O ma ṣe o! Awọn akẹkọọ imọ iṣẹgun oyinbo mẹta bomi lọ

Adewale Adeoye

Awọn ọmọ ogun oju omi orileede wa kan to wa lagbegbe Calabar, nipinlẹ Cross-River, ti sọ pe mọkanla lara awọn akẹkọọ iṣẹgun oyinbo kan ti ọkọ oju omi wọn danu lojiji lọjọ Abamẹta, Satidee, ọjọ kẹrinlegun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lakooko ti wọn n rinrin-ajo afẹ pẹlu ọkọ oju omi kekere kan lagbegbe ‘Marina Resort Jetty’, lawọn ti ri gbe jade laaye, nigba tawọn ṣi n wa awọn mẹta kan tawọn gbagbọ pe o ṣee ṣe ki wọn ti ku sinu odo naa.

Awọn akẹkọọ ti wọn ṣi n wa bayii ni awọn meji kan ti wọn jẹ akẹkọọ lati Ahmadu Bello University, ati ẹni kan lati University tiluu Uyo.

Awọn akẹkọọ iṣẹgun oyinbo ọhun la gbọ pe wọn waa ṣeto idanilẹkọọ pataki wọn, eyi ti wọn maa n ṣe lọdọọdun niluu Calabar. Kaakiri origun mẹrẹẹrin ilẹ yii si ni wọn ti kora wọn jọ fun eto pataki ọhun, eyi ti ẹka ilu Calabar gbalejo rẹ lọdun yii. Ṣugbọn nigba to ku diẹ ki wọn pari eto naa lawọn mẹrinla kan lara wọn sọ pe ki awọn gun ọkọ oju omi lati lọọ gbatẹgun leti ọsa.

Inu ọkọ oju omi kan ni gbogbo wọn wa lọjọ naa ti iji buruku kan bayii fi bẹrẹ, to si da ọkọ ti gbogbo wọn wa naa nu pata.

Ọpẹlọpẹ awọn ọmọ oju ogun omi ilẹ wa kan to wa nitosi ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ti wọn sare bẹ sodo ọhun lati doola ẹmi awọn akẹkọọ iṣẹgun oyinbo naa. Awọn mọkanla ni wọn ri ko jade ninu omi naa, nigba ti wọn ko ri awọn mẹta to ku ninu wọn ko jade rara titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ.

Ẹni kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa ṣalaye pe ibudokọ kan ti wọn n pe ni ‘Marina Resort Jetty,’ ni ọkọ oju omi awọn akẹkọọ naa ti gbera, to si n lọ si Tinapa, ṣugbọn ko pẹ rara ti wọn de aarin omi naa ti iji nla  kan fi bẹrẹ lojiji, eyi to mu ki ọkọ oju omi wọn danu lojiji, ti gbogbo awọn akẹkọọ mẹrinla ati awakọ wọn jọ ko sinu omi yii.

Leave a Reply