Faith Adebọla
Oju bọrọ, ti wọn ni ko ṣee gbọmọ lọwọ ekurọ, ti waye latari bawọn ẹṣọ alaabo ipinlẹ Ogun kan, Social Orientation and Safety Corps, ti wọn n pe ni so-safe, ṣe padanu ọkan lara awọn oṣiṣẹ wọn, Saheed Ogunrinde, soju ija, nigba ti wọn lọọ gbena woju awọn afurasi ajinigbe ti wọn fori mulẹ sinu igbo nla to wa ni Orile-Imọ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ ọhun.
Ninu atẹjade kan ti Oludari eto iroyin fun awọn ẹṣọ ọhun nipinlẹ Ogun, Yusuf Moruf, fi lede lori iṣẹlẹ ohun lo ti sọ pe Ọjọbọ, Wẹsidee, to kọja, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn gba ipe pajawiri kan lọfiisi awọn to wa lagbegbe Orile-Imọ, pe awọn ajinigbe tun ti gbe iṣe wọn de, wọn ti paayan meji labule kan lagbegbe ọhun. Wọn ni nibi ti wọn ti n sọ eyi lọwọ lawọn tun gbọ pe awọn amookunṣika naa tun paayan meji mi-in l’Abule Awo, ti ko jinna sira wọn, wọn si ji awọn eeyan kan gbe wọ’gbo, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode yii kan naa.
Lọjọ keji, awọn ẹṣọ so-safe, eyi ti Oloogbe Saheed Ogunrinde lewaju fun dihamọra lati lọọ doola ẹmi awọn ti wọn ji gbe naa, wọn kori sinu igbo dudu tawọn afurasi ajinigbe yii fi ṣe ibuba wọn. Amọ gbogbo bi wọn ṣe pooyi to, wọn o ri wọn, wọn o si roye awọn ti wọn ji gbe rara.
Nigba to ya, awọn ikọ ọlọpaa kan lọọ kun awọn ẹṣọ yii lọwọ, wọn tubọ tẹpẹlẹ mọ iwadii ati ifimu finlẹ wọn, wọn si n fọ inu igbo naa daadaa. Ko pẹ ni wọn roye awọn atilaawi, wọn ri ipasẹ wọn, wọn si bẹrẹ si i tọpinpin wọn lọ.
Ṣe Yooba bọ, wọn ni a ki i gbọn bii ẹni to n ṣọ’ni, nibi tawọn ẹṣọ alaabo yii ti n fẹsọ lọ lawọn afurasi naa ti lọọ lugọ de wọn, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ, lọrọ ba di tau, tau, iro ibọn n dun lakọlakọ laarin awọn ọlọpaa atawọn ajinigbe.
Ibi ti eyi ti n lọ ni ọta ibọn awọn ajinigbe naa ti wọle si ọga So-Safe yii, Ogunrinde, lara, o si ba a nibi ti okun ẹmi ẹ wa. Niṣe lọkunrin naa ṣubu loju-ẹsẹ, wọn lẹjẹ to jade lara ẹ ti pọ ju, niku ogun ba pa akinkanju rẹ.
Wọn lawọn ajinigbe naa ni wọn kọkọ debi to ṣubu si, ti wọn si ji ibọn ati foonu rẹ lọ, ni wọn ba mori mu ṣinra sinu igbo dudu wọn.
Awọn agbofinro ni wọn palẹ oku ọkan lara wọn yii mọ, ti wọn si gbe e lọ sile rẹ to wa ni adugbo Ajura, ni Orile-Imọ, nibi ti wọn sin in si nilana ẹsin Musulumi.
Ọga agba ẹṣọ alaabo so-safe nipinlẹ Ogun, Sọji Ganzallo, ti ba’wọn mọlẹbi yii kẹdun pe Ọlọrun yoo tu wọn ninu, bẹẹ lo ṣeleri pe adiyẹ irana ni oro nla tawọn ajinigbe da yii, ki i ṣohun ajẹgbe fun wọn rara, tori awọn maa gbẹsan iku oloogbe naa lara wọn dandan.