O ṣi ku ọdun mẹrin kipo aarẹ too le kuro nilẹ Hausa – Awọn aṣofin APC Ariwa

Faith Adebọla

Agbarijọ awọn ọmọleegbimọ aṣofin lawọn ipinlẹ to wa lagbegbe Ariwa/Ila-Oorun ilẹ wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC (All Progressive Congress) ti kede pe ko ti i to asiko ti ipo aarẹ yoo kuro ni agbegbe Ariwa ilẹ wa, tori o ṣi ku ọdun mẹrin si i ti agbegbe naa yoo fi ṣakoso.

Latari eyi, awọn aṣofin naa ti rọ awọn ẹgbẹ oṣelu lati ṣeto ti yoo mu ki ondije fun ipo aarẹ lọdun 2023 jade lati iha Ariwa nikan, wọn lawọn o ni i faramọ eto tabi ẹgbẹ oṣelu to ba fa aarẹ kalẹ lati agbegbe mi-in yatọ si Ariwa.

Ọrọ yii wa ninu atẹjade kan ti Alaga ẹgbẹ awọn aṣofin naa (Conference of Nigeria State Legislature, North-East zone) lati ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Gombe, Alaaji Sadique Ibrahim, buwọ lu lẹyin ipade kan tawọn adari ileegbimọ aṣofin naa ṣe niluu Bauchi, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Atẹjade naa ka lapa kan pe: “A ti ṣakiyesi ọpọ awuyewuye to n lọ nilẹ wa lori eto idibo to n bọ lọdun 2023, a si ti jiroro lori rẹ.

“Ọdun mẹrinla ni ipo aarẹ ti fi wa ni agbegbe Guusu ilẹ wa. Ti Buhari ba fi maa pari ijọba rẹ lọdun to n bọ ni yoo di ọdun kẹwaa ti ipo aarẹ ti wa ni agbegbe Ariwa, tori naa, o ṣi ku ọdun mẹrin si i ti ipo aarẹ yoo fi wa ni agbegbe ariwa, ko too lọ si agbegbe mi-in. Eyi nikan lo le mu alaafia wa, ti ko si ni i si ojooro ninu pinpin ipo aarẹ ilẹ wa.

“A nifẹẹ si iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari,  a si gboṣuba fun igbimọ kiateka ẹgbẹ APC, eyi ti Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, jẹ alaga rẹ, a si ṣetan lati ṣatilẹyin fun wọn lẹnu akitiyan wọn lati mu ki Naijiria ati ẹgbẹ APC dara si i ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ

“A tun fẹẹ fi atilẹyin wa han si Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, fun bo ṣe fẹẹ jade dupo aarẹ lọdun 2023, ati bo ṣe n pe fun ipo aarẹ lati bọ si apa Ariwa/Aarin-Gbungbun orileede yii.”

Leave a Reply