Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn agbofinro ko Wolii kan, Adebayọ Festus, ati ọmọ ‘yahoo’ kan tawọn eeyan mọ si Ọlafusi, tọwọ tẹ lọsẹ to kọja lori ọrọ akẹkọọ Adeyẹmi kan, Wẹnnuọla Iluyọmade, ti wọn ni wọn fẹẹ fi ṣoogun owo lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ fun ifọrọwanilẹnuwo.
ALAROYE gbọ pe ọmọbinrin ti wọn fẹẹ lo ọhun, Wẹnnuọla Iluyọmade, ni wọn lo wa nipele keji nile-iwe olukọni agba Adeyẹmi, to wa niluu Ondo. Lati nnkan bii ọdun diẹ sẹyin ni wọn ni ọrọ ifẹ ti wa laarin oun ati Ọlafusi. Ọdun to kọja lọmọbinrin yii deede dubulẹ aisan, awọn nnkan ajeji kan ni wọn lo n jade lati oju ara rẹ nigba naa.
Oriṣiiriṣii ile-iwosan ni wọn ti gbe e lọ, koda, ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn ni wọn ti ṣiṣẹ abẹ fun un nile-iwosan pajawiri to wa loju ọna Laje, niluu Ondo, ṣugbọn ti ko si iyatọ.
Lẹyin-o-rẹyin ni wọn ni akẹkọọ naa ṣẹṣẹ jẹwọ fawọn obi rẹ pe Ọlafusi to jẹ ọrẹkunrin oun lo mu paadi toun fi n ṣe nnkan oṣu, eyi to lọọ fun Wolii Festus ninu oṣu kejila, ọdun to kọja.
Loju ẹsẹ ni Aposteli Iluyọmade Festus to jẹ baba Wẹnnuọla, ti lọọ fẹjọ Wolii Festus ati onibaara rẹ sun ni teṣan ọlọpaa to wa ni Ẹnuọwa, niluu Ondo. Awọn agbofinro wa awọn mejeeji ri, wọn si fi pampẹ ọba gbe wọn.
Ọkan ninu awọn ẹbi akẹkọọ ọhun to ba ALAROYE sọrọ ni awọn mejeeji ko fi akoko ṣofo rara ti wọn fi jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ ni awọn fẹẹ fi paadi nnkan oṣu naa ṣoogun.
Abilekọ yii ni agba wolii kan lo gba awọn nimọran lati lọọ ṣayẹwo fun ọmọbinrin naa, leyii to gbe awọn de ileewosan aladaani kan ti akọroyin wa ti lọọ ba wọn.
ALAROYE gbọ pe Wolii Adebayọ ti ṣeleri pe oun ṣetan lati tọju ọmọbinrin naa ni kete ti esi ayẹwo naa ba ti jade.
Wọn ti ko awọn afurasi naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ ta a wa yii, fun ifọrọwanilẹnuwo.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni loootọ lawọn mejeeji tọwọ tẹ ti wa lọdọ awọn, bakan naa lo ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.