O ma ṣe o ! Aṣofin Kwara ku lojiji

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn kede iku adari ileegbimọ aṣofin, to tun jẹ oludije dupo lẹẹkeji  funpo yii kan naa lẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), Họnarebu Abubakar Ọlawọyin Magaji, pe o jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta loke eepẹ.

ALAROYE gbọ pe Mọgaji yii lo n ṣoju ẹkun Aarin Gbungbun Ilọrin, nileegbimọ aṣofin Kwara, to si ti n mura, bẹẹ lo n polongo ibo fun eto idibo ti yoo waye ninu oṣu Keji, ọdun yii, nitori o fẹẹ pada sile naa lẹyin to ba lo saa akọkọ tan. Ṣugbọn lojiji ni wọn kede iku rẹ lẹyin aisan ranpẹ.

Ẹmaya ilu Ilọrin, to tun jẹ Alaga awọn lọba-lọba nipinlẹ Kwara, Alaaji Dokita Ibrahim Sulu-Gambari CFR, ti kẹdun pẹlu Gomina Abdurazaq, iyawo oloogbe, awọn ọmọ, gbogbo ẹbi Magajin Geri ati gbogbo Ilọrin lapapọ. Ẹmia gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere, ko si rọ gbogbo mọlẹbi loju.

Leave a Reply