O ma ṣe o! Abilekọ kan ja bọ lẹyin ọkada, lo ba gbabẹ ku

Gbenga Amos, Abẹokuta

Iṣẹlẹ a-gbọ-bomi-loju lo ṣẹlẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, nibi ti abilekọ kan ti dagbere faye. Ọkọ rẹ lo fi ọkada Bajaj, ti nọmba rẹ jẹ TTN 08 VG, gbe e, to si jokoo sẹyin ọkunrin naa pẹlu ọmọ wọn, lasiko ti wọn n lọ si ṣọọṣi laduugbo Fajol, agbegbe Ọbantoko, niluu Abẹokuta.

Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, ṣalaye pe iṣẹlẹ buburu yii waye lasiko ti ọkọ oloogbe fẹẹ sare pẹwọ fun ọkada to fẹẹ kọ lu wọn lati iwaju. Ọkada to n bọ niwaju, to si jọ pe o fẹẹ rọ lu wọn lọkunrin naa fi sare pẹwọ, ti iyawo ẹ to jokoo sẹyin si ja bọ latari ẹru biba ati bi ko ṣe jokoo daadaa tẹlẹtẹlẹ, oju-ẹsẹ to ṣubu naa lo dagbere faye. Ṣugbọn ohun to ba ni lọkan jẹ ni pe ọkada keji to fẹẹ rọ lu tọkọ-taya naa ko duro ṣugbaa wọn, niṣe lo sa lọ”.

Agbẹnusọ ajọ to n ri si igboke-gbodo ọkọ nipinlẹ Ogun, Ogun Traffic Compliance and Enforcement Corps (TRACE), Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe iwakuwa ẹni to wa ọkada lo jẹ ki ọwọ ẹ tase, to fi tibẹ sọ ijanu rẹ nu, eyi to pada ṣokunfa bi obinrin naa ṣe ṣubu, to tun fori gbalẹ nibi to ja bọ si, to si gbabẹ ku lojiji.

O tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa ti wọ ọkada naa kuro loju titi fun iwadii to peye, awọn mọlẹbi oloogbe si ti gbe oku ẹ kuro nibẹ.

Nigba to n ranṣẹ ibanikẹdun sawọn mọlẹbi oloogbe, Akinbiyi gba awọn ọlọkada nimọran lati maa ṣe suuru, ki wọn si maa ṣọrapẹlu ere asapajude lati dena iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

Leave a Reply