O gbẹnu tan o, ẹgbọn baba Mohbad naa ti jade sọrọ, awọn ohun to sọ kọja bẹẹ

Adewale Adeoye

Bi onifa kan ba gbe ọpẹlẹ rẹ ṣanlẹ to sọ pe ija to n lọ laarin ẹbi Baba Mohbad ati iyawo ọmọ rẹ maa too pari, o yẹ ki wọn sọ fun oniṣegun ọhun pe irọ nla lo n pa, nitori pe ọrọ naa ti di egbinrin ọtẹ bayii, bi wọn ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru. Obinrin kan to pe ara rẹ ni ẹgbọn Baba Mohbad, lo tun bọ sita bayii, to si bẹrẹ si i sọ awọn ọrọ ti ko ṣe e gbọ nipa iya to bi Mohbad ati iyawo rẹ, Ọmọwunmi.

Ẹgbọn Alagba Joseph Alọba yii sọ pe gbogbo aluwala ologbo ti iya oloogbe naa n ṣe, to n pariwo kiri pe ki wọn jẹ ki wọn sin oku ọmọ oun, ati pe baba Mohbad lo n da wọn duro ti ko ti i jẹ ki awọn sin in, ọgbọn ati kẹran jẹ lasan ni. O ni ki wọn yee ba baba Mohbad wi, ki wọn fi i silẹ.

Iya yii ni ki i ṣe pe obinrin naa nifẹẹ ọmọ rẹ to bẹẹ lo fi n pariwo eke to n pa pe baba oloogbe ni ko gba ki wọn sinku ọmọ rẹ gẹgẹ bo ti ṣe fẹsun kan aburo oun lori fidio kan to gbe jade.

O ni, ‘‘Gbogbo ohun ti mo n sọ pata nipa Iya Mohbad yii lo da mi loju ju ada lọ, ki i ṣe pe o nifẹẹ oloogbe to bẹẹ gẹ lo ṣe n pariwo tabi sunkun ẹlẹya kaakiri bayii, ki i ṣe obi to daa rara, ẹni to jẹ pe ṣe lo gbagbe oloogbe naa ati aburo rẹ silẹ, to si lọọ fẹ ọkọ miiran lai bikita pe awọn ọmọ ọhun kere lọjọ ori. Oniṣina ni, ko mọ ọn kọ rara, ko sẹni ri ko le tẹdii ẹ silẹ fun. Adogan ni, ko sẹni ti ko le to igi si i. Eyi gan-an lo fa a to fi kuro nile aburo mi nitori pe ọkunrin miiran lo fun un loyun to fi sa lọ nigba naa.

‘‘Ko si jọ mi loju rara pe ọrọ oun ati iyawo ọmọ rẹ wọ daadaa bayii, ṣe awọn agba bọ, wọn ni, ‘ẹgbẹ ẹyẹ lẹyẹ n wọ tẹle lẹyin’. Oniranu kan naa lawọn mejeeji yii ni ọrọ wọn ṣe wọ, ti ko fi sẹnikankan to ri aarin wọn rara. Ṣe lo yẹ ki Iya Mohbad faṣọ boju, ọrọ ko tọ si i lẹnu rara, o niye igba ati ọdun to fi sa tẹle ọkunrin miiran lọ. Oyun to ni fọkunrin ajoji nigba to wa lọdọ baba oloogbe lo fi sa kuro lọdọ ọkọ rẹ, ko si boju wẹyin rara, afi igba tọmọ naa tojuu bọ daadaa. Koda, ọmọ ọhun ti figba kan kọ ọ ninu awo orin rẹ kan pe fọdun mẹwaa gbako loun ko fi foju kan iya oun rara, ṣe abiyamọ gidi kan a waa ṣe bo ti ṣe yẹn.

‘‘Ọrọ oun ati Ọmọwunmi dọgba lẹ ko ṣe gbọ ariwo ija laarin awọn mejeeji rara. Wọn ko ṣe mi o gba ri, ko sẹni ti ko le ba wọn sun, beeyan pe wọn ni aja, onitọhun ko ṣiṣọ rara, ẹni o ri lo ba lọ lọrọ wọn’’.

Inu ọpọ awọn ololufẹ ọmọkunrin yii ni ko dun si bi awọn mọlẹbi naa ṣe n ba ara wọn ja lori iku ọmọ naa.

Leave a Reply