O ma ṣe o, agbara ojo gbe ọmọọdun mẹrin lọ l’Ekoo

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n ko iroyin yii jọ ni awọn mọlẹbi kan ṣi n wa oku ọmọ wọn, Oloogbe Chukwuemeka Okoro, tomi gbe lọ lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii. Wọn ni agbara ojo to rọ lọjọ yii lo gbe ọmọ naa lọ.

Gẹgẹ bi akọroyin Punch ṣe sọ, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu yii, ni arọọda ojo kan waye lagbegbe Ọgba. Wọn ni lasiko ti ojo to lagbara naa n rọ lọwọ, ni ọmọ naa to duro lẹgbẹẹ koto idaminu kan to wa niwaju ita yii ni ẹsẹ rẹ yẹ sinu koto idaminu nla kan (Canal) to wa niwaju ile wọn ọhun laduugbo Noble, ni Onibata, niluu Ọgba-Ikeja, nipinlẹ Eko.

Loju-ẹsẹ si ni agbara ojo ọhun ti gbe ọmọ ọhun lọ patapata, ti ko sẹni to lanfaani lati doola ẹmi rẹ.

Ọpọ awọn araadugbo naa ni wọn jade lọjọ Ẹti, Furaidee, ojọ kẹrinla, oṣu yii, lati ran awọn obi ọmọ ọhun lọwọ, ki wọn le ba wọn wa oku Chukwuemeka nibi ti agbara ojo gbe e lọ, ṣugbọn ti ko so eeso rere.

Baba ọmọ naa, Ọgbẹni Ikechuwu, ni ohun kan ṣoṣo to jẹ oun logun ju lọ bayii ni bi oun yoo ṣe ri oku ọmọ oun yọ jade ninu odo, ti oun yoo si le sin in nilana to tẹ oun lọrun.

O ni, ‘Inu mi ko dun rara pe latigba ti ọmọ mi ti ku, a ko ti i ri oku rẹ gbe jade. Ko sibi ta a ko ti i wa oku Chukwuemeka de, a ti de agbegbe kan bayii ti wọn n pe ni Alagboole, bakan naa la ti de Akintolu, koda a ti de Kara, ṣugbọn ko sohun to jọ ọ.

Lori ọrọ koto idaminu nla (Canal) to ṣeku pa oloogbe yii, awọn olugbe agbegbe naa to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe bii ẹni pe  ijọba fi koto idaminu ohun ṣe panpẹ iku fawọn olugbe agbegbe naa ni, nitori pe aburu to ti ṣe fawọn ti ju anfaani rẹ lọ bayii.

A gbọ pe gbogbo igba ti ojo nla ba ti rọ lagbegbe naa ni gbogbo awọn olugbe ibẹ ki i ni alaafia rara, ti agbara ojo aa si ya wọle wọn gidigidi. Iṣẹ aṣepati ti ijọba ṣe yii ko jẹ ki awọn araalu gbadun rara, ti wọn si lawọn ti ke si ijọba titi pe ki wọn waa ba awọn ṣiṣẹ naa pari ko too di pe ojo ọdun yii tun bẹrẹ, ṣugbọn ti wọn ko ti i wa.

Leave a Reply