Adewale Adeoye
Ileewosan kan to wa niluu Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, ni wọn gbe oku gende kan, Oloogbe Ojibe Chibueze, ẹni ọdun mẹtadinlogun, to gbẹmi ara ẹ nitori to ṣe ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (N100,000) owo ọga rẹ baṣubaṣu.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹta yii, ni oloogbe naa to n kọṣẹ ọwọ lagbegbe Abijo, niluu Ẹpẹ, ro o pin lẹyin ti ko le ri owo ọga rẹ da pada, lo ba gbe majele jẹ, to si ku loju-ẹsẹ
ALAROYE gbọ pe ọdọ ẹgbọn rẹ kan ni oloogbe naa n gbe. Lọjọ iṣẹ̀ẹ ọhun, niṣe lo sare wọnu ile lati ita, to si mu owo rẹ nibi to n tọju rẹ si lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu yii, to si tun jade lẹsẹkẹsẹ. Ṣugbọn ariwo gee lẹgbọn rẹ, Omidan Cynthia, gbọ lati ita pe aburo rẹ ti ku si bọsitọọbu Abijo lẹyin to gbe majele jẹ tan. Nigba tawọn araale fi maa tẹle ẹgbọn oloogbe yii debi ti aburo rẹ ku si, igo ohun mimu kan ti wọn gbagbọ pe majele ni ni wọn ba lẹgbẹẹ rẹ, ti oloogbe naa si ti n po ọṣẹ lẹnu gidi.
Cynthia ti i ṣe ẹgbọn oloogbe lo sọ fawọn ọlọpaa pe oun gba ipe pajawiri kan latọdọ ọga oloogbe naa pe aburo oun, Ọloogbe Chibueze jẹ oun ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira, toun ko si ri i ko wa si ṣọọbu mọ.
Igbagbọ awọn eeyan ọhun ni pe oloogbe naa gbe majele jẹ ni, niwọn igba ti ko mọ ọna to maa gba lati san gbese to jẹ ọga rẹ pada. Awọn ọlọpaa agbegbe naa ti wọn pe lori iṣẹlẹ yii ni wọn pada gbe oku oloogbe naa lọ si mọṣuari kan to wa nileewosan ijọba niluu Ẹpẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Eko, S.P Benjamin Hundeyin, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun yii, pe Cynthia ti i ṣe ẹgbọn oloogbe naa lo pe awọn ọlọpaa lori foonu nipa iṣẹlẹ ọhun, tawọn ọlọpaa si ti lọọ wo ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe naa. O fi kun un pe awọn maa too bẹrẹ iwadi nipa iṣẹlẹ ọhun.