Ọlawale Ajao, Ibadan
Afaimọ ni oluṣọ-aguntan kan, Ajihinrere Samson Afọlabi, ko ni i ṣe diẹ ninu iṣẹ ihinrere rẹ lọgba ẹwọn, iyẹn bo ba jẹbi ẹsun agbere ti wọn fi kan an.
Ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) ti wọn n pe ni Pasitọ Samson yii ni wọn lo ki obinrin ẹni ọdun mejidinlogoji (38) kan, Abọsẹde, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri mọlẹ ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, to si ko ibasun fun un karakara.
Oun pẹlu iya kan to n jẹ Oluwatosin Akintunde ni wọn jọ fẹsun to ni i ṣe pẹlu iwa agbere ọhun kan nile-ẹjọ Majisreeti to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.
Nigba to n ṣalaye idi to ṣe gbe awọn olujẹjọ naa lọ si kootu niwaju adajọ, ọlọpaa to gbe awọn afurasi ọdaran naa lọ sile-ẹjọ, fìdi ẹ mulẹ pe iya ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta (54) yii lo fi ọrọ didun tan obinrin naa fun Pasitọ Samson, ti iyẹn fi ribi ko ibasun fun un.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ki i ṣe pe o ti ọkan obinrin ti wọn ba laṣepọ yii wa lati ṣe ‘kinni’ naa, olujẹjọ keji, Oluwatosin, tan an lọ sile Samson laduugbo Oke-Ado, n’Ibadan, ti iyẹn fi huwa to lodi sofin yẹn fun un.
Bẹẹ si ree, o lodi si okoolerugba ati mẹrin (224), abala keji ofin ipinlẹ Ọyọ ọdun 2000 to de iwa ọdaran lati mu ki ẹnikẹni lọwọ ninu ibalopọ laijẹ pe kinni naa ti inu ọkan onitọhun funra rẹ wa.”
Lẹyin atotonu agbẹjọro awọn olujẹjọ mejeeji, adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Serifat Adeṣina, gba beeli ẹni kọọkan wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọọgọrun-un Naira (₦100,000) ati oniduuro meji meji.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ naa ṣi ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii.