Jamiu Abayọmi
Ọwọ ikọ ọdẹ ibilẹ ati fijilante adugbo Gateway Junction, lagbegbe Ada George, niluu Port Harcourt, ipinlẹ Rivers, ti tẹ ọmọkunrin kan, Favour Chucks, to jẹ ọmọ DPO ọlọpaa kan lagbegbe naa pẹlu baagi nla kan to kun fun igbo laṣaalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Nigba to n fidi isẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin Ọjọruu, Wẹsidee, l’ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ to ṣẹṣẹ pari yii, lọga agba ajọ fijilante adugbo naa, Mathew Iheanyi, ṣalaye pe owuyẹ kan lo ta awọn oṣiṣẹ awọn lolobo, tawon fi tọpasẹ ọmọkunrin naa debi to ti fẹẹ wọ Kẹkẹ Maruwa ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa.
Ọkunrin naa lawọn ba ọmọ ọga ọlọpaa naa pẹlu baagi kan to ṣe pe igbo lo kun inu rẹ, toun gan-an si n fagbo ọhun lọwọ lasiko tawọn fọwọ ofin gba a mu, o lawọn si ti fa a le ọlọpaa teṣan Kala, nipinlẹ naa lọwọ.
O ṣalaye pe, “Ọmọkunrin ti ẹ n wo lẹgbẹẹ mi yii la mu nibi to ti fẹẹ wọ kẹkẹ Maruwa, pẹlu ẹru igbo rẹpẹtẹ to di sinu baagi rẹ, ohun to daju si ni pe o wa lara awọn to n ṣowo igbo nipinlẹ Rivers yii. Ọmọ DPO ọlọpaa to ṣi wa lẹnu iṣẹ ni, koda o n mu igbo na lọwọ lasiko ta fi mu un ni.
“Bawo la ṣe fẹẹ jẹ ki iru ẹni ibi bayii maa rin yan fanda lawujọ, gbogbo ẹni ti ko ba fẹ ki ipinlẹ yii ni alaafia lawa naa ko ni i jẹ ki wọn gbadun”.
Ọmọkunrin naa jẹwọ pe loootọ loun n mu igbo, ṣugbọn ẹru igbo ti wọn ba ninu baagi ọwọ oun ki ṣe toun, oun kan ba eeyan kan gbe e dani ni kawọn fijilantẹ naa too wa mu oun.