O gbẹnu tan: Shaibu ki ọmọ to bi mọlẹ, o ba a sun karakara

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Kabak, nijọba ibilẹ Mubi-South, nipinlẹ Adamawa, ti mu  baale ile kan, Ọgbẹni Auwal Shaibu, ẹni ọdun mejilelogoji. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fipa ba ọmọbinrin rẹ ti ko ju ọdun mẹsan-an lọ sun leyin to mu ọti amupara yo tan lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe Abilekọ Asman Isa, ti i ṣe iya ọmọ ọhun lo lọọ fọrọ ọkọ rẹ to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wọn to wa lagbegbe naa, tawọn yẹn si tete waa fọwọ ofin mu un lọ sọdọ wọn.

Odọ awọn ọlọpaa ọhun ni Shaibu wa to fi jẹwọ pe loootọ, oun loun fipa ba ọmọ oun sun lẹyin toun muti yo tan lọjọ naa, ati pe abamọ nla gbaa lọrọ ọhun jẹ foun bayii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Nguroje, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ naa, C.P Dankombo Morris, ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, to si ti paṣẹ pe ki awọn ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun daadaa, lẹyin naa ni kawọn foju baba naa bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply