Jọkẹ Amọri
Bo tilẹ jẹ pe ipolowo fiimu rẹ ti yoo jade ninu oṣu yii ni arẹwa oṣere ilẹ wa nni, Merxy Aigbe ati ọkọ rẹ, Kazeem Adeoti n ṣe lasiko yii ti oun ati ọkọ rẹ si ti n gbe fidio oriṣiiriṣii jade lati polowo sinima ọhun. Ṣugbọn nnkan ti oṣere naa ko ro ti ba eyi to n ro jẹ bayii pẹlu bi ina nla ṣe ṣẹ yọ ninu ile nla to kọ si Magodo, nipinlẹ Eko, ti o si jo gbogbo dukia to wa nibẹ kanlẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu yii.
Ọpọ awọn oṣere ni ko mọ pe ohun to lagbara bẹẹ sẹlẹ si Mercy, afi bi oṣere naa ṣe gbe fidio ajoku ile naa sori ayelujara, to si kọ ọ sibẹ pe ‘Aliamdulillahi, ẹmi kankan ko ba ofo naa lọ.
Lasiko yii lawọn to ri fidio naa bẹrẹ si i ba a kaaanu nitori gbogbo yara to wa ninu ile naa ni ina ọhun fọwọ ba, to si jo gbogbo awọn dukia olowo iyebiye to wa nibẹ gburugburu.
Ọpọlọpọ awọn oṣere ẹgbẹ ẹ ni wọn ti n ba a daro, ti wọn si n ki i, bẹẹ ni wọn n ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹnikankan ko ba iṣẹlẹ naa lọ, ti wọn si n gbadura fun un pe ko ni i ṣofo ẹmi.
Ọkan ninu awọn oṣere to kọkọ ki Mercy ni Toyin Abraham, o jọ pe ko mọ pe ohun to ṣẹlẹ si iyawo Kazeem Adeoti yii lagbara to bẹẹ. Nigba to ri fidio ile naa lo waa n sọ pe, ‘abajọ to o fi n sunkun lori foonu.’
Bakan naa ni Iyabọ Ojo ti kọ ọrọ imulọkanle si arẹwa oṣere yii ati ọkọ rẹ. O ki i pe ko ni i ṣofo ẹmi, bẹẹ lo ni Ọlọrun yoo bo wọn laṣiiri lati ko eyi to daa ju ile to jo yii lọ.
Iyabọ ni, ‘’Arabinrin mi daadaa, Mercy Aigbe ati Arakunrin mi to nirẹle daadaa, Kazeem Adeoti, o ba mi lọkan jẹ lati gbọ nipa adanu to ṣẹlẹ si ile yin. Ọkan mi wa pẹlu yin niru asiko tẹ ẹ n la kọja yii. Mo fẹ kẹ ẹ mọ pe Ọlọrun wa pẹlu yin, Yoo si ran yin lọwọ lati kọ ile mi-in to daa ju bayii lọ. Adanu yii ki i ṣe opin ohun gbogbo.
‘’Bakan naa lo jẹ ayọ ọkan mi pe ẹnikẹni ko ku ninu ijamba ina naa, ati pẹlu eyi, ireti ọjọ ọla to dara wa fun yin. Mo fẹ ko o ni idaniloju atilẹyin mi ni asiko to le ti ẹ n la kọja yii’’.
Lara awọn oṣere mi-in to tun ti ki Mercy lori iṣẹlẹ to jo dukia olowo nla nina ọhun ni Kẹmi Korede, Adeniyi Johnson atawọn mi-in bẹẹ lọ.
Bakan naa lawọn ololufẹ arẹwa oṣere yii lori ayelujara ti n ki i, ti wọn si n ṣadura fun un pe ile ọba to jo ni ọrọ naa yoo jẹ fun un, ẹwa nla ni yoo bukun ile ọhun.