Jọkẹ Amọri
Looootọ lo ti pẹ ti awọn eeyan ti n gbe e pooyi ẹnu pe ko jọ pe ajọṣepọ to dan mọran wa laarin awọn oṣere ilẹ wa meji ti wọn jẹ tọkọ-tiyawo nni, Bukọla Awoyẹmi ti gbogbo eeyan mọ si Arugba ati Damọla Ọlatunji, toun naa jẹ oṣere.
Ibi tara ti n fu awọn mejeeji ni bo ṣe jẹ pe wọn ko ki ara wọn lasiko ayẹyẹ ọjọọbi wọn, wọn ko si tun ri wọn papọ bi wọn ṣe jọ maa n ṣe tẹlẹ pẹ̀u awọn ọmọ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ ni ko ka eleyii si, bẹẹ ni awọn oṣere mejeeji yii naa ko sọrọ jade lati sọ pe bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ lori pe igbeyawo wọn ti tu ka, ti onikaluku si ti n lọ lọtọọtọ.
Ṣugbọn gbogbo awuyewuye yii ti wa sopin bayiin pẹlu bi Bukọla Arugba ṣe gbe iwe ipinya laarin oun ati Damọla ti lọọya rẹ kọ sori ikanni Instagraamu rẹ lati sọ fun gbogbo eeyan pe oun ko si pẹlu baba ọmọ oun naa mọ, ati pe awọn mejeeji ti pin gaari.
Ninu lẹta naa ti agbẹjọro rẹ kọ ọhun lo ka bayii pe, ‘‘Awa gẹgẹ bii agbẹjọro Arabinrin Bukọla Awoyẹmi ti gbogbo eeyan mọ si Arugba n fi asiko yii sọ fun yin pẹlu aṣẹ ti a gba lati ọdọ onibaara wa ka too gbe ọrọ yii jade pe a n fi asiko yii kede pe a fẹ ki ẹ fi eleyii sọkan pe onibaara wa, Bukọla Awoyẹmi, ati Damọla Ọlatunji ko ni ajọṣepọ kankan papọ mọ. Onikaluku ti n lọ nilọ rẹ, lai ni ikunsinu kankan sira wọn. Ko sigba kankan ti awọn mejeeji ṣegbeyawo, ṣugbọn Ọlọrun fi ibeji ta wọn lọrẹ.
‘‘Awọn mejeeji ni wọn ti jọ fohun ṣọkan pe awọn yoo ma ri si itọju awọn ọmọ mejeeji yii’’.
Ohun ti awọn kan n sọ, ṣugbọn ti ALAROYE ko le fidi rẹ mulẹ ni pe oṣere-kunrin naa ti fun ẹlomi-in loyun nita.
Bẹ o ba gbagbe, ki Damọla too fẹ Arugba lo ti kọkọ ṣegbeyawo pẹlu ọmọbinrin kan, Raliat Abiọdun Ṣobọwale, lọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2013.
Igbeyawo naa ko ju ọdun kan lọ to fi tuka. Ẹsun agbere ni ọmọbinrin naa fi kan Damọla. Bukọla Awoyẹmi ti Damọla pada fẹ silẹ, ti wọn si ti kọ ara wọn bayii ni ọmọbinrin to n gbe niluu oyinbo nigba naa fẹsun kan pe o n ṣe wọle-wọde pẹlu ọkọ oun, eyi to si pada fa ipinya laarin wọn.