Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Obinrin oniṣowo kan ti wọn porukọ rẹ ni Patience, ni wọn pa nipakupa lasiko to n pada sile rẹ lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.
Obinrin ọmọ bibi ipinlẹ Delta ọhun ni wọn lawọn amookunsika kan da lọna lagbegbe Kajọla, loju ọna Ọda, ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ naa.
ALAROYE gbọ pe ọmọ mẹrin ni Patience ti bi, bẹẹ lo tun n ṣe iṣẹ aṣerunlọsọọ ninu Ọja Ọba to wa l’Akurẹ.
Awọn apaayan ọhun ni wọn tọ ipasẹ obinrin naa titi debi ti wọn pa a si lasiko to n lọ sibi ọrọ okoowo kan ti wọn pe e si ni Iyana Kajọla.
Ọkan ninu awọn eeyan oloogbe ọhun to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ni awọn ọmọ bibi ipinlẹ Delta ti wọn filu Akurẹ ṣe ibugbe ti pade lati jiroro lori iṣẹlẹ naa, o ni oun to da awọn loju saka ni pe ọrọ okoowo ti wọn pe e si ni wọn tori ẹ pa obinrin naa.
Ọkunrin naa ni awọn to ṣiṣẹ ibi ọhun ko laaanu rara, nitori ipa ika ati ọdaju ni wọn pa a, o ni ṣe ni wọn gun un lọbẹ laya titi ti wọn fi ge ori ọmu kan ja.
Iya ọlọmọ mẹrin ọhun lo ni awọn ti lọọ tọju rẹ si mọṣuari kan l’Akurẹ titi ti awọn yoo fi mọ igbesẹ to kan lati gbe.
Nigba to n fi idi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami ni loootọ loun gbọ nipa iku obinrin naa, bo tilẹ jẹ pe ko sibi ti wọn ti fi to awọn agbofinro leti kawọn ẹṣọ Amọtẹkun too da si i.