O ṣẹlẹ, Ọlayiwọla dẹ aja si ọlọpaa to fẹẹ mu un, lo ba bu u jẹ yankanyankan

 Jamiu Abayọmi

L’ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, foju ọkunrin  ẹni ọgbọn ọdun kan, Gabriel Ọlayiwọla, to n gbe l’Ojule kejidinlogun, Odogbolu, lagbegbe Princess Abiọla, ba ile-ẹjọ Majisireti kan to fikalẹ si agbegbe Yaba, nipinlẹ naa, lori ẹsun pe o tu aja nla rẹ kan ti wọn n pe ni German Shepherd, silẹ lati le ọlọpaa kan, ASP Ọyagbọla Jẹlili, to fẹẹ wa mu un nilẹ rẹ lori ẹjọ rẹ ti wọn lọọ fi sun ni teṣan ọlọpaa lagbegbe Ikọtun Egbe, nipinlẹ naa, ti aja naa si papa ge ọlọpaa naa jẹ lapa ọtun, eyi to si da apa nla ati irora si agbofinro naa lara.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, alajọgbele ọkunrin naa lo lọọ fọrọ rẹ sun ni teṣan ọlọpaa pe o ba ọkọ ti owo rẹ n lọ bii miliọnu mẹta Naira oun jẹ, ṣugbọn lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii, tawọn agbofinro lọ silẹ rẹ lati lọọ mu un fun iwa ọdaran to hu naa, niṣe lo mọ-ọn-mọ dẹ aja si ọfiisa ọhun.

Ẹsun mẹta ọtọọtọ ni wọn fi wọ ọ dewaju Onidaajọ O.Y. Adefọpẹ. Akọkọ ni pe o huwa ọdaran, ẹẹkeji ni pe o ba dukia onidukia jẹ. Paripari rẹ si ni pe o dunkooko mọ ẹmi ọmọniyan, leyi tofin ipinlẹ Eko ko fara mọ.

Lẹyin ti wọn ka ẹsun naa tan ni ọlọpaa olupẹjọ, Haruna Magaji sọ fun ile-ẹjọ pe awọn ẹṣẹ ti olujẹjọ ṣẹ yii lo tako ofin iwa ọdaran ipinlẹ naa t’ọdun 2015 to si ni ijiya to lowura ninu.

Nigba ti wọn beere lọwọ olujẹjọ boya o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an tabi ko jẹbi, o ni oun ko jẹbi. O waa rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe ki wọn ṣiju aanu wo oun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ O.Y. Adefọpẹ, ni Gabriel Ọlayiwọla  jẹbi awọn ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan an, ṣugbọn o faaye beeli ẹgbẹrun-un lọna ẹẹdẹgbeta Naira (N500,000) silẹ fun un pẹlu oniduuro meji ni iye kan naa.

Adajọ wa a sun igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

Leave a Reply