Eyi ti Alani Akinrinade wi yii nkọ o
Ninu ọrọ to wa nilẹ yii, Ọgagun-agba Alani Akinrinade naa ti sọrọ, ohun kan naa ti gbogbo eeyan si n wi loun naa tun sọ. Olori awọn ṣọja ni Akinrinade, o ti figba kan jẹ olori awọn ṣọja Naijiria pata, bẹẹ lo si di olori awọn ologun gbogbo ni orilẹ-ede wa. Nitori bẹẹ lo ṣe jẹ bo ba sọrọ, eeyan gbọdọ feti balẹ si i ni. Olori awọn ṣọja pata, Tukur Buratai, lo wa si ipinlẹ Ọṣun, Akinrinade si wa ninu awọn alejo pataki ti wọn pe sibi apejẹ ti ijọba Ọṣun ṣe lati ki i kaabọ. Nibẹ ni Akinrinade ti ran Buratai si Buhari, o ni ko sọ fun un pe bi nnkan ṣe n lọ yii, bi ko ba tete wa atunṣe si i, o ṣee ṣe ko jẹ ọdun 2023 ti wọn n pariwo pe wọn fẹẹ dibo mi-in yii, a le ma ni Naijiria mọ nigba naa, ko jẹ korofo lasan ni gbogbo agbegbe yoo wa, ki ogun ti tu wa ka lọ. Akinrinade ni ko si ohun ti yoo fa eleyii ju pe ko si orilẹ-ede kan ti wọn n jagun nibẹ lẹẹmeji ti i tun duro mọ, yoo tuka pata ni. Bẹẹ, bi nnkan ṣe n lọ yii, oko ogun mi-in la tun n ro yii, awọn ohun to n ṣẹlẹ, ti oun si ti gbọ, le da ogun silẹ bi Aarẹ wa ko ba tete ṣe nnkan si i. Akinrinade sọrọ elẹyamẹya, o sọ nipa ipakupa tawọn Fulani n paayan, ati awọn iwa ibajẹ mi-in to pọ ju lasiko ijọba Buhari yii. Ọrọ ti Akinrinade sọ yii naa ko yatọ si ti Ọbasanjọ ati Ṣoyinka, ohun to kan ya awọn eeyan lẹnu ni pe awọn mẹtẹẹta sọrọ naa si asiko kan naa, bii ẹni pe wọn ti ṣepade tẹlẹ pe awọn fẹẹ sọrọ bayii, bẹẹ ata ati oju ni wọn ni kọrọ, awọn mẹtẹẹta yii ki i ṣe ọrẹ ara wọn. Nitori bẹẹ, o han pe ọrọ ti awọn mẹtẹẹta n sọ yii, ọrọ ọlọgbọn ni. Bẹẹ ọrọ ọlọgbọn a maa ba ara wọn mu, ti aṣiwere ẹda nikan ni i yatọ. Ohun to dun mọ ni ninu ni pe awọn ti wọn n sọrọ yii, agbaagba ilẹ Yoruba ni wọn, awọn ti wọn si mọ itan orilẹ-ede yii daadaa ni gbogbo wọn. Ko sẹni to mọ idi ti Buhari ko fi gbọ gbogbo ariwo ti iru awọn eeyan yii n pa, nitori awọn ti oun naa mọ daadaa ni gbogbo wọn. O mọ Ọbasanjọ, o mọ Ṣoyinka, o si mọ Akinrinade daadaa. Bi awọn mẹtẹẹta yii ba n sọrọ, ọrọ naa ni nnkan mi-in ninu ni. Ṣugbọn ko jọ pe awọn ti wọn yi i ka jẹ ko ri ọrọ yii, ko si jọ pe oun naa bikita lati ri wọn. Ibi ti a ba fẹẹ gba bayii, afi ka bẹ Olodumre, ki nnkan ma bajẹ kọja atunṣe. Ṣugbọn ọrọ ni Akinrinade tun sọ yii o, ẹyin ti ẹ ba sun mọ Buhari, ẹ ba wa sọ fun un bi ko ba gbọ o!
Awọn wo lo n ko ibọn fun wọn l’Ondo nitori ibo
Gbogbo bi awọn ọlọgbọn ti n pariwo to, pe ki wọn ma jẹ ki oloṣelu kan lo awọn tabi awọn ọmọ wọn fun iṣẹ aburu, sibẹ, ọpọ eeyan ko gbọn, ohun ti wọn ro ni pe nibi jagidijagan lẹyin awọn oloṣelu lawọn le fi jẹun. Nigba ti eeyan ba ri awọn tọọgi ti wọn doju ibọn kọ ara wọn, ti wọn ba nnkan jẹ, ti wọn n fibọn le awọn eeyan ni Ọba Akoko, nipinlẹ Ondo, lọjọsi, ohun ti eeyan yoo maa beere ni pe awọn wo ni wọn bi awọn eleyii, ki lo de to jẹ iṣẹ iku bayii ni wọn jẹ ki awọn kan maa bẹ awọn. Eelo ni wọn yoo fun wọn nidii ẹ gan-an. Loootọ ni awọn oloṣelu yii ko ṣe daadaa rara, ẹnikẹni to ba n tori oṣelu, to n ko ibọn fun awọn tọọgi, to n lo awọn ọdaran nitori ko le de ipo nile ijọba, iru ẹni bẹẹ ko yẹ lẹni ti awọn araalu gbọdọ fi ṣe olori ijọba wọn, nitori ko ni i ko oriire kan ba wọn nibẹ, yoo kan da kun iṣoro wọn lasan ni. Tabi kin ni a fi fẹẹ ṣe olori ijọba, ṣe ka le maa ko tọọgi kiri, ka si maa fi ibọn le wọn lọwọ ni, ọran ni wọn fi n ṣiṣẹ fun ilu ni! Ṣugbọn nitori pe ki i ṣe ilu ni awọn eeyan yii waa ṣiṣẹ fun, to jẹ wọn kan waa ja ilu lole ni, ko si ohun ti wọn ko ni i lo lati fi de iru ipo bẹẹ. Ki i kuku u ṣe pe wọn fi kinni naa bo, awọn tọọgi n lọ, wọn n bọ, wọn dirọ mọ mọto, wọn si n pe awọn yoo ba nnkan jẹ ni. Tọọgi to gbe ibọn dani ko ṣaa le da wọ ilu oniluu, ẹni kan lo ko owo fun un, ẹni kan lo si gbe ibọn rẹ fun un. Ẹni kan lo haaya ẹ pe ko waa yọ awọn alatako wọn lẹnu, bẹẹ ọmọ ipinlẹ Ondo ni gbogbo wọn, ati awọn ti wọn fẹẹ dibo, ati awọn ti wọn n dupo, ati awọn tọọgi ti wọn wa yii, ọmọ Ondo yii naa ni gbogbo wọn. Ṣugbọn ki gbogbo ọmọ Ondo ranti o, pe ẹgbẹ oṣelu yoowu, tabi ẹnikẹni to ba lo tọọgi nitori eto idibo, tọhun ko ni i mu anfaani kan waa fun wọn, yoo pada jẹ wọn nijẹkujẹ, yoo si ba tirẹ lọ ni, nitori lati ilẹ, ole, jaguda, adigunjale ni iru ẹni bẹẹ, ko si fi pamọ fun wọn pe oun yoo ja wọn lole, iyẹn lo ṣe le ko tọọgi waa ba wọn. Ṣugbọn bi awọn oloṣelu ba n ṣe bayii, o yẹ ki ọlọmọ le kilọ fun ọmọ rẹ, o yẹ ki gbogbo ẹni to ba leeyan le kilọ fun wọn pe ki wọn ma fi iku ojiji tabi ẹwọn gbere ṣefa jẹ nitori ọrọ oṣelu ti awọn to n du ipo ko naani wọn, ti wọn o si ro tiwọn mọ ọn. bi wọn ba ku lonii yii, wọn ku gbe lasan ni. Eyi ni kaluku ko ṣe gbọdọ sinmi, bi ẹ ba ti n ranti pe ole ni oloṣelu to n lo tọọgi, bẹẹ naa ni ki ẹ si maa ranti lati kilọ fun awọn eeyan yin, ki wọn ma ṣe tọọgi, ki wọn ma si fi ara wọn silẹ lati lo fun awọn oloṣelu to fẹẹ ṣe wọn laidaa. Lojoojumọ ni nnkan n bajẹ niluu yii si i, ṣugbọn ki ọlọmọ kilọ fọmọ rẹ, nitori to ba ṣẹlẹ tan, ko ni i mọ ni awọn nikan.
Lẹẹkan si i, o yẹ ki Mimiko ṣọra ẹ gidigidi
Ẹni to ba n wa ohun ti ko sọnu kiri, tọhun yoo ri nnkan aburu ti ẹni kan ti gbe junnu sibi kan he. Nibẹrẹ ijọba yii, ẹni apọnle kan ni Dokita Oluṣẹgun Mimiko jẹ loju awọn ti wọn n ṣejọba ati awọn araalu lapapọ. Gẹgẹ bii ipo oriṣiiriṣii to si ti di mu nipinlẹ Ondo yii, to ti ṣe akọwe ijọba, to ti ṣe kọmiṣanna, to ti ṣe minisita, ko too waa ṣe gomina fun odidi ọdun mẹjọ, ipo agba, ipo baba isalẹ fun gbogbo oloṣelu, lai fi ti ẹgbẹ wọn ṣe lo yẹ ki awọn eeyan maa ba a. Ṣugbọn Mimiko ti fi ọdun mẹrin lo ipo naa, ko si fẹẹ ṣe bẹẹ mọ, iyẹn ipo agba fun awọn oloṣelu ati awọn ti wọn n ṣejọba. Loju ọpọlọpọ eeyan bayii, oun Mimiko lo n ṣe atilẹyin fun Agboọla Ajayi, oun lo wa lẹyin ẹ to fi n ba ọga rẹ ja, eyi lo si jẹ ko jẹ inu ẹgbẹ rẹ lo fabọ si, nitori oun Mimiko n wa ẹni ti yoo ṣe gomina, ti yoo le maa paṣẹ fun, ti yoo si maa ni ko ṣe ohun ti oun ba fẹ. Ati pe nitori ti ko ri Akeredolu lo fun iru eyi, bo tilẹ jẹ ọrẹ ni wọn, lo ṣe mura lati gbe Agboọla dide pe ko tako o. Oun naa ko si fi bo mọ o, o ti jade pe Agboọla lo dara ju lati di ipo gomina mu l’Ondo, ti wọn ba n fẹ ijọba rere. Agboọla ti ṣe igbakeji gomina fun ọdun mẹrin, bo si tilẹ jẹ pe o ti lo kọja ọdun mẹta ki ija too de, sibẹ, ko sẹni to ri ipa ribiribi kan ti ọkunrin naa ko ninu ijọba to n ba wọn ṣe. Ẹni to ba ṣe igbakeji gomina ti ko ri kinni kan ṣe fun araalu, iwọnba nnkan ni keeyan reti lọdọ rẹ mọ to ba di gomina. Ṣugbọn iyẹn kọ ni pataki bi ko ṣe ipa ti Mimiko n ko ninu ibo to n bọ naa. Ohun to yẹ ko ṣọra si ni, ko si fura rẹpẹtẹ, bi bẹẹ kọ, bi awọn ti wọn n ṣejọba ba doju kọ oun naa, ko ma di ohun ti yoo maa sare palọ ni yara, ti yoo maa rin kiri lai ni i tete ri ẹni ti yoo ba oun da si i. Agba aja ki i ba awọ jẹ, bi Akeredolu ko ba daa to, ki i ṣe igbakeji rẹ ni Mimiko yoo dẹ si i, nitori oun naa ko ni i gba iru rẹ, ohun ti ko ba si jẹ gba, ko yẹ ko ṣe e fẹlomi-in o.
Ẹ sọ fun Alao Akala ko lọọ sẹmpẹ jare
Lati igba ti gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Isiaka Abiọla Ajimọbi, ti ku lo jọ pe ipo tuntun ti ṣi silẹ ninu ẹgbẹ APC ipinlẹ naa, ti awọn oloṣelu si n sare akọlukọgba labẹlẹ, bo tilẹ jẹ wọn ni wọn n daro Ajimọbi. Ninu awọn ti wọn si yọri lati gba ipo aṣiwaju APC yii naa ni gomina atijọ, Oloye Alao Akala. Akala ti mura gidigidi lati di olori ẹgbẹ naa, ipade oriṣiiriṣii lo si n pe lati fi han gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ pe oun ni olori wọn tuntun. Bi Akala ba di olori APC Ọyọ, ko buru rara, ṣugbọn yoo ṣoro ki awọn eeyan gidi niluu too ri ẹgbẹ naa bii ẹgbẹ to nikan an ṣe ni. Tabi ki i ṣe Alao Akala to ṣe gomina bii ọdun mẹfa, to fi ọdun mẹta ṣe igbakeji gomina, ninu ẹgbẹ PDP, to si ti jẹ ọmọ ẹgbẹ ọhun lati ibẹrẹ pẹpẹ, to si ti ṣe olori PDP Ọyọ yii ni gbogbo igba to fi n ṣe olori ijọba, ṣe ki i ṣe oun naa lo fẹẹ di aṣaaju wọn ninu APC yii. Ohun to n ba ẹgbẹ APC jẹ nile-loko ree, nitori eeyan ko mọ iyatọ laarin awọn ati awọn PDP, tori gbogbo awọn ti wọn n pe ara wọn ni olori tabi aṣiwaju ẹgbẹ naa, eeyan nla ni wọn ninu PDP tẹlẹ. Bawo ni Akala yoo ṣe di olori APC Ọyọ, ti yoo si maa paṣẹ le awọn alaga ati gbogbo awọn to ba ku ninu ẹgbẹ naa lori. Ṣebi o yẹ ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ beere lọwọ ẹ pe ki lo le e ninu PDP to ti jẹ olori wọn tẹlẹ. Dajudaju, bi wọn ba bi i, yoo ri ọrọ sọ, ṣugbọn bi yoo ti ṣe ri ọrọ sọ naa niyi lọjọ ti wọn ba tun lu APC naa fọ, to si mu ẹwu rẹ, to n lọ. Nigba ti eeyan ba kọle, to waa tori pe ija de ninu ile naa, tabi pe ko si ounjẹ ninu ile naa mọ, to mu ẹwu rẹ, to jade, to fi iyawo ati ọmọ silẹ, to lọ sile ọrẹ rẹ nitori pe ounjẹ wa nile awọn, iru baba wo leeyan yoo pe iru ẹni bẹẹ. Olori ẹgbẹ kan ki i fi ẹgbẹ rẹ silẹ, nigba ti ki i ṣe pe wọn di i loju ko too wọ inu ẹgbẹ naa. Bo ba si ti waa fi i silẹ, ko yaa lọọ sẹmpẹ ni, ki i ṣe ko tun maa fo sinu ẹgbẹ mi-in kiri. Nitori bẹẹ, bẹ ẹ ba ri Alao Akala, ẹ sọ fun un ko lọọ sẹmpẹ!
Wọn ni ọrẹ wa ni Kogi n binu
Ẹ ti gbọ ti ọrẹ wa ni Kogi ti wọn lo n binu. Yahaya Bello n binu, o ni awọn ara Amẹrika ni awọn ko ni i fun oun ni fisa lati wọ orilẹ-ede awọn. Njẹ ki lo de, wọn ni nitori wọn sọ pe oun ṣojooro lasiko ibo, oun riigi ibo! O waa ni ki lo kan Amẹrika ninu ọrọ Naijiria, bi oun ba ṣojooro nkọ, ṣebi ilẹ baba oun loun wa, abi ewo ni tiwọn. Eyi to jẹ tiwọn naa gan-an ni wọn fi han an yẹn. Abi ta ni ko mọ bi ibo ti wọn di ni Kogi ṣe lọ, ti wọn n yinbọn paayan, ti wọn n dana sunle, nitori ki Yahaya Bello le wọle ni gbogbo ọna. Tabi ta ni ko mọ pe ojooro buruku ati ipaayan lo waye nibi ibo Kogi. Ẹni to ba wa nidii iru nnkan bẹẹ, awọn orilẹ-ede ti wọn ba fẹ alaafia lọdọ wọn ko ni i fẹẹ ri i lagbegbe wọn rara.Nitori ẹ ni Amẹrika ṣe lawọn ko fẹ ẹ lọdọ tiwọn. Ṣugbọn ọrọ naa maa n ka awọn oloṣelu wa lara ti wọn ba ni ki wọn ma wa si Amẹrika, nigba to jẹ nibi ti wọn ti n fowo naira ti wọn ba ji ko ṣe faaji niyi, ti wọn si n na an ni inakunaa bi wọn ba ti fẹ. Bi ko ba wa jẹ bẹẹ, kin ni yoo maa bi Yahaya ninu si nitori wọn ni ko ma wa si Amẹrika! Ṣe o da ileeṣẹ sibẹ ni abi ibẹ ni wọn ti bi i. Abi ibẹ ni ile iya ati baba rẹ! Bi wọn ba ba ilu tiwọn jẹ tan, wọn yoo maa wa ọna lati sa lọ siluu oniluu kiri! Iba jẹ bi ẹyin ṣe n ba ilu tiyin jẹ lawọn naa ba tiwọn jẹ ẹyin iba ribi maa sa lọ! Ṣiọ!