O doju ẹ! Ija igboro buruku ṣẹlẹ laarin ilu Ilobu ati Ifọn, ọlọpaa mẹrin lo fara pa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọlọpaa mẹrin, ninu eyi ti DPO Irẹpọdun Divisional Headquarters, wa, la gbọ pe wọn ti fara pa yanna yanna ninu wahala to n waye laarin ilu Ilobu ati Ifọn, nipinlẹ Ọṣun.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu yii, ni wahala aarin ilu mejeeji tun bẹrẹ lẹyin ti awọn eeyan Ifọn kegbajare pe awọn janduku kan lati Ilobu n dena de awọn eeyan awọn, ti wọn si n yinbọn lu wọn.

Ninu wahala ọjọ Wẹsidee yii ni Taye, ọmọ bibi ilu Ẹrin Ọṣun ti pade iku ojiji latari ifarapa to ni lẹyin ti awọn janduku naa yinbọn lu u lẹsẹ.

Nigba to di irọlẹ ọjọ Wẹsidee naa ni wahala bẹrẹ, bi awọn eeyan ilu Ifọn ṣe n pariwo pe awọn eeyan Ilobu n dana sun ile awọn naa lawọn eeyan Ifọn n pariwo pe awọn eeyan Ifọn n dana sun ile awọn.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe lasiko wahala alẹ ọjọ Wẹsidee naa, ọlọpaa mẹrin lo fara pa.

O ni DPO agọ ọlọpaa Irẹpọdun naa wa lara awọn to fara pa naa, awọn mẹrẹẹrin si n gbatọju lọwọ nileewosan.

Ọpạlọla fi kun ọrọ rẹ pe awọn janduku naa tun dana sun mọto ọlọpaa kan lọjọ naa, ṣugbọn alaafia ti n jọba nibẹ.

Amọ ṣa, nigba ti ALAROYE ṣabẹwo si agbegbe naa laaarọ ọjọ Tọsidee ọhun, gbogbo adugbo lo da paroparo, ko si si irinkerindo ọkọ rara.

Iwadii fihan pe eeyan meji; obinrin kan, ọkunrin kan, ni wọn fara gbọta, bi awọn kan ṣe n sọ pe ọta ibọn to n fo kaakiri (stray bullet) lo ba wọn, lawọn miran n sọ pe ibọn awọn agbofinro lo ba wọn.

Ọpọlọpọ dukia ni wọn dana sun laarin ilu mejeeji, bẹẹ ni awọn agbofinro ṣi n lọ kaakiri lati ri i pe alaafia jọba lagbegbe naa.

Leave a Reply