ ‘kinni’ abẹ ẹ gun irin nibi to ti n sa lọ fawọn ọlọpaa to fẹẹ mu un lọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Ọgbọọgbọn ti agbalagba fi n sa fun maaluu ni Portable fi fẹgbẹẹgbẹ rin bii alakan, to si sa mọ awọn agbofinro to waa fọwọ ofin mun un lati ile-ẹjọ giga lọwọ.

ALAROYE gbọ pe mọto bọginni, Mercedes alawọ dudu, ti i ṣe ọkan lara awọn mọto asiko towo rẹ jẹ miliọnu lọna mẹtadinlọgbọn Naira (27,000,000), ni Portable ra lawin pẹlu ileri ati ọrọ ajọsọ, to kọ sinu iwe nipa bi yoo ṣe sanwo mọto tan lẹẹmẹrin. Ṣugbọn ọmọkunrin olorin naa ko mu adehun to ṣe ṣẹ.

Ọga ileeṣẹ mọtọ naa, Ọgbẹni Ogunsanwo Temitọpẹ, ti ileeṣẹ Temmy Autos to fohun ranṣẹ si Portable lori bi ko ṣe siika adehun yii sọ pe, “Habeeb, Habeeb, Habeeb, mo nigbagbọ pe mo ti ṣe suuru to fun ẹ to o Portable. Mo mọ pe mo ti ṣe suuru to fun ẹ. Oriṣiriṣii nnkan ni mo n bo fun ẹ kawọn nnkan kan ma baa le bọ sita, amọ ibi ti mo wa nisinyii, o ti sun mi de ogiri. O ti sun mi de ogiri o.

“Mi o ta mọto awin o, mi o dẹ duro de owo to o ba pa lawọn ode ti wọn ba ti pe ẹ ni elere lati sanwo mọto o. Mọto to wa lọwọ ẹ nisinyii, o mọ iye ti wọn n ta a bayii bayii o. O mọ’ye ti wọn n ta mọto yẹn bayii o. O da bii pe nnkan ti n ba dẹ fi mọ nisinyii ni mo fi maa gbowo mi. Boya ijọba lo maa ba mi gbowo mi, boya awọn ọmọ Naijiria ni o, wọn maa ba mi gba a tabi ki n gba mọto mi.

“Tori o ni adehun ti a jọ ṣe, nitori ẹni to ni mọto ti fẹrẹ fun ile aye mi pa, o ti to akoko ti n maa lọọ sọ fun un pe mọto rẹ lo wa lọwọ ẹ yẹn o. Haa ha haaa, o wa gbowo mi sọwọ”.

Bayii ni ọkunrin naa sọ ninu ohun to ka ranṣẹ si Portable.

Ninu iwe adehun ti wọn jọ tọwọ bọ lasiko ti Portable fẹẹ ra mọto naa lo ti kọ ọ sibẹ bayii pe,”Emi Badmus Okikiọla Habeeb ti wọn n pe ni Portable, ti mo n gbe ni Odogwu bar, Oke Osa, Sango Ilogbo, nijọba ibilẹ Ado-odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, n tọwọ bọwe adehun yii, pe mo ra ọkọ bọginni Mercedes Benz GLE 35, alawọ dudu, pẹlu nọmba iforukọsilẹ 4JDA5HB6GA656575, ni ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgbọn miliọnu Naira (27 million), leyii ti mo ṣeleri lati kọkọ san owo asansilẹ miliọnu mejila Naira ni ọla, ọjọ kẹwaa, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

“Ma a san miliọnu marun-un Naira ni igba keji, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii. Ma a tun san miliọnu marun-un nigba kẹta, lọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun yii. Miliọnu marun-un yooku gbọdọ jẹ sisan lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ọdun yii. Apapọ gbogbo eyi ti o jẹ miliọnu lọna mẹtadinlọgbọn Naira, ti emi Badmus Okikiọla Habeeb, to n jẹ Portable fara mọ pe ọkọ naa duroo re fun mi.

“Ti n ba kuna lati fara mọ gbogbo ajọsọ wa yii, tabi ti n ba kuna lati sanwo gẹgẹ bi a ṣe ti la a kalẹ yii, Ọgbẹni Ogunsanwo Temitọpẹ, ti ileeṣẹ Temmy Autos, to wa ni 15, Adesanya Street, Ẹpẹtẹdo, Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, ni aṣẹ lati gba ọkọ Mercedes Benz GLE pada lọwọ emi Badmus Okikiọla Habeeb, ti mo tun n jẹ Portable, lai da owo kankan pada fun mi.

Mo fara mọ ọn, bẹẹ ni mo gba gbogbo ohun to wa ninu iwe adehun ti mo kọ yii, lonii ọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024”.

Ṣugbọn Portable ko san owo rẹ to ku, niṣe lo si n sa fun ọkunrin to ta mọto fun un yii.

Ibinu eyi lo mu ki dila naa gba kootu lọ, to si fẹjọ sun nibẹ pe ki ile-ẹjọ ba oun gba owo oun lọwọ Portable. N ni kootu ba fun awọn oṣiṣẹ kootu niwee pe ki wọn lọọ gbe Portable wa.

Aṣọ alapa gigun to ni ila dudu ati funfun kan bayii ni Portable wọ sori sokoto kan, to si de fila alawamọti funfun si i. Bawọn oṣiṣẹ kootu pẹlu ọlọpaa ṣe ka a mọ kọna nibi ile kan ni wọn ni, ‘‘Portable, iwọ la waa mu, iwe aṣẹ ti kootu si fun wa lati mu ẹ niyi’’.

Ni oṣere yii ba bẹrẹ si i pooyi bii ṣia baaba, bo ṣe n lọ lo n bọ, to si n sọ pe, ‘Mọto naa ni eleyii, mọto naa niyi, mọto naa niyẹn. Gbogbo bo ba ṣe jẹ, mo maa ku sibi loni’. Bẹẹ lo n sọ fawọn ọlọpaa to waa mu un pe oun n bọ, nigba ti awọn yẹn ni awọn waa mu un.

Afi bo ṣe fẹyin rin lọ sibi ẹyinkule geeti kan to wa nitosi ibi ti wọn ti n ba a sọrọ, ki awọn to wa nibẹ si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọmọkunrin olorin ti ẹnu ki i sin lara rẹ naa ti bẹ gija bii ologbo sori geeti giga kan to wa nibi ti wọn ti n ba a sọrọ, n ni ẹlẹgiri ba ta kọsọ si odi-keji. Ọlọrun lo si yọ ọmọ Ọlalọmi ti baba ọmọ rẹ ko gun irin geeti, nitori to ba ṣẹlẹ bẹẹ ni, ọtọ ni ohun ti a ba maa wi bayii. Afi bii fiimu agbelewo ni ọrọ naa ri fun gbogbo awọn to wa nibẹ, to fi mọ awọn ọlọpaa to waa mu un. Ohun ti awọn kan si n wi ni pe aṣe Portable ko tiẹ le, ẹnu lo ni bii ti ajakara.

Ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni Portable gbe aworan mọto rẹ tuntun yii soju opo Instagram rẹ, lẹyin to fi eyi to n lo tẹlẹ lasidẹnti. Gẹgẹ bi ohun to kọ si abẹ fọto to gbe sori Instagram yii, owo ọwọ ara ẹ lo ni oun fi ra a, ki i ṣe pe wọn bun oun tabi pe oun ya a lo.

O ni, “Ilẹkun kan ti, mẹta mi-in ṣi. Owo mi ni mo fi ra eleyii o. Ọlọrun Ọba nla ti tun ṣe e lẹẹkan si i. Ọpẹlọpẹ Ọlọrun, ọta o ba yọ mi, ori lo yọ mi. Tony montana, ika to n lo benz. Ika gbogbo Afrika, oore-ọfẹ to pọ, ti ki i doju ti ni”.

Tẹ o ba gbagbe, lẹyin ti mọto olowo nla to ra nijamba mọto lo lọọ ra mọto naa, pẹlu ileri pe oun yoo sanwo rẹ diẹdiẹ fun ẹni to ra a lọwọ rẹ, ṣugbọn ti ọmọkunrin olorin naa ko mu adehun rẹ ṣe. Titi di ba a ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to mọ ibi ti ọfẹ gbe ọmọ Ọlalọmi lọ titi di ba a ṣe n sọ yii.

Bi Portable yoo yọju si kootu bi ko ni i yọju, ko sẹni to ti i le sọ

 

Leave a Reply