Faith Adebọla
Ootọ lawọn agba n powe pe ‘ori ade ki i sun’ta,’ amọ owe naa ko wọle ni ti ọba alaye yii, Ọsọlọ tilu Ado-Odo, Ọba Mufutau Dosunmu, tori ibi tori ade yii yoo sun kọja ita, ọgba ẹwọn taara ni, latari bile-ẹjọ Majisreeti kan to fikalẹ si agbegbe Iṣabọ, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ṣe gbe idajọ kalẹ pe ko lọọ fẹwọn oṣu mẹfa jura pẹlu iṣẹ aṣekara lori hihuwa to lodi sofin.
Onidaajọ E. O. Idowu, lo la ọba naa mọ keremọnje lọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, o lo jẹbi ẹsun pipe ara rẹ ni ohun ti ko jẹ, hihuwa to le da omi alaafia ilu ru, atawọn ẹsun bii mẹrin mi-in ti wọn fi kan ọdaran ọhun.
Oye Ọsọlọ yii wa lara awọn agba oye ilu Ado-Odo, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, ti gomina ana nipinlẹ naa, Sẹnetọ Ibikunle Amosun sọ di ọba alade, pẹlu awọn mẹrinlelaaadọrin (74) mi-in kaakiri ipinlẹ ọhun lasiko to ku dẹdẹ ki iṣakoso rẹ tẹnu bọpo lọdun 2019.
Amọ, oju-ẹsẹ ti Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti gori aleefa lẹyin Amosun, lo ti wọgi le awọn agba oye ti Amosun sọ dọba ọhun, o ni ipo oloye ti wọn wa tẹlẹ naa ni ki wọn pada si kiamọsa.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọba alaye naa kọri sile-ẹjọ, ti wọn si lawọn gba idajọ kan to da gomina lọwọ kọ lori gbigba ade lori awọn, sibẹ, ijọba to wa lode yii ni ko sohun to jọ ọ, awọn ko fẹẹ gburoo pe ẹnikan ninu wọn n pera ẹ ni Kabiyesi nibikibi.
Ni ti Oloye Dosunmu yii, wọn fẹsun kan an pe o n pe ara ni ọba, bẹẹ lo n dade, to si n tẹpa ilẹkẹ pẹlu irukẹrẹ lọwọ rẹ bii ọba alaye, eyi ti wọn lo ta ko isọri kẹtalelogun, abala keji, iwe ofin ifọbajẹ ati didi oloye nipinlẹ Ogun.
Wọn ni niṣe ni baba naa n da bii ẹdun, to n rọ bii owe, bii ọba gidi, to si tun fi awọn kan bii Alabi Afizu, joye Babalọja Ado, ni ọja Ọba Agaloye, niluu Ado-Odo, loṣu Kẹta, ọdun to kọja, eyi to ta ko isọri ojilerugba le mẹsan-an iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ naa. Wọn tun lọba yii paṣẹ fun alaago ilu lati kede pe kawọn eeyan ma jade laarin asiko kan si asiko mi-in, tori wọn fẹẹ ṣetutu siluu, eyi to lodi sofin.
Bo tilẹ jẹ pe Dosunmu loun ko jẹbi, Agbefọba, Ọgbẹni Adebayọ Adesanya, ni awọn iwa wọnyi ta ko iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Ogun, o si ni ijiya to gbopọn.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajo Idowu ni ẹri fihan pe Ọba Dosunmu jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, o ni ko lọọ ṣẹwọn oṣu kan lori ọkọọkan awọn ẹsun keji titi dori ekeje, eyi ti aropọ rẹ jẹ oṣu mẹfa, ki ẹwọn ọhun si bẹrẹ lati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii. Amọ ṣa, o faaye lati sanwo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta Naira lori ọkọọkan ẹsun naa dipo lilọ sẹwọn silẹ fun un.