Jọkẹ Amọri
Gbajumọ olorin asiko tawọn ọdọ fẹran daadaa nni, Habeeb Okikiọla ọmọ Ọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable Zaazu zeh, ti sọrọ lori bi ijamba ọkọ ṣe waye pẹlu mọto olowo nla rẹ tuntun to ṣẹṣẹ ra, G-Wagon, ti gbogbo imu mọto naa si run womuwomu.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun yii, ni Portable ni ijamba ọkọ, ori lo si ko o yọ nitori mọto naa bajẹ kọja afẹnusọ.
Ninu fidio to gbe sori ẹrọ ayelujara, to ti n sọ bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ, ibi to ti waye ati igbesẹ to kan, lo ti ni ọrọ aje loun n ba kiri toun fi ni ijamba, ati pe orin tuntun kan toun n po pọ lọwọ ni studio loun tori ẹ gbe mọto sọna nigba ti ijamba naa fi waye.
Portable sọrọ siwaju si i pe idi iṣẹ orin toun mọ lọna oun, orin toun si tori ẹ nijamba ọkọ yii naa ni yoo ra omi-in foun, ṣugbọn ti ko ni i mọ ni ẹyọ kan ṣoṣo lọtẹ yii mọ.
Ninu fidio ọkọ to fi nijamba lagbegbe Ọsapa London, Lẹkki, nipinlẹ Eko, ọhun lo ti ni ojo to n rọ lọwọ lo jẹ koun nijamba, oun ṣi nilo ẹmi oun loun ṣe yaa fi mọto ọhun silẹ, toun du ẹmi oun. Portable ni oun ti ṣetan lati ri i daju pe oun yoo kọle si agbegbe to gba mọto ọhun lọwọ ọhun.
Bakan naa ni ọkunrin ti o tun maa n pe ara rẹ ni Ika gbogbo Afrika yii tun kilọ fawọn ọta ẹ, atawọn alaroka lati dẹyin, nitori wọn o le ri oun pa. O ni afigba ti wọn ba gbin iṣu sunsun to ti jona daadaa ni wọn too le pa oun. O ni gbogbo awọn ti wọn n sọ pe mọto naa lo maa gbẹmi oun loju ti, nitori ko gba ẹmi oun. Niṣe ni gbogbo imu ọkọ naa bajẹ, to ri janganjangan, Ọlọrun lo si ko Portable yọ ti ko padanu ẹmi ẹ sinu ẹ.
Ninu fidio ọhun lo ti ni, “Awa o tun mọto ṣe o, a ma paarọ ẹ, ṣe ẹ gbọ. A maa ra omi-in. Iṣẹ ta a ṣe ta a fi ra iyẹn lo tun maa ra mi-in. A ṣẹṣẹ bẹrẹ ni o. mọto mi wọn ti fẹnu ba ti ara wọn jẹ o. Awọn Abatẹnijẹ, ẹ o le ba temi jẹ. Mo ra mọto, ẹ fẹnu wotowoto maa rojọ mọto mi, ẹ fẹnu ba mọto mi jẹ. Mọto yẹn o pada pa mi o, ṣe ẹ n gbọ. Wọn ni ẹẹn ṣe ẹ mọ pe oogun owo lọmọ yẹn ṣe, oun naa lo maa pa a. Oun ree o, mo n wa mọto ninu ojo, ojo lo gba a lọwọ mi ki i ṣe pe mo ti lo egboogi oloro lile kan o.
“Mo kan n lọ temi ni, koda gan-an, studio ni mo n lọ, ki i ṣe pe boya pe mo n lọọ ṣe nnkan ti ko daa. Lori atijẹ atimu yii naa ni. Ọrọ orin ni mo n ba lọ. Ninu orin yii naa ni ma a dẹ ti ri owo ra ilọpo mẹwaa mọto yẹn o. Ma a ra ọkọ oju ofurufu jẹẹti, ma a kọle, si Lẹkki ni o. Ọsapa London yẹn gangan, to gba mọto lọwọ mi dẹ ni ma a kọ ọ si.
“Iranṣẹ Ọlọrun dẹ lemi, wọn o le pa mi. Iku kan ko le pa mi, mo ti ni àpají, ṣe ọrọ mi ye yin. Tẹ ẹ ba gbagbe, ẹ lọọ ṣe àpají o, emi ti ni àpají. Ko o ma gbagbe, ko o ṣe apamajona naa mọ ọn, nitori ti wọn ba pa ẹ to o ku, wọn le lọ jo ẹ, nitori apajona naa wa. Mo ti ṣe awo ile aye, ko si nnkan kan o, mo ti di arọgidigba, ko si nnkan kan o. Iku Ọlọrun nikan ni, afi Ọlọrun nikan lo le sọ pe rara. Ọlọrun lo ni bẹẹ ni, Oun lo si ni bẹẹ kọ, ki i ṣe iru yin, o ti lọ bẹẹ yẹn. Ni ti mọto yẹn, mo maa ra omi-in.
Orin yẹn sẹẹ, a maa fi ra omi-in”.
Bo ṣe di pe Portable ni ki wọn ba oun tan orin toun n ṣiṣẹ lori ẹ lọwọ toun tori ẹ fi mọto jaamu niyẹn.
Ariwo pe o ku ewu yiyọ Ọlọrun lawọn eeyan n pa, awọn ololufẹ ẹ tubọ gbadura fun aabo Ọlọrun lori ẹmi ẹ.