Ọlawale Ajao
Owo ti apapọ rẹ jẹ tiriliọnu kan ati biliọnu marundinlọgọta Naira (₦1.055 trn) nipinlẹ Ogun yoo na lọdun 2025 to n bọ yii.
Eyi ni iye owo to wa ninu akọsilẹ aba eto iṣuna, eyi ti gomina ipinlẹ naa, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, gbe lọ siwaju awọn aṣofin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2024 ta a wa yii.
O han gbangba pe eto ẹkọ pẹlu eto ilera lo jẹ ijọba ipinlẹ yii logun ju lọ, nitori awọn nnkan mejeeji wọnyi ni wọn yoo nawo le lori ju lọ lọdun to n bọ gẹgẹ bo ṣe wa ninu akọsilẹ aba eto iṣuna naa.
Gẹgẹ bii ìfọ́síwẹ́wẹ́ aba eto iṣuna ọhun, eto ẹkọ lo wa nipo kin-in-ni, nitori owo to fi diẹ le ni biliọnu mẹtadinlọgọsan-an (₦177,8358 bn) ni wọn ya sọtọ fun eto ẹkọ nikan, ida mẹtadinlogun (17) leyi si jẹ ba a ba da gbogbo aba eto iṣuna ọdun to n bọ yii ṣi ọna ọgọrun-un (17%).
Eto ilera lo wa nipo keji ninu ohun to jẹ ijọba ipinlẹ Ogun logun. Ida mẹtala apapọ iṣuna ọdun to n bọ, to jẹ biliọnu mẹrinlelaaadoje Naira ati diẹ (₦134,5388) ni wọn pinnu lati na lori eto ilera.
Ni ti iṣẹ idagbasoke ilu, ida mẹfa ninu apapọ owo iṣúná ni wọn ya sọtọ fun un, eyi si ko ida mẹfa ninu ida ọgọrun-un apapọ aba eto iṣuna ọhun.
Nigba to n tọka si diẹ ninu awọn aṣeyọri ijọba rẹ laarin ọdun to n pari lọ yii, Gomina Abiọdun sọ pe ijọba oun ti dawọ le atunṣe ọna nla to ti igboro Abẹokuta lọ si ipinlẹ Eko, eyi ti yoo
tubọ mu igbelarugẹ ba eto ọrọ aje ipinlẹ Ogun daadaa.
O ni laipẹ yii nijọba oun yoo bẹrẹ atunṣe awọn oju titi to wa kaakiri inu igboro awọn ilu gbogbo nipinlẹ naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mo dupẹ fun ifọwọsowọpọ ẹyin aṣofin pẹlu ijọba mi. Mo si fẹ ki iru ifọwọsowọpọ yii tẹsiwaju fun anfaani awọn ara ipinlẹ yii.
“Inu mi yoo dun ti igbimọ ẹyin aṣofin ba le fọwọsowọpọ pẹlu mi lati fọwọ si aba eto iṣuna yii fun idagbasoke ipinlẹ wa.”
Diẹ ninu awọn to peju pesẹ sibi eto naa ni Igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Nọimọt Salakọ-Oloyede; Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, atawọn leekan leekan mi-in lawujọ.
Fun igba akọkọ ninu itan iṣejọba ipinlẹ Ogun, gbogbo awọn aṣofin da owo nla jọ, wọn si ra ẹṣin nla kan, wọn fi ta Gomina Abiọdun lọrẹ lẹyin ti wọn tẹwọ gba aba eto iṣuna ọhun lọwọ ẹ tan.
Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, funra rẹ lo lewaju awọn aṣofin yooku ti wọn gba gomina ati gbogbo awọn eeyan naa lalejo. Oun naa lo si fa okun ẹṣin ọhun le gomina lọwọ lati fi idunnu wọn ha si i fun ọna to n gba ṣejọba.
Nigba to n fi idunu ẹ han si ẹbun pataki naa, Ọmọọba Abiọdun sọ pe, “Ki i ṣe ohun tuntun ni pe ki gomina lọ sileegbimọ aṣofin, ṣugbọn ohun ti ko ṣẹlẹ ri ni ki gomina gba ẹbun bọ.
Itumọ ẹbun ẹṣin yii naa si ni pe ki n tubọ maa ṣiṣẹ takuntakun.”
Lẹyin naa ni gomina ta le nnkan irinṣẹ rẹ tuntun naa, to si bẹrẹ si i jo lori ẹṣin. Eyi pe awọn aṣofin nija, awọn paapaa yọ ọwọ ijo gẹngẹ niwaju gomina ẹlẹṣin tuntun, gbogbo wọn bẹrẹ si i jo ijo ayọ, ni ireti pe eto iṣejọba ọdun 2025 to n bọ lọna yii yoo san gbogbo ara ipinlẹ Ogun si rere.