Pasitọ Adeboye pẹlu owo dọla
Ni ti ohun to n ṣẹlẹ ni orilẹ-ede Naijiria wa bayii, ko si aṣaaju rere kan ti yoo ni ọrọ naa ko kan oun, afi awọn aṣaaju buruku nikan. Nnkan kan n fojoojumọ bajẹ ṣaa ni, ohun gbogbo to dara daadaa tẹlẹ si bajẹ loju wa. Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn Ọjọgbọn nla orilẹ-ede yii, Pat Utomi, ti wi ni Satide to kọja yii, o ni o yẹ ki oju ti awọn ti wọn ba n pe ara wọn ni aṣaaju ni Naijiria, nitori bi ohun gbogbo ṣe yipada si aidaa loju wọn. Nitori ẹ ni ọrọ ti olori ijọ Ridiimu, Pasitọ E. O. Adeboye, sọ nibi ibẹrẹ isin nla Holy Ghost ijọ yii ṣe yẹ ni ohun ti eeyan n pe akiyesi pataki si. Ojiṣẹ Ọlọrun naa ni owo naira to jẹ ti Naijiria n bọ waa dara laipẹ yii, pe owo naa yoo dara gan-an bi wọn ba gbe e si ẹgbẹ owo dọla ti awọn ara Amẹrika. Ṣe ni tootọ, o pẹ ti nnkan ti bajẹ to bayii fun Naijiria, nibi ti dọla ẹyọ kan ti n lọ si bii ẹẹdẹgbẹta naira. Eleyii buru, nitori ohun to tumọ si ni pe bi eeyan ba n ji lojoojumọ aye yii, to n tọju naira kan pamọ, to ba ṣe bẹẹ fun odidi ọdun kan, gbogbo owo to tọju naa ko ti i ni pe dọla ẹyọ kan. Bẹẹ igba kan si wa nilẹ yii ti owo naira wa tobi ju owo dọla lọ, to jẹ dọla meji leeyan yoo ni ko too gba naira kan. Koda, ki ijọba to wa lode yii too de, nnkan o buru to bayii, lara ileri ti wọn si ṣe nigba ti wọn fẹẹ wọle ni 2015 ni pe awọn yoo sọ dọla kan di naira kan fun gbogbo wa. Ṣugbọn kaka ki wọn sọ dọla kan di naira kan, ẹẹdẹgbẹta naira ni wọn sọ dọla kan da. Awọn ti ko mọ pataki ọrọ yii le maa beere pe kin ni owo dọla ni i ṣe pẹlu owo naira tiwa. Pataki ẹ ni pe owo dọla yii ni wọn fi n wọn bi orilẹ-ede kan ba ti lagbara, ati bo ṣe riṣe, to lagbaaye. Ọpọlọpọ ọja ti a n lo ni Naijiria, ilẹ okeere, nilu oyinbo, ni wọn ti n ko wọn wa, dọla ni wọn si fi n ra a. Eyi lo n fa a to jẹ ọja ti a ba ra ni iye kan loni-in yii, ko too di lọla, kinni naa yoo ti gbe owo lori. Ki i ṣe pe ọja yii gbowo lori nibi ti wọn ti n ta a, owo dọla ti wọn fẹẹ fi ra a lo ti pọ pupọ ju owo naira tiwa lọ. Ohun to n sọ wa di onigbese kaakiri aye ree, ohun ti ko si jẹ ki ilọsiwaju kan de ba wa lati igba ti ijọba yii ti de niyẹn, nitori lati igba ti awọn ti de ni owo dọla ti n ga soke, ko si ti i fi ọjọ kan bayii walẹ ri, oke lẹmu n ru si ni. Ṣugbọn Pasitọ Adeboye ni owo naira n bọ waa dara, nidii eyi, o yẹ ki gbogbo wa maa yọ ni. Ṣugbọn ayọ naa ṣoroo yọ, nitori bi owo dọla ba dara, awọn to ba a jẹ de ibi to de yii, awọn ti wọn n fi ojoojumọ ji i ko, awọn yii wa nibẹ ti wọn ko rebi kan. Awọn ti wọn n ṣẹjọba, awọn oloṣelu ati awọn aja wọn ti wọn wa nigboro, awọn yii ni ole, awọn lọbayejẹ ti n ba nnkan wa jẹ. Boya ki Baba Adeboye kọkọ gbadura fun wọn, ki wọn ba wa yọ ojukokoro ati ole-jija to ti dapọ mọ inu ẹjẹ wọn kuro, ki wọn yee ji owo araalu ko, ki wọn yee sọ owo ijọba di owo baba wọn ti wọn le ji bo ṣe wu wọn, ki wọn fi ole-jija silẹ, ki wọn si ṣejọba ko dara. Nitori bi owo dọla ba daa, awọn eeyan yii yoo tun ji i ko ni o! Awọn naa ni wọn ba wa debi ti a wa yi, ko si jọ pe wọn ṣetan lati pada lẹyin wa. Ki owo naira too dara pada, Pasitọ Adeboye, ẹ ba wa gbadura fawọn oloṣelu naa, paapaa awọn ọmọ ẹyin Buhari yii, ki wọn yee ko wa lowo jẹ!
Ṣe nitori ẹ ni, o ti ye wa bayii
Ọkunrin kan, Tunde Balogun, ti i ṣe alaga igbimọ alaabojuto ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Eko ti sọ pe adehun wa laarin awọn aṣaaju APC pe ti ilẹ Hausa ba ti jẹ aarẹ tan, ilẹ Yoruba ni wọn yoo ti mu aarẹ mi-in lọdun 2023. Balogun ni nibi ti wọn ti n ṣe adehun naa paapaa, Tinubu wa nibẹ, bẹẹ si ni Buhari. Lọrọ kan, ohun ti ọkunrin yii n sọ bayii ni pe bi awọn Buhari ba fẹẹ tẹle adehun ti wọn ṣe, Tinubu lo yẹ ko di aarẹ ni 2023. Balogun ba ọrọ naa jẹ, nitori o ni wọn ko kọ kinni naa sibi kan, eyi lo ṣe jẹ pe awọn ẹni tọhun n sọ pe ko si adehun kan laarin awọn, ẹni yoowu ti ẹgbẹ ba mu lo le di aarẹ, koda, ko tun jẹ ọmọ Hausa mi-in ni. Ṣugbọn ohun to wa nilẹ yii, ọna naa ko jọ pe yoo dun-un-rin bi Balogun ti n sọ ọ yii, ọna ti yoo le diẹ fun Tinubu lati di aarẹ ni, nitori awọn ti wọn jọ ṣe adehun yii ko mura lati mu adehun naa ṣẹ. Bẹẹ awọn naa si jẹbi, nitori adehun ti wọn n sọ yii ko si ni akọsilẹ nibi kan. Ati paapaa, awọn ohun to n bọ sọnu lapo Yoruba lasiko yii ti pọ ju, awọn irẹjẹ, iwa ika, ati imunilẹru, to n lọ nilẹ yii, to si jẹ Yoruba lo n fori fa a ko ṣee maa fẹnu sọ. O dara ti a mọ bayii pe nitori adehun to wa laarin Buhari ati Tinubu ni awọn aṣaaju APC ilẹ Yoruba ko ṣe le sọrọ si gbogbo aburu to n ba wa, nitori ẹ ni wọn ṣe n fi Fulani ṣe kọmiṣanna Eko, nitori ẹ ni wọn ṣe n fẹẹ fi ọba Fulani jẹ, nitori ẹ ni wọn ko si jẹ sọrọ bi awọn Fulani onimaalu ba n ji awọn ọmọ wa gbe, ti wọn n fipa ba awọn aya wa sun, ti wọn n paayan lọ falala, ti wọn si n dara ti ko si Yoruba to le da iru ẹ lọdọ tiwọn. Ṣe nitori ẹ ni! Ṣe nitori pe Tinubu yoo di aarẹ ni gbogbo iya yi ṣe n jẹ Yoruba, o ṣẹṣẹ ye wa ni. Ṣugbọn ohun ti ko ye wa nibẹ ni pe ti a ba tori pe a fẹẹ lọ si Ẹdẹ, ti a waa ba ẹẹdẹ jẹ, nigba ti a ba ti Ẹdẹ de, nibo la fẹẹ pada de si o. Ko dara lati tori pe Tinubu tabi ẹnikẹni yoo di aarẹ, ka tori ẹ sọ Yoruba di ero ẹyin, bi a ba ja fun Yoruba, nigba ti ipo naa ba de, ko sẹni ti yoo gba a lọwọ wa. Ṣugbọn ti a ba tori pe a fẹẹ du ipo kan, ti a ba ba ilẹ Yoruba jẹ, afaimọ ki ipo naa ma bọ lọwọ wa. Bo ba jẹ nitori ipo aarẹ ni awọn aṣaaju oloṣelu ilẹ Yoruba ṣe n wo wa niran ki iya maa jẹ wa, ki ẹ tete yaa tun ero naa pa o, nitori ohun ti yoo lẹyin gidi gan-an ni!
Iyẹn la o ṣe le ko ọrọ Fayoṣe danu
Iyẹn lo ṣe jẹ ọrọ ti Gomina Ekiti tẹlẹ, Peter Ayọdele Fayoṣe, sọ ko ṣee ko danu. Ọkunrin naa ni gbogbo awọn ti wọn n gbe Buhari kiri lọdun 2015, awọn ti wọn n wọ ọ kiri ilẹ Yoruba pe oun lo dara ju ni gbogbo Naijiria lati jẹ aarẹ wa, awọn ti wọn sọ pe ko si iru rẹ ni agbaye, oun ni ki gbogbo Yoruba tẹle, o yẹ ki wọn jade bayii lati waa tuuba, ki wọn si tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria, paapaa ju lọ awọn ọmọ Yoruba pata. Koda, bi eeyan kan ba wa ti ko lọpọlọ rara, bo ba jẹ iru Buhari yii lo ba lọ sode gẹgẹ bii aarẹ orilẹ-ede kan, o yẹ ki tọhun pada sẹyin loootọ, nitori gbogbo iwa ti Buhari n hu lati ọjọ yii ko jọ ti aarẹ, bẹẹ ni ko si jọ ti ẹni to fẹran orilẹ-ede rẹ. Ijọba yii ko ro rere kan awọn eeyan orilẹ-ede yii, ijọba to ko gbogbo Naijiria si yọọyọọ ni. Bi eegun ẹni ba joore, ori yoo maa ya atọkun, bo ba jẹ Buhari ṣe daadaa nile ijọba, idunnu awọn ti wọn gbe e wọle ni ọdun naa lọhun-un ni yoo jẹ, ṣugbọn Buhari ko ṣe daadaa, awọn naa si mọ. Ko waa si ohun meji to yẹ ki wọn ṣe ju ki wọn tuuba lọ, ki wọn sọ pe ki awọn ọmọ orilẹ-ede yii ma binu, nitori awọn ni wọn tan wọn, awọn ni wọn parọ, awọn ni wọn sọ ohun ti wọn ko mọ nipa Buhari, ti araalu fi jade dibo fun un. Ṣugbọn kaka ki awọn oloṣelu yii ṣe bẹẹ, niṣe ni wọn tun n purọ mọ irọ, ti wọn n sanwo fun awọn ọmọ-koniṣẹ lati maa lọ sori ẹrọ ayelujara pa irọ oriṣiiriṣii, pe Buhari n ṣe bẹbẹ, ijọba rẹ daa, nigba ti gbogbo araalu foju ara wọn ri i pe ijọba amuṣua ni. Awọn ọmọ Naijiria n reti ki awọn oloṣelu gbogbo nilẹ Yoruba waa tọrọ aforiji, bi bẹẹ kọ, bi ẹnikan ba de pẹlu irọ ori-buruku kan ni ọdun 2021 si 2023, epe buruku ni tọhun yoo gba, awọn epe naa ko si ni i bọ lori rẹ nigba kan.
Awọn Fulani to n paayan l’Ọyọọ
Wọn tun ṣa Fatai Abọrọde pa sọna oko rẹ, awọn Fulani lo ṣa a pa. Ko si ṣe ohun meji fun wọn ju pe o n ṣiṣẹ agbẹ rẹ jẹẹjẹ lọ. O n ti oko bọ, o gun ọkada pẹlu maneja rẹ, awọn janduku Fulani si da a lọna, wọn si ṣa a wẹlẹwẹlẹ nitori ko gba ki wọn ji oun gbe, ki wọn si maa fi oun gbowo lọwọ awọn eeyan oun. Ni gbogbo agbegbe Oke-Ogun ati Ibarapa, awọn Fulani darandaran, ajinigbe ati janduku ti gba ọna oko lọwọ awọn eeyan ibẹ, wọn si ti sọ ara wọn di alaṣe, koda, le awọn ọba agbegbe naa paapaa lori. Abi nigba ti awọn oniluu ko ba ri kinni kan ṣe si ọrọ awọn ti wọn n pa wọn lojoojumọ, ti wọn si n ṣe awọn iyawo wọn ati awọn ọmọ wọn ṣikaṣika. Awọn ohun ti kinni yii yoo mu wa yoo buru. Akọkọ ni wahala ti yoo mu wa nigba ti awọn eeyan ko ba raaye de oko wọn, ẹkeeji si ni aibalẹ ọkan fun gbogbo araalu pata, nitori ninu ijaya ni kaluku yoo maa gbe. Lọna kẹta, ko sẹni to mọ iru aburu ti yoo gbẹyin eyi, nitori o daju pe ki i ṣe nnkan daadaa kan ni yoo gbẹyin ẹ. Ṣe Yoruba yoo laju silẹ, ṣe awọn ijọba wa yoo maa woran titi ti awọn Fulani wọnyi yoo fi ba aye awọn eeyan adugbo yii jẹ ni. Nibo ni awọn oloṣelu ti wọn n pe ara wọn ni ọmọ ẹgbẹ kan tabi ẹgbẹ mi-i wa, kin ni ijọba ipinlẹ Ọyọ funra rẹ n ṣe. Nibo ni awọn Amọtẹkun wa, iṣẹ wọn da, kin ni wọn n ṣe, tabi ki lo n di wọn lọwọ lati le ṣe iṣẹ ti wọn gbe fun wọn. Nitori ki a ma jiya ni a ṣe n ya majiya lọfa, nitori ki iya ma jẹ wa ni a ṣe ni Amọtẹkun tiwa. Asiko ti to ti awọn ijọba wa ko gbọdọ ṣe ojo mọ, lati Eko titi de Ogun, de Ọyọ, de Ọṣun, Ekiti ati Ondo, awọn ijọba wa ko gbọdọ se ojo mọ, ki wọn mura lati ja fawọn eeyan wọn. Iya to n jẹ wa yii pọ, bẹẹ ni inira naa ko si yọ ẹni kan ku. Awọn Fulani yii ko kuku pọ to wa, bi wọn si to wa, wọn ko pọ ju wa lọ. Ki waa ni a oo maa wo wọn niran ti wọn yoo maa fooro ẹmi wa bayii si, lori ilẹ ti awọn baba wa fun wa. Ẹyin ijọba ilẹ Yoruba, ẹ dide o, ọrọ oṣelu kọ leleyii, ẹ dide ki ẹ tun awọn Amọtẹkun yii ṣe, ki wọn le ṣe iṣẹ wọn.
Nitori iku Ọgagun Irefin, ẹyin ọọfisa, ẹ sọrọ soke o
Afi ki awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun Naijiria wa yii tubọ ṣalaye ọrọ iku to pa ọga ologun ṣọja kan, Olubunmi Irefin, lati ipinlẹ Kogi. Ọmọ Yoruba ni, ọkan pataki lo si jẹ ninu iṣẹ ologun. Ọsẹ meji sẹyin ni ọkunrin ṣọja yii sin oku iya rẹ, nibi to si ti n ṣoku naa lọwọ ni wọn ti ni ko maa bọ ni ileeṣẹ ologun fun ipade awọn ọga agba ṣọja. Alọ ni awọn eeyan ọkunrin yii gbọ, abọ ti wọn yoo gbọ, iku rẹ ni awọn ṣọja kede, wọn si ni korona lo pa a, ati pe awọn yoo sinku ẹ lọjọ keji. Awọn ẹbi binu, awọn ara Kogi naa si n binu lọwọlọwọ. Wọn ṣalaye idi ibinu wọn, wọn ni korona ki i paayan laarin ọjọ mẹta, ẹni ti korona yoo ba pa yoo kọkọ ṣaarẹ, o si kere tan, wọn yoo fi bii ọsẹ meji wo tọhun, bi wọn ba fura pe korona lo n ṣe e, ẹni naa yoo wa ni igbele fun ọjọ diẹ fun ayẹwo, lẹyin naa ni wọn yoo too mọ boya korona lo n ṣe e loootọ tabi oun kọ. Awọn ẹgbẹ ọmọ Gbẹdẹ, ni Kogi ni ti Irefin ko ri bẹẹ, ko sẹni to gbọ nigba ti ara rẹ ko ya, laarin ọjọ mẹwaa sira wọn to si kuro ni Kogi ni wọn kede iku rẹ, bẹẹ lawọn ologun ko faaye ayẹwo ẹbi silẹ, wọn ni ki wọn sin oku ẹ kiakia ni. Ọrọ naa ru awọn ẹbi loju, o ru gbogbo eeyan loju, ko si si ohun ti awọn ọga ologun ilẹ yii gbọdọ ṣe ju ki wọn waa ṣalaye bi ọrọ naa ti ri gan-an lọ. Awọn eeyan fẹẹ mọ igba ti korona ti wa lara ọkunrin yii, awọn dokita to tẹesi ẹ, ati idi ti wọn ko fi sọ fawọn ẹbi rẹ ko too jẹ iku ẹ nikan ni wọn gbọ. Loju gbogbo eeyan, iku Ọgagun Irefin lọwọ kan abosi ninu, awọn ọga ṣọja funra wọn ni lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ gan-an. Gbogbo aye n reti o, ẹyin ọọfisa, ẹ sọrọ soke kiakia.