Monisọla Saka
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn eeyan ṣi n lọ si ile olori ẹka iṣiro owo ni ọfiisi gomina ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Taiwo Oyekanmi, lati lọọ ba wọn daro iku ojiji to mu ẹmi ọkunrin naa lọ. Koda, Gomina ipinlẹ ọhun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, paapaa ti yọju si awọn mọlẹbi oloogbe naa lati ba wọn kẹdun ẹni wọn, to si ṣeleri pe awari ti obinrin in wa nnkan ọbẹ lawọn yoo fọrọ awọn to da ẹmi ọkunrin naa legbodo ṣe, nibikibi ti wọn ba si wa, awọn maa fin wọn jade bii okete to wa ninu isa ni.
ALAROYE gbọ pe awọn adigunjale bii marun-un kan ni wọn ran Oyekanmi sọrun apapandodo. Wọn ni owo ni ọkunrin naa lọọ gba ni ileefowopamọ Fidelity, kan niluu Abẹokuta, toun ko si mọ pe awọn ẹni ibi kan ti n ṣọ oun latigba to ti wa ninu banki ọhun. Bi oloogbe ti gba owo tan to n lọ lawọn ẹruuku ti wọn ti lọọ lugọ de e yọ si i lojiji labẹ biriiji Kutọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Awọn adigunjale ti wọn ni wọn n lọ bii marun-un yii ko beṣu-bẹgba ti wọn fi paaki ọkọ, ti wọn si yinbọn pa Ọgbẹni Taiwo lagbegbe Kutọ, ni wọn ba gbe gbogbo owo to gba sa lọ.
Ninu ọrọ ẹ, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abiọdun Alamutu, ṣalaye pe oloogbe, awakọ ati ẹni kan ni wọn jọ wa ninu mọto agboworin (bullion van) ọhun.
“O yẹ ki ọkọ ọlọpaa tẹle wọn, ṣugbọn nitori idi kan tabi omi-in, wọn fun ẹni yẹn laaye lati rinrin-ajo lọọ yanju awọn nnkan kan. Nitori bẹẹ ni ko ṣe ba wọn rin. Gẹgẹ bi ohun ta a gbọ, wọn ti gba owo tan, wọn si ti n pada si ọfiisi ki wọn too da wọn lọna.
“Mọto kan ni wọn lo da wọn lọna lori biriiji, awọn maraarun ti wọn wa ninu mọto ni wọn sọ kalẹ, bi wọn ṣe yinbọn lu Ọgbẹni Taiwo tan ni wọn gbe haama gbẹngbẹ kan jade lati fi fagidi fọ ilẹkun ibi ti wọn gbe owo si, wọn si gbe owo naa sa lọ.
“Ni gbogbo asiko ti wọn n ṣe eyi, ko si bi ọrọ naa ṣe fẹẹ de etiigbọ awọn agbofinro, ko si mọto awọn ọlọpaa to tẹle wọn titi tawọn olubi ẹda yii fi rọna sa lọ.
Awakọ awọn oloogbe naa tun ṣalaye pe oun tọpinpin wọn debi kan nitosi Conference Hotel, titi ti ko fi pada ri wọn mọ. Nigba ti wọn yoo si fi gbe oloogbe dele iwosan, ẹmi ti bọ lara ẹ”.
Alamutu fi kun un pe oun ti paṣẹ fun ọga ọlọpaa agbegbe naa lati gba gbogbo akọsilẹ ori kamẹra aṣofofo (CCTV) inu banki ọhu, nitori eleyii ni yoo jẹ kawọn ọlọpaa mọ iru mọto to jẹ. Ati lati da oju awọn eeyan naa mọ to ba jẹ pe wọn sọ kalẹ ninu mọto, tabi wọn o jade ti wọn fi rẹni ti wọn n wa.
“Mo ti kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko atawọn ibi kan lati di awọn ọna to gba ipinlẹ wọn jade, lojuna ati le ri awọn agbebọn ọhun, niwọn igba ti wọn ti ni marun-un ni wọn, aṣọ otutu ti wọn maa n da fila ẹ bori ni wọn si wọ’’.
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti ṣabẹwo sile oloogbe lati ba awọn mọlẹbi rẹ kẹdun iku eeyan wọn. Bakan naa ni Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Tokunbọ Talabi, Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Tokunbọ Talabi atawọn eeyan mi-in ti lọọ ki mọlẹbi Oyekanmi.
Awakọ ati ẹni kan yooku to wa pẹlu wọn ti wọn fara pa ṣi wa nileewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju.