O ma ṣe o, ile wo pa ọmọ ikoko ati iya rẹ l’Akurẹ 

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọ tuntun jojolo kan pẹlu iya rẹ ni wọn pade iku ojiji ninu iṣẹlẹ ile to da wo lagbegbe Ayedun, niluu Akurẹ, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala oṣu Kejila, ọdun 2023 ta a wa ninu rẹ yii.

ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ to gbomi loju ẹni ọhun pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kejila yii, ni wọn sọ ọmọ tuntun naa lorukọ, ṣugbọn ti iku wọle wẹrẹ mu ọmọ ọhun ati iya rẹ lọ lọjọ keji ti wọn sọ ọ lorukọ.

Tanki omi nla kan ti wọn gbe soke lẹgbẹẹ ile tawọn obi ọmọ naa n gbe lo deedee ja lojiji le ile wọn lori, leyii to ṣokunfa bi ogiri ṣe yẹ lu iya ọhun, awọn ọmọ rẹ meji, ati iyaaya ọmọ to waa ba wọn tọju ọmọ.

Wọn ni loju-ẹsẹ ni ọmọ tuntun ọhun ati iya rẹ ti ku, ti ẹgbọn ọmọ naa pẹlu iyaaya wọn si fara pa yannayanna.

Awọn ẹṣọ alaabo ni wọn pe lati waa gbe awọn to ku sinu ijamba ọhun lọ si mọṣuari, awọn naa ni wọn tun ṣeto bi wọn ṣe sare gbe awọn to fara pa lọ silẹ-iwosan ti wọn ti n gba itọju lọwọ lasiko ta a n ko iroyin yii jọ.

 

Leave a Reply