Monisọla Saka
Ajọ to n ri si ọrọ kaadi idanimọ lorilẹ-ede yii, National Identity Management Commission (NIMC), ti kede pe dandan ni kawọn ọmọ Naijiria sanwo lati gba kaadi idanimọ lati isinyii lọ, nitori ko sowo lapo ijọba mọ.
Wọn ni gẹgẹ bi owo ko ṣe wọle deede sapo ijọba Aarẹ Bọla Tinubu mọ, afi kawọn ọmọ Naijiria ti wọn ba fẹẹ gba kaadi tuntun to wulo fun gbogbo nnkan yii sanwo ẹ.
Peter Iwegbu, ti i ṣe adari ẹka ti wọn ti n ṣe kaadi pelebe ọhun nileeṣẹ NIMC, lo sọrọ yii di mimọ lasiko ipade ọlọjọ meji ti wọn ṣe pẹlu awọn oniroyin l’Ekoo.
O ni pataki idi ti awọn eeyan yoo fi maa sanwo ni lati ri i daju pe awọn to nilo rẹ ni wọn n ṣe e fun.
Iwegbu ni ọna lati ma ṣe awọn aṣiṣe tawọn ti ṣe sẹyin lo fa a tawọn fi gbe igbesẹ yii. Nitori ọpọlọpọ lawọn ṣe lọfẹẹ latẹyinwa, ṣugbọn tawọn eeyan ki i waa gba a.
O ni o le ni miliọnu meji kaadi tawọn tẹ kalẹ lati le fun awọn eeyan lọfẹẹ, ṣugbọn ti pupọ wọn ko gba a titi doni.
“Owo ti ko wọle daadaa sapo ijọba gan-an lo pọ ju ninu idi ta a fi pinnu pe kawọn ọmọ Naijiria maa sanwo lati gba kaadi wọn tuntun”.
Iwegbu fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ko lowo ti wọn le gbe kalẹ fawọn lati maa tẹ ẹ mọ, nitori bi owo to n wọle funjọba ko ṣe to nnkan.
Lanre Yusuf, toun naa jẹ adari lẹka eto imọ ẹrọ nileeṣẹ NIMC, ṣalaye pe ọrọ kawọn eeyan waa maa gba kaadi idanimọ orilẹ-ede yii lọfẹẹ lofo tawọn n ṣe tẹlẹ ko yọri si rere.
O ni iru kaadi tuntun tawọn ṣẹṣẹ fẹẹ bẹrẹ yii, eeyan gbọdọ ti nilo rẹ ko too le beere fun un.
“Lati gba kaadi NIN tuntun yii, awọn ọmọ Naijiria maa kọkọ sanwo ni, wọn yoo si mu aaye tabi agbegbe ti wọn ba ti fẹẹ lọọ mu kaadi wọn, ti wọn yoo si gba a ni adirẹsi ti wọn ba fẹ lati gba a.
“Ijọba ti ṣagbekalẹ awọn eto ti yoo mu kawọn mẹkunnu ti wọn ko lagbara lati gba a, ṣugbọn ti wọn nilo rẹ lati beere fun iranlọwọ ijọba.
“Eto yii n ṣafihan erongba ijọba lati ri i pe gbogbo eeyan, lai wo ti ipo ti wọn wa, ni wọn n ri anfaani wọn jẹ”.
Yusuf ni laipẹ yii ni kaadi ti yoo wulo fun gbogbo nnkan teeyan ba fẹẹ lo o fun, eyi ti wọn n pe ni (Multipurpose Card) yii, yoo bẹrẹ, ati pe eyi tawọn fi n ṣayẹwo rẹ wo ti wa nilẹ tawọn eeyan ti gba.
O fi kun ọrọ rẹ pe ajọ NIMC ti fọwọsowọpọ pẹlu awọn ileefowopamọ, kawọn ọmọ Naijiria le beere fun kaadi wọn, ki wọn si gba a ni ẹka banki yoowu, ki o le rọrun fun wọn.