O gbẹnu tan! Eyi lawọn gomina ti EFCC kede pe wọn ko obitibiti owo jẹ lasiko iṣejọba wọn

Faith Adebọla

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati jibiti lilu nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti kede pe o kere tan, mejidinlọgọta lara awọn to ti ṣe gomina tẹlẹri lorileede yii ni iwadii awọn ti fidi ẹ mulẹ pe wọn kowo rọgun-rọgun jẹ nigba ti wọn fi wa lori aleefa nipinlẹ koowa wọn, aropọ owo ti iye rẹ to tiriliọnu meji o le biliọnu mẹtadinlaaadọwaa Naira (N2.187t) ni wọn jale rẹ.

Ninu atẹjade kan ti EFCC fi lede lori ikanni ayelujara wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni wọn ti to orukọ ati ipinlẹ awọn gomina tọrọ kan lẹsẹẹsẹ, wọn lawọn ṣi n tanna wodi gbogbo wọn lọwọ.

EFCC ni awọn gomina ti wọn n sọ yii ki i ṣe awọn to ṣẹṣẹ kuro nipo nikan, amọ awọn to ti n ṣakoso bọ latigba ti Naijiria ti kuro labẹ ijọba ologun lọdun 1999 ni. Ajọ naa ni, o kere tan, gomina bii aadọsan-an (170) la ti ni lati 1999, titi kan awọn mejidinlogun ti wọn ṣe adele gomina, awọn mẹrinlelaaadọfa (114) ti wọn ṣe saa meji meji, atawọn ti ile-ẹjọ ge saa iṣakoso wọn kuru, ti wọn yọ nipo, atawọn ti wọn ti ku paapaa. Amọ mẹrin pere laarin awọn mejidinlaaadọta ni EFCC ṣi ṣaṣeyọri lati gba idajọ lodi si wọn, tori ẹjọ awọn mẹrin ọhun ti rinrin-ajo de ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, nibi ti ẹjọ maa n pẹkun si, ti wọn si ti da wọn lẹbi.

Awọn mẹrin ọhun ni Oloye Lucky Igbinedion tipinlẹ Edo, Oloogbe DSP Alamieyesegha ni Bayelsa, Alagba Jolly Nyame ti ipinlẹ Taraba, ati Joshua Dariye lati Plateau. Ẹ oo ranti pe lasiko iṣejọba Muhammadu Buhari to kọja lo yọ Dariye ati Nyame kuro logba ẹwọn Kuje, nibi ti wọn ti n faṣọ penpe roko ọba lọwọ.

Orukọ awọn gomina to gbọn owo gbẹ ni koto ọba ipinlẹ wọn ọhun ati iye ti wọn ṣiro si wọn lọrun ni: Oloogbe Abubakar Audu ipinlẹ Kogi, biliọnu mọkanla din diẹ (N10.966 bn), Yahaya Bello lati Kogi, ọgọrin biliọnu le diẹ (N80.2 bn), Idris Wada, Kogi (N500m). Ni ipinlẹ Ekiti ti eeyan inu rẹ ko fi bẹẹ to nnkan, Peter Ayọ Fayoṣe, biliọnu meje din ṣiun (N6.9 bn), nigba ti Kayọde Fayẹmi, ipinlẹ Ekiti, biliọnu mẹrin Naira (N4bn), Rashid Ladoja, Ọyọ (4.7bn), Christopher Alao-Akala, Ọyọ (N11.5 bn), Chimaroke Nnamani lati Enugu, biliọnu marun-un o le (N5.3 bn) lo sọnu mọ ọn lọwọ; Sullivan Chime lati Ẹnugu kan naa, miliọnu irinwo le aadọta (N450 million) ni tiẹ. Theodore Orji atawọn ọmọ rẹ nipinlẹ Abia, ọtalelẹgbẹta biliọnu din diẹ (N551 bn)

Awọn yooku ni Abdullahi Adamu, Nasarawa, (N15bn)

Joshua Dariye, Plateau, (N1.16 bn)

Timipre Sylva, Bayelsa, (N19.2 bn)

Danjuma Goje, Gombe, (N5bn)

Aliyu Wamakko, Sokoto, (N15 bn)

Sule Lamido, Jigawa, (N1.35 bn)

Saminu Turaki, Jigawa, (N36bn)

Bello Matawalle, Zamfara, (N70 bn)

Lucky Igbinedion, Edo (N4.5 bn)

Musa Kwakwanso, Kano (N10bn)

Peter Odili, Rivers, (N100 bn)

Jolly Nyame, Taraba, (N1.64 bn)

James Ngilari, Adamawa, (N167 m)

Abdulaziz Yari, Zamfara, (N84 bn)

Godswill Akpabio, Akwa Ibom, (N100bn)

Abdul Fatah Ahmed, Kwara (N9 bn)

Ali Mode-Sheriff, Borno (N300bn)

Willie Obiano, Anambra (N43 bn)

Ibrahim Dankwambo, Gombe (N1. 3bn)

Darius Ishaku, Taraba (N39bn)

Ramalan Yero, Kaduna (N700m)

Achike Udenwa, Imo (N350m)

Rochas Okorocha, Imo (N10. 8bn)

James Ibori, Delta (N40 bn),

DSP Alamieyeseigha, Bayelsa (N2.655bn)

Gabriel Suswam, Benue (N3. 111bn)

Samuel Ortom, Benue (N107bn)

Murtala Nyako, Adamawa (N29bn)

Abdulkadir Kure, Niger (N600m)

Babangida Aliyu, Niger (N4bn)

Ibrahim Shekarau, Kano, (N950m)

Adamu Aliero, Kebbi, (N10bn)

Usman Dakingari ati iyawo rẹ, (N5. 8bn)

Attahiru Bafarawa, Sokoto, (N19. 6bn)

Jonah Jang, Plateau (N6.3bn)

Aliyu Doma, Nasarawa, (N8bn)

Tanko Al’Makura, Nasarawa (N4bn)

Boni Haruna, Adamawa, (N93bn)

Bindow Jibrila, Adamawa (N62bn)

Adamu Muazu, Bauchi, (13bn)

Isa Yuguda, Bauchi, (N212bn)

Mohammed Abubakar, Bauchi, (N8. 5bn).

Leave a Reply