Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, eeyan mẹẹẹdọgbọn lo jona kọja idanimọ, ninu ijamba kan to waye ni adugbo Pẹ̀kẹ́, lagbegbe Oko-Olówó, Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii. Tanka epo kan ati bọọsi akero lo fori sọra wọn.
Alukoro ileeṣẹ panapana ipinlẹ naa, Hassan Hakeem Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii. O ni ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ni iṣẹlẹ buruku naa ṣẹ lagbegbe Oko-Olówó, niluu Ilọrin, nibi ti tanka epo kan ti nọmba rẹ jẹ JJN17XW pẹlu tirela to ko ẹru, to fi mọ ọkọ bọọsi akero elero mejidinlogun ti fori sọra wọn, ti awọn mejeeji si gbina loju-ẹsẹ. Eeyan mẹẹẹdọgbọn lo padanu ẹmi wọn sibi iṣẹlẹ naa, eeyan mẹẹẹdogun fara pa yannayanna, ti wọn si n gba itọju nileewosan bayii.
O tẹsiwaju pe iwadii fidi ẹ mulẹ pe lati ipinlẹ Niger, ni tanka epo yii ti n bọ, to si lọọ gba ọna ọlọna, eyi to fi lọọ fori sọ tirela akẹru to n bọ lati ilu Eko, tawọn mejeeji si gbina, to tun ran mọ bọọsi elero mejidinlogun to n lọ jẹẹjẹ rẹ.
Alukoro fun ajọ ẹṣọ ojuupopo nipinlẹ Kwara, Arabinrin Basambo, naa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ti ṣe gbogbo ohun to yẹ nipa kiko awọn to fara pa lọ sileewosan, tawọn si ti ko awọn oku lọ si mọṣuari.