Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni ile-ẹjọ Majisireeti kan to filu Ilọrin ṣe ibujokoo gba beeli Abdulazeez Adegbọla, ti inagi jẹ rẹ n jẹ Ta-ni-Ọlọrun, pẹlu miliọnu meji Naira, lẹyin ọjọ mọkandinlaaadọrun-un (89) lọgba ẹwọn.
Ta-ni-Ọlọrun lo ti n jẹjọ lawọn ile-ẹjọ mẹrin ọtọọtọ, Upper Area Court ati Majisreeti, niluu Ilọrin, lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an lọna mẹta ọtọọtọ. Ẹsun jijo Kuraani ni wọn fi kan an nibi ẹjọ to gbẹyin ti wọn tun pe e.
Tẹ o ba gbagbe, ninu ẹjọ mẹrin to n jẹ ni wọn ti gba beeli meji, iyẹn eyi ti Aafaa Okutagidi pe e ati eyi ti ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Ogo Ilọrin pe e, ti ko si tete ri beeli ẹjọ meji yooku gba, eyi to n da a duro si ọgba ẹwọn. Ṣugbọn ni bayii, wọn ti gba beeli ẹjọ meji yooku, eyi ti Aafaa Labeeb Lagbaji ati ẹgbẹ Mọdirasatul Muhammad, pe e.
Ọkan lara awọn agbẹjọro to n duro fun un, Ademọla Banks, lo tun gbe gbe iwe beeli rẹ lọ siwaju ile-ẹjọ Majisireeti l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, pe ki adajọ wo onibaara rẹ ṣe, ko fun un ni beeli, ko maa waa jẹjọ lati ile rẹ, nitori pe onibaara oun ti rawọ ẹbẹ si awọn to ṣẹ fun idariji, to si ti kọwe si awọn olupẹjọ pe ki wọn dariji oun.
Agbẹjọro to n soju Aafa Labeeb ati Mọdirasatul Muhammad, Kayọde Ọlatẹju, ko ta ko ẹbẹ yii, ṣugbọn o gba ile-ẹjọ niyanju lati gbe awọn ilana ti yoo mu olujẹjọ naa maa yọju sile-ẹjọ kalẹ.
Majisireeti Muhammad Adams, gba si awọn mejeeji lẹnu, o fun olujẹjọ naa ni beeli miliọnu meji Naira (N2,000,000), ati oniduuro meji, ti ọkan ninu wọn gbọdọ jẹ ibatan rẹ.
Gẹgẹ bi Adajọ Muhammad Adams, ṣe la a kalẹ, awọn oniduuro yii gbọdọ ni dukia ni agbegbe ile-ẹjọ tabi ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si gbọdọ fi iwe dukia naa ranṣẹ si ile-ẹjọ. Bakan naa ni olujẹjọ gbọdọ fi ami idanimọ ati iwe irinna rẹ silẹ sile-ẹjọ.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni, ọdun to n bọ.