Ẹ sọ fun wọn ki wọn ma dan an wo
Bo ba jẹ Aarẹ Muhammadu Buhari funra ẹ lo n ṣe e, ko tete jawọ. Bo ba jẹ oun kọ, to jẹ awọn ọmọlẹyin rẹ ni, ki oun naa tete pe wọn ko sọ fun wọn ki wọn kuro nibẹ. Bi ko ba ṣe bẹẹ, ọjọ kan n bọ ti ilẹ yii yoo gbina mọ wọn lara, ọjọ naa ko si le jẹ ọjọ kan ti yoo dara. Ijọba apapọ fẹẹ fi tipatipa gba ilẹ awọn ẹlomi-in, ilẹ awọn ọmọ oniluuu fun awọn Fulani ti wọn ri i pe wọn jẹ ẹya wọn, gbogbo ọna ni wọn n wa lati ṣe bẹẹ, nigba ti wọn si ti gbiyanju titi ti ko bọ si i fun wọn, wọn ti tun dide lati gbe ofin tuntun mi-in kalẹ, ofin ti yoo faaye gba ijọba lati sọ gbogbo eti-okun, gbogbo bebe-omi, gbogbo ipado, gbogbo ebute di ti ijọba apapọ. Ko le rara, bi wọn ba ti le ri ofin yii ṣe, kia ni wọn yoo fi ọmọ Hausa kan ṣe minisita nibẹ, ti wọn yoo ni oun ni minisita to n ri si ọrọ eti omi Naijiria, nibẹ ni wọn yoo si ko awọn Fulani si lati maa fi maaluu jẹko. Ofin yii ti wa niwaju ile-aṣofin wa bayii, awọn ọmọ Buhari ni wọn gbe ofin naa wa, pe ki ijọba apapọ gba gbogbo bebe-omi, ebute ati etikun gbogbo lọwọ awọn ijọba ipinlẹ to ni wọn, ko waa di ti ijọba apapọ. Ohun ti eyi tumọ si ni pe gbogbo eti-okun, nibi ti awọn ọmọ oniluu ti n pẹja, ti wọn ti n ṣiṣẹ aje, nibi ti ijọba ipinlẹ n lo fun aaye igbafẹ ati wiwa awọn ohun alumọọni, ijọba apapọ fẹẹ gba a, wọn ni awọn lawọn yoo maa ṣetọju ẹ, ti yoo si di tawọn. Ninu gbogbo iṣoro to wa lọrun ijọba apapọ orilẹ-ede yii, njẹ ko ni i yaayan lẹnu pe ija bi eti-okun ati eti-odo gbogbo yoo ṣe di tiwọn ni wọn tun n ba awọn ipinlẹ ja bayii. Kin ni wọn fẹẹ fi gbogbo agbegbe naa ṣe. Ohun to ṣẹlẹ ni pe ẹgbẹ awọn Fulani onimaaluu ti n pariwo kiri tipẹ pe awọn fẹ ibẹ, o daa fun maaluu lati maa jẹko. Bi ijọba apapọ ba si ti gba ibẹ, nigba to jẹ ọmọ Hausa-Fulani ni wọn yoo fi ṣe minisita, wọn yoo maa gba ilẹ onilẹ pẹlu irọrun ni, ko si le pẹ ti gbogbo eti-okun ati ebute orile-ede yii yoo fi di ti awọn Fulani pata. Ohun ti wọn fẹẹ ṣe nigba ti wọn gbe ofin RUGA jade ti wọn ko ri ṣe naa ni wọn tun gba ọna ẹyin gbe wọle yii, ti wọn fẹẹ gba ilẹ onilẹ fun awọn Fulani onimaaluu wọnyi nigba naa, ki wọn le kari gbogbo ilu, ki wọn ni awọn n fi maaluu jẹko kiri. Igba ti awọn eeyan pariwo pe awọn ko fẹ RUGA yii, igba naa ni wọn too jawọ. Ofin kan naa ti wọn fẹẹ lo laye igba naa ni wọn tun gbe jade yii, ti wọn pe ni ofin iṣakoso bebe-omi gbogbo ni Naijiria. Abadofin naa ti wa niwaju awọn aṣofin, ki wọn sọ ọ dofin lo ku. Pataki to wa ninu ofin yii naa ni pe bii maili mẹwaa tabi ju bẹẹ lọ si ibi ti omi nla ba ti wa, ibẹ yoo di ti ijọba apapọ, wọn yoo si maa lo o bi wọn ti fẹ. Bo ba jẹ ni ilu ti ijọba apapọ n da si ọrọ idagbasoke ni, ti ijọba naa si ti n ṣe daadaa pupọ fun awọn araalu, ko sẹni ti yoo fura tabi binu si wọn ni iru eyi, ṣugbọn kaluku lo mọ pe ọpọlọpọ awọn ohun ti ijọba maa n sọ pe awọn dawọ le bayii ni ki i yọri si rere. Ati pe ko si eto idagbasoke kan ti ijọba apapọ yii ti la silẹ pe awọn fẹẹ ṣe ni awọn eti-bebe omi ilẹ wa ti awọn gomina ti wọn ni ipinlẹ wọn ko ti i ṣe. Ijọba fẹẹ gba okun Eko lọwọ awọn ara Eko, ki wọn gba ọsa Ijẹbu lọwọ awọn ara Ogun, ki wọn gba awọn ibi iwapo lọwọ awọn ara Delta, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Iwa ole ni, iwa ilọnilọwọgba ni, iwa buruku ti yoo dalu ru ni, nitori ohun ti iru eyi yoo jọ loju awọn araalu naa ni pe ete ijọba apapọ lati gba ilẹ wọn fawọn Fulani ni. Iyẹn ni Buhari ṣe gbọdọ ba awọn ọmọ rẹ sọrọ, ki oun naa si kilọ funra ẹ, bi bẹẹ kọ, eyi ti wọn rawọ le yii yoo di ariwo, yoo si da wahala silẹ, yoo si mu iyapa nla ba orilẹ-ede wa.
Abi kinni kan wa lara awọn araabi yii ni
Eyi ti a n sọ niyi ti a ko ti i sọ tan, ti olori ẹgbẹ awọn Fulani onimaaluu ti wọn n pe ni Miyetti Allah, Abdullahi Bodejo, fi sọ pe awọn ti ṣetan bayii lati pin awọn Fijilante Fulani kaakiri gbogbo orilẹ-ede yii, ki wọn le maa ṣọ awọn eeyan awọn. Nigba ti wahala awọn ajinigbe yii pọ ju, to si jẹ awọn Fulani onimaaluu ni won n ba nidii ẹ lawọn ijọba ipinlẹ gbogbo bẹrẹ imura fun eto aabo, ti wọn ni awọn gbọdọ daabo bo awọn eeyan awọn, ṣugbọn igbesẹ yii ko dun mọ ẹgbẹ awọn onimaaluu ninu rara. Ohun to fa eyi ko ye ẹnikan. Boya wọn fẹ ki awọn Fulani maa ji awọn ọmọ Yoruba ati Ibo gbe ni o. Boya wọn fẹ ki wọn maa fi maaluu jẹ oko oloko, ki wọn si maa pa awọn oloko to fi owo ati agbara wọn dako wọn ni o. Boya agbara to si ru bo wọn loju nibi ti wọn ti n pariwo pe awọn lawọn ni Naijiria lo fa a. Ko saa sẹni to mọ ohun to n gun wọn laya galegale, nitori ohun ti kaluku gbọ ni pe ẹgbẹ awọn Fulani onimaaluu naa ni awọn fẹẹ ni fijilante tawọn, awọn fẹẹ ni ẹgbẹ alaabo, awọn yoo da aṣọ fun wọn, awọn ti wọn ba si le gbebọn ninu wọn yoo maa gbebọn rin, wọn yoo si maa mu ohun ija mi-in lọwọ. Ẹgbẹ Miyetti Allah ki i ṣe ijọba ipinlẹ, koda, wọn ki i ṣe ijọba ibilẹ, ẹgbẹ oniṣowo lasan ni wọn, bi tiwọn si ti jẹ lati da ẹgbẹ alaabo sile, ti wọn yoo ni fijilante laarin ilu to lọba to nijoye, ni alaye rẹ ko ti i ye ẹnikẹni. Ṣugbọn nigba to jẹ gbogbo awọn Fulani ti wọn n da maaluu kiri yii ni wọn n gbe ibọn rin, ti awọn araalu si pariwo titi ti ijọba apapọ ko dahun, to jẹ wọn yoo ni wọn fi n daabo bo ara wọn ni, ọna da ti awọn eeyan naa ko ni i maa leri ẹgbẹ fijilante tiwọn. Ki gbogbo ọba ilẹ Yoruba tete dide o, ki awọn ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba naa si kọ, ko ni i si fijilante Fulani nilẹ Yoruba o, ẹni to ba dan an wo, ko jiyan ẹ niṣu ni. Awọn Ibo ti sọrọ pe awọn ko ni i gba fijilante Fulani laaye lọdọ awọn, Gomina Benue naa ti pariwo pe ti oun ba ri fijilante Fulani kan nibi kan, ẹwọn ni yoo ku si. Ki awọn ijọba ilẹ Yoruba naa tete ṣe bẹẹ, nitori fijilante Fulani ko ni i mu alaafia kan ba ilu, wọn yoo pada di ajinigbe, igaara ọlọṣa ati janduku gbẹyin ni. Ẹ ma gba wọn laaye o, ewu nla ni wọn jẹ fun wa.
Awọn alagbara ma mero baba ọlẹ
Gomina ipinlẹ Kano n leri kiri bayii, ohun to si n sọ ni pe oun yoo bu ọwọ lu idajọ apaayan ti wọn da fun Yahaya Sharif lori pe wọn lo kọrin bu Anọbi. Musulumi ni Sharif, iru orin to si kọ to fi bu Anọbi ko ye ọpọ eeyan rara. Bi oun funra rẹ ba jẹ Musulumi, to si kọrin bu olorin ẹsin to n sin, idajọ iru ẹni bẹẹ ko wa wa lọdọ Ọlọrun. Ati pe iru eebu wo ni wọn bu Anọbi lasiko yii ti yoo ju eyi ti awọn ara Mẹkka ati ara Mẹdina bu oun funra rẹ nigba aye rẹ lọ. Ninu itan wo lo wa, tabi ọọkan ibo lo wa ninu Kuraani, nibi ti Ọlọrun ti ni ki wọn pa ẹni to ba kọrin tabi to bu Anọbi, nibo lawọn eeyan yii ti ri idajọ tiwọn. Bo ba waa jẹ loootọ ni, alaaanu ati alaforiji ni gbogbo aye mọ Ọlọrun Ọba si, ki i ṣe ọba ti i tori ẹṣẹ kekere bayii paayan, nitori ẹni to kọrin bu Anọbi loni-in, ti alaye ẹsin ba tubọ ye e, o le kọrin ki Anọbi lọla, to si jẹ orin naa yoo dun kọja, yoo si gbajumọ ju eyi to fi bu ojiṣe Ọlọrun naa lọ. Lọna mi-in, ki lo de ti awọn eeyan yii maa n fẹẹ gbeja Ọlọrun. Ọlọrun ko wa lagbara lati gbeja ara rẹ bi! Bi ẹnikẹni ba ṣe aidaa si Ọlọrun, ẹda ni yoo wa gbeja Ọlọrun bi! Ṣe agbara Ọlọrun ko to lati gbeja ara rẹ ni. Gbogbo ohun to yẹ ki awọn adajo Sharia ti wọn da ẹjọ pe ki wọn pa .. ro ree, ki wọn too ni ki wọn lọọ pa a. Bi awọn ba tilẹ waa ṣe eleyii, ohun ti gbogbo aye ro ni ki Gomina Abdullahi Ganduje ti i ṣe gomina Kano ṣe aforiji fun ọkunrin yii lọwọ ara tirẹ, nigba to lagbara lati ṣe bẹẹ. Ṣugbọn kaka bẹẹ, niṣe loun naa n leri kiri pe oun yoo bu ọwọ lu idajọ naa, wọn yoo si pa ọkunrin olorin Hausa yii lẹsẹkẹsẹ. Bi ẹ ba n wa alagbara ma mero baba ọlẹ, awọn ree o. Ilu yii la wa ti Ganduje n ko owo riba to gba sinu apo, ti wọn ya fidio ẹ, ti wọn si fi han gbogbo aye. Ko sẹni to pa a, koda, ko ṣẹni to mu un, bẹẹ aburu ti oun ṣe fun awọn ara Kano ju eyi ti olorin yii ṣe lọ. Lọjọ wo ni wọn yoo juko pa Ganduje funra ẹ, adajọ wo ni yoo si da a. Bi Ganduje ba pa ọkunrin yii loni-in, awọn eeyan n bọ lẹyin oun naa lọla, oun naa ko si ni i ri idariji nibi kan nigba ti idajọ Ọlọrun ba de.
Ṣebi ẹ ri wọn ni Zamfara
Awọn aṣọfin Zamfara tun n ba kinni kan bọ o. Bi wọn ti n ba a bọ yii, bi a ko ba ri ẹni ṣi wọn lọwọ, bi wọn ba ṣe ofin ti wọn n leri pe awọn tun fẹẹ ṣe yii, wahala mi-in yoo tun bẹrẹ si i ṣẹlẹ nilẹ Hausa o. Ofin mọto wiwa tuntun ni wọn n gbero lati ṣe, ohun ti wọn si fẹẹ ṣe sinu ofin naa ni pe ẹni to ba wa mọto niwakuwa, ki wọn dajọ iku fun un. Họwu, ki la gbe ki lẹ ju! Wọn yoo dajọ iku fun ẹni to wa mọto ẹ niwakuwa, ṣugbọn wọn yoo fi awọn akowojẹ silẹ, wọn yoo maa lọ, tabi ki wọn da ẹwọn ọlọjọ taṣẹrẹ fun wọn. Iru nnkan bayii ko daa. Ofin ti wa nilẹ lati ayebaye, bi eeyan ba wa mọto niwakuwa, bi wọn ba mu un, to si han bẹẹ, wọn yoo ju u sẹwọn ni, wọn si le paṣẹ ko ma wa mọto mọ laelae. Ewo waa ni ti idajọ iku ninu iyẹn. Ṣugbọn ẹ ma wo wọn niran, nitori bi awọn eeyan yii ti ṣe lasiko ti wọn fẹẹ bẹrẹ ofin Sharia ree, bii ere bii ere ni wọn fi da kinni naa silẹ, ti ọrọ naa si pada di ariwo yikayika Naijiria. Ofin naa wa nibẹ bi a ti n sọ yii, to jẹ bi ọmọ talaka kan ba ṣe ohunkohun ni Zamfara, ofin Sharia ni wọn yoo lo fun un, ṣugbọn to jẹ bi ọmọ olowo tabi oloṣelu kan ba ṣẹ si ofin, yoo sọ pe oun ko fẹ Sharia, ofin ijọba apapọ, ofin alakọwe, loun fẹ ki wọn lo foun. O jọ pe awọn alaboosi eeyan pọ ju ninu awọn oloṣelu Zamfara yii, o si jọ pe wọn ti mọ pe awọn eeya won ko gbọn ọgbọn iwe debii pe wọn yoo ko awọn loju lori ofin ti ko ba dara ti awọn ba fẹẹ ṣe. Ohun ti wọn ṣe n ṣe palapala yii ree. Ki gbogbo ẹyin ọlọgbon ilu dide, ki ẹyin ajijagbara tootọ dide, ẹ ja fun wọn ni Zamfara, ki wọn ma gbe ofin aburu kalẹ nibẹ, nitori ti ofin naa ba ṣẹlẹ, yoo kan ọmọ Naijiria gbogbo, afi ẹni ti ko ba wa mọto ẹ de Zamfara nikan. Bẹẹ eeyan ko mọ ohun to le gbeeyan de ọna ipinle Zamfara, nitori rẹ ni gbogbo wa ṣe gbọdọ dide lati ja fun un. Ofin rẹrun-rẹrun leleyii, Ọlọrun o ni i jẹ ko ṣee ṣe fun wọn.