O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Ni bayii ti Akeredolu ti tun wọle lẹẹkeji

Ariwo pọ, idaamu ati fa-a-ka-ja-a. Ibo Ondo yii, bii ogun kan lọtọ ni. Ṣugbọn a dupẹ pe ko le ju bayii naa lọ. Wọn ti dibo naa, ki iṣẹ bẹrẹ pẹrẹwu ni. Ko si aaye fun idaduro kan tabi ikunsinu kankan mọ, ohun to kọja lọ ti kọja lọ. Gbogbo awọn to ba ti mọ pe wọn yoo ṣe ipinlẹ Ondo loore, gbogbo wọn ni ko ko mọra, ki iṣẹ idagbasoke si bẹrẹ loju ẹsẹ. Bi ibo ba ti n bọ wa bayii, ohun gbogbo ni yoo fọnka, eto idagbasoke ilu yoo duro soju kan, ija lọtun-un ija losi, kaluku oloṣelu yoo fẹẹ le ẹni to wa nibẹ lọ, ẹni to wa nibẹ ko si ni i fẹ ki wọn le oun lọ. Ati pe ọrọ oṣelu lọdọ tiwa nibi bayii, bii ẹni to n ṣowo ni, ọpọ awọn oloṣelu yii, owo ni wọn n ṣe, lẹyin ti wọn ba si ti dibo ti wọn wọle tan, owo ti wọn ko sile ni wọn yoo maa wa bi wọn yoo ti ṣe ri i pada, ko ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn bi ija ba ti tan bayii ti ẹni kan ti wọle, oloṣelu to ba fẹ ki ọrọ oun wa lọkan awọn araalu titi, daadaa ni yoo ṣe fun gbogbo eeyan, ti wọn yoo le maa sọrọ rẹ si rere, koda nigba to ba fi ipo naa silẹ. Akeredolu ti waa wọle bayii, o ti ja ogun ajaye, ko si aaye fun ibinu tabi arokan mọ, ko fa ẹni gbogbo mọra, ko si ri i pe oun di baba gbogbo ara Ondo pata. Bẹẹ ni tootọ, oun ni baba gbogbo eeyan nipinlẹ Ondo, ko si gbọdọ yọ ẹnikẹni sẹyin, ko ṣeto idagbasoke naa ko kari ẹni gbogbo ni. Akeredolu ti wọle, ko gbọdọ si ibinu tabi ifarayaro, ki gbogbo oloṣelu Ondo pawọ-pọ lati jọ gbe ipinlẹ naa ga ni. Yoo ṣee ṣe o, ipadabọ Akeredolu lẹẹkeji yii, nnkan rere ni yoo jẹ fun gbogbo eeyan ipinlẹ naa o.

 

Nibo ni Agboọla Ajayi yoo gbe ọrọ ara ẹ gba bayii o

Oloṣelu ki i lojuti ni, bo ba ṣe pe wọn n lojuti, awọn ohun kan wa to yẹ ki wọn ṣe. Ṣugbọn wọn ko ni i ṣe e, nitori ailojuti wọn. Bi Agboọla Ajayi yoo ba ṣe daadaa bayii ni, ko si ohun to dara ju ko kọwe fipo to wa gẹgẹ bii igbakeji gomina Ondo lọ. Eleyii yoo fun un ni apọnle ju bo ba wa ni ipo naa titi ti asiko wọn yoo fi pe, ti yoo kan maa gba owo-oṣelu awọn ara ipinlẹ Ondo lai ni iṣẹ kan ti yoo ṣe fun wọn lọ. O daju pe Akeredolu ko le fọkan tan an lati gbe iṣẹ ilu ṣe fun un ninu ijọba rẹ yii mọ, nitori oun naa ṣe ohun to buru ju lọ. Bo ba ṣe pe bi oun ṣe ṣe ni iru igbakeji gomina ipinlẹ Edo ṣe, iba ṣoro ki Ọbaseki ọhun too di gomina lẹẹkeji, bi ko si jẹ ti ọpọ ara Ondo to wa lẹyin Akeredolu, eyi ti a n wi yii kọ la ba maa wi, nitori igbakeji rẹ ko ro daadaa si i. Ẹni to ba ro daadaa si ni ko ni i duro lati koju ẹni ninu idibo, ṣebi ohun ti oun naa ṣe wa ni ki oun le wọle, ki oun si gba ipo gomina naa lọwọ ọga oun. Ṣugbọn iwa ọdalẹ ni, koda, ko lorukọ meji ti eeyan yoo pe e, iwa ọdalẹ ni Agboọla hu, o si daju pe ko si oloṣelu gidi kan ni ipinlẹ Ondo ti yoo fẹ ki kinni kan pa oun ati ẹ pọ lọjọ iwaju. Bi Akeredolu ko ba dara, ti o si fi ibinu kuro ninu ẹgbẹ wọn, ki lo tun le e ni ẹgbẹ PDP to sa lọ. Dajudaju, ko si ohun meji to n le ju ko di gomina lọ. Bo ba jẹ inu PDP to binu lọ lo duro si, o ṣee ṣe ki ẹgbẹ naa wọle, nitori awọn eeyan mi-in yoo tubọ dibo fun ẹgbẹ naa nitori tirẹ, yatọ si ibo ti wọn ko di fun un daadaa nigba to sa lọ sinu ẹgbẹ ti ọpọ eeyan ko mọ orukọ rẹ, ẹgbẹ ti wọn si ti mọ pe ko le wọle. Ni bayii, ọgbẹni ti le eku meji, o ti pofo, ko si si ipo kankan to wa ninu ẹgbẹ oṣelu tabi ijọba rẹ ju korofo lasan lọ. Bi i ṣee ri fun alaṣeju naa niyẹn. Nitori rẹ ni ko ṣe yẹ ko maa gba owo awọn ara ipinlẹ Ondo lai ṣe kinni kan fun wọn, ohun to dara fun un ni lati kọwe fi ipo rẹ silẹ, boya yoo le ri apọnle diẹ. Koda bi wọn mu un lọọ bẹ Akeredolu, ti wọn si ni ki wọn pari ija, ko sẹni ti ko mọ pe ko si oore kan ti yoo ti idi iru ipari-ija bẹẹ jade fawọn ara Ondo, ifowojona lasan ni yoo si jẹ, wọn yoo kan maa nawo awọn ara ipinlẹ yii danu ni. Iyẹn o si daa rara o, oloṣelu ti ko ba niṣẹ to n ṣe fun ilu, ko ma gbowo awọn araalu o. Ko si iṣẹ ti Agboọla yoo ṣe bayii, ko ma gba owo kankan lọwọ ijọba.

 

Mimiko paapaa yoo fara ko o

Nigba ti agbalagba ba wẹwu aṣeju, ẹtẹ ni yoo fi ri. Eyi ti Oluṣẹgun Mimiko, gomina Ondo tẹlẹ, ṣe lasiko ibo to kọja yii, afaimọ ko ma fi ri ẹtẹ o. O daju pe laarin ọdun yii si ọdun mẹrin to n bọ, iṣoro yoo wa fun un nile ijọba ipinlẹ Ondo, iṣoro yoowu to ba si ba a, ọwọ ara rẹ lo fi fa a o. Bi eeyan ba de ipo agba, yoo jokoo bi agba ni, eyi ko ni i jẹ ki awọn ọmọde kan ri i fin. Ṣugbọn nigba ti agba ko ba jokoo si ipo agba, ọmọde yoo ri i fin. Nigba ti ibo n bọ yii, ohun ti awọn eeyan ti ro ni pe ẹyin Gomina Rotimi Akeredolu ni Mimiko yoo wa, nitori pe ọrẹ loun ati gomina ọhun, ati pe Akeredolu ti ṣe daadaa pupọ fun un. Lara daadaa ti Akeredolu ṣe ni pe ninu gbogbo awọn gomina ti wọn maa n jẹ ti wọn n daamu ẹni ti wọn ba gba ipo lọwọ rẹ, paapaa nigba ti wọn ki i baa ti i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa, Akeredolu jẹ ọkan ninu ẹni ti ko daamu Mimiko, o fi i silẹ ko maa ba tirẹ lọ. Tabi Mimiko yoo sọ pe ti wọn ba tu idi oun laarin ọdun to fi ṣejọba, wọn ko ni i kan igbẹ nibẹ, tabi ki i ṣe awọn oloṣelu Naijiria yii ni. Ṣugbọn Akeredolu ko ṣe bẹẹ, o si tun ṣe awọn ohun mi-in to fi ṣe apọnle fun Mimiko yii. Ẹni to ba ṣe iru oore bẹẹ fun ni, eeyan ki i jẹ ki nnkan onitọhun bajẹ, koda, ko tilẹ ṣe ohun ti ko ba dun mọ ni fun ni. Ṣugbọn Mimiko ko ronu bẹẹ, oun lo gba ọdalẹ to dalẹ ọga rẹ lalejo, oun lo fio fi sinu ẹgbẹ oṣelu rẹ, to ni ko koju ọga rẹ, ki oun le jẹ baba isalẹ fun wọn. Ohun to fa eyi ni pe ko si ohun ti awọn oloṣelu ki i fi ara wọn pe, koda, nigba ti ko si agbara kankan lọwọ wọn mọ, ti wọn ko si ja mọ kinni kan loju awọn eeyan, yatọ si awọn ti wọn ba ṣi n ri tọrọ-kọbọ lọwọ wọn, wọn yoo maa sọ pe ko si bawọn ko ṣe jẹ ni. Mimiko naa ti ri i bi agbara oun ti to, yoo ti ri iye ibo ti ẹgbẹ oṣelu oun ati ọmọ ti oun fa kalẹ mu, eleyii yoo fi han an bi agbara rẹ ti to, yoo si le mọ pe Mimiko ọdun marun-un sẹyin ki ṣe Mimko toni yii, nnkan ti yatọ pata. Ṣugbọn awọn oloṣelu ki i gba, eyi ni ki i jẹ ki wọn mọ iwọn ara wọn. O ti ṣẹlẹ bayii, Mimiko ti koju Akeredolu, o si ti ja bọ, bi yoo ti ṣe e bayii, oun nikan lo mọ o.

 

Akeredolu pẹlu Makinde, ẹ ma jẹ kọrọ yii dija o

Igba kan n bọ ti awọn gomina yoo fi si aarin ara wọn lati mọ pe wọn ko ni i maa lo pọ si ipinlẹ ẹlomi-in lati ba wọn ṣeto tabi polongo ibo lorukọ ẹgbẹ wọn nibẹ. Pe nigba ti oun ba fẹẹ du ipo gomina ni ipinlẹ kan, ko dara ki gomina to ba n ṣejọba ni ipinlẹ tirẹ kuro ni ipinlẹ rẹ, ko wa si ipinlẹ gomina mi-in, ko maa ba wọn nawo, ko maa ba wọn nara lati yọ gomina to ba wa nipo naa kuro. Iru eyi to ṣẹlẹ l’Ondo lọsẹ to kọja yii, nibi ti Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti fi ipinlẹ rẹ silẹ, to n waa ba wọn ni ipinlẹ Ondo, to si ṣe atilẹyin fawọn ti wọn fẹẹ gba ipo lọwọ Akeredolu. Bẹẹ Akeredolu yii, ọrẹ loun ati Makinde, paapaa lori ọrọ Amọtẹkun ti wọn jọ n ṣe. Iroyin to wa niluu ni pe Makinde ati awọn gomina to ku gbe owo nla wa lati ipinlẹ wọn, Makinde si ṣaaju wọn lati ri i pe PDP gba ipo naa kuro lọwọ Akeredolu, ijọba Ondo si bọ sọwọ Jẹgẹdẹ. Eto idibo ni ilẹ wa nibi ko ti i dagba to bẹẹ, ko ti i laju to eyi ti awọn oloṣelu meji yoo wa ninu ẹgbẹ ọtọọtọ, ti wọn yoo jọ du ipo, ti wọn yoo si dibo tan ti wọn yoo tun maa ṣe ọrẹ ara wọn. Afaimọ ni eyi ti Makinde ṣe yii ko ni i ba eto Amọtẹkun ti wọn n ṣe ni ilẹ Yoruba jẹ, nitori bi Akeredolu ba ṣi n ṣe Amọtẹkun l’Ondo, ko ni i jẹ ki Amọtẹkun tirẹ ba ti awọn Makinde ṣe. Bo si jẹ iṣẹ okoowo mi-in lo fẹẹ pa wọn pọ, bii ileeṣẹ Oodua ti wọn jọ wa ti wọn n n ṣe akoso, afaimọ ni wọn ko ni i ba ileeṣẹ naa ati ajọṣe wọn yii jẹ. Loootọ ko si ohun ti Makinde le ṣe bi ẹgbẹ rẹ ba ni ko lọ si Ondo, ṣugbọn ibukun ni fun ọmọ ọdọ naa to fọgbọn ṣe e. Oun nikan ni gomina PDP ilẹ Yoruba, tipatipa si ni awọn gomina to ku fi n ba a ṣe. Pẹlu eyi to ṣe yii, ọta yoo tubọ pọ pupọ fun un ni, ohun to si n ba ni lẹru ni pe ọta naa yoo pọ nilẹ Yoruba ju ibomi-in lọ. Abi iru ewo la tun ko si bayii nitori Ọlọrun!

 

Ẹgbẹ wo ni Fayoṣe n ṣe

Nigba ti wọn n ṣe ipolongo ibo wọn ni Edo, ti oju ogun le gan-an, ti gbogbo awọn eeyan PDP, awọn gomina, atawọn aṣaaju ẹgbẹ naa si n rọ kẹkẹ, ko sẹni to gburoo Ayọdele Fayoṣe; titi ti wọn fi dibo naa tan, ati nigba ti wọn dibo tan paa, ko ranti ki awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ku oriire. Igba ti ija oun ati Abiọdun Olujimi bẹrẹ nibi lọjọsi, ti Ṣeyi Makinde, gẹgẹ bii olori ẹgbẹ naa ni ilẹ Yoruba, loun yoo da si i, Fayoṣe loun o mọ Makinde, ko si le da sọrọ awọn nitori o ti kere ju. Lọsẹ to lọ lọhun-un, Fayoṣe ni Bọde George ni wahala PDP, afi ki awọn le e lọ. Lọsẹ to koja yii, wọn dibo l’Ondo, awọn PDP ja fitafita, Makinde wa lati Ọyọ, awọn gomina mi-in wa lati ipinlẹ wọn, ṣugbọn Fayoṣe to wa nitosi nibi ko jade si wọn, koda ko fara han bii PDP l’Ondo, o da wọn da iṣoro wọn ni. Ninu ẹgbẹ wo gan-an waa ni Fayoṣe wa o, nitori bo ba ya, yoo ko agbada yẹyẹ kan kọrun, yoo ni oun n gba ilẹ Ibo tabi ilẹ Hausa lọ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ PDP. Ṣebi ko si ibi ti ija ko ti n si, bi ẹgbẹ ba si ti wa, to tobi bii ẹgbẹ PDP yii, ija yoo maa waye nibẹ, bẹẹ ni awọn aṣaaju ati awọn ọmọ ẹgbẹ paapaa yoo maa ṣẹ ara wọn, ohun ti wọn fi n mọ aṣaaju ẹgbẹ gidi ni awọn ti wọn ba duro, ti wọn yanju ija to ba ṣẹlẹ, ti wọn si pa ija tabi ibinu ti lasiko to ba yẹ ki wọn pawọ pọ ṣiṣẹ idagbasoke fun ẹgbẹ wọn. Pẹlu gbogbo eyi ti Fayoṣe n ṣe yii, ko lẹnu lati pe ara rẹ ni aṣaaju PDP nibi kankan, gbogbo ija tabi akọ to ba si n ṣe ni Ado Ekiti, asan lasan ni, nigba to ba ya, yoo ri i pe ko ri bi oun ti ro o si. Ẹni ti ko le ṣe akoso tabi adari ẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ rẹ ati agbegbe rẹ, bawo ni tọhun yoo ṣe jade lati ṣe adari ẹgbẹ naa ni gbogbo orilẹ-ede, tabi ti yoo fi orukọ ẹgbẹ naa du ipo pataki kan. Ẹni ba ba ẹgbẹ rẹ jẹ ko le jẹ anfaani ẹgbẹ naa. Fayoṣe n ba ẹgbẹ rẹ jẹ, n jẹ yoo ri anfaani ẹgbẹ naa jẹ!

Leave a Reply