Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Beeyan ba gẹṣin ninu ajafẹtọọ ẹṣin Iṣẹṣe nni, AbdulAzeez Adegbọla, ti gbogbo eeyan mọ si Ta-ni-Ọlọrun, ko ni i kọsẹ rara. Eyi ko ṣẹyin bi ọkunrin naa ṣe darapọ mọ awọn to n fi mọto ṣe ẹsẹ rin pẹlu iranlọwọ ẹlẹyinju aanu kan, Kabiyesi Ọba Ilu Ẹlla, tileeṣẹ rẹ n ṣe iranwọ fun awọn to ku diẹ ka a to lawujọ, iyẹn ‘Ọba Ẹlla Foundation’.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ni Ọba ilu Ẹlla mu inu rẹ dun pẹlu bo ṣe ra mọto Toyota Highlander alawọ funfun to rẹwa daadaa fun un, ti wọn si kọ Ọba Ẹlla Foundation si mọto naa lara.
Ẹgbọn Ta-ni-Ọlọrun lobinrin, Hajia Jubril Ọmọlara, to ba ALAROYE ṣọrọ lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni inu ayọ ati idunnu ni gbogbo mọlẹbi AbdulAzeez Adegbọla Ta-ni-Ọlọrun wa bayii, awọn n yayọ pe o gba ominira ni oore ayọ ti mọto tun wọle wẹrẹ. O ni awọn dupẹ lọwọ Ọba Ilu Ẹlla, to ṣe e loore banta banta yii, bẹẹ ni wọn fẹmi imoore wọn han si awọn afẹnifẹre ti wọn duro ti i lasiko to wa lahaamọ.
Yatọ si Ọmọlara ọpọ awọn mi-in bẹẹ ni wọn ti ba Ta-ni-Ọlọrun yọ, wọn ni ẹmi rẹ yoo lo o, ole ko si ni i gbe e.
Awọn mẹrin ọtọọtọ ni awọn aafaa to wọ Ta-ni-Ọlọrun lọ sile-ile-ẹjọ, awọn naa ni Aafaa Okutagidi, Ẹgbẹ ogo Ilọrin, Aafaa Labeeb Lagbaji ati ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Mọdirasatul Muhammad, eyi ti Ọjọgbọn Abubakar Aliagan jẹ olori fun, ti awọn adajọ si ti gba beeli ẹjọ mẹrẹẹrin eyi to mu ko gba ominira.
Tẹ o ba gbagbe, lọṣẹ to kọja yii, ni Ta-ni-Ọlọrun gba ominira lẹyin to lo oṣu mẹta lahaamọ niluu Ilọrin, latari ẹsun ibanilorukọ jẹ ati didana sun Kurani tawọn aafaa Ilọrin fi kan an.