Monisọla Saka
Asiko yii ki i ṣe eyi to dara rara fun ọkan ninu awọn gbajumọ onifuji ilẹ wa nni, Alaaji Wasiu Alabi Ọdẹtọla Pasuma, tawọn eeyan tun mọ si Paso, tabi ọga nla Fuji, pẹlu bi iya to bi i lọmọ, Alhaja Adijat Kubura, tọmọ ẹ funra ẹ maa n pe ni iyawo Anabi, ṣe fi aye silẹ, to gba ọrun lọ nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Manigbagbe nirọlẹ Tọsidee yii jẹ fun Pasuma, pẹlu bo ṣe padanu iya rẹ yii, nitori o fẹran obinrin naa de gongo, o si mu iya naa ni pataki. Gbogbo itọju to yẹ ki obi fun ọmọ ni Pasuma fun iya rẹ yii nigba to wa laye, bẹẹ ni ki i wọn lọdọ rẹ nigba kọọkan. Bẹẹ lo maa n ki i kikankikan ninu awo orin rẹ, to si maa n pe ara rẹ ‘ọmọ iyawo Anabi’.
Pasuma funra ẹ lo kede iku iya naa lori ikanni Instagraamu rẹ. O kọ ọ sibẹ pe, ‘Ohun ẹṣọ iyebiye mi, mo maa ṣafẹri rẹ titi laelae ni. N ko tiẹ mọ ohun ti mo feẹ sọ. Maa sun ninu alaafia, jọwọ, maa mojuto mi lati ọrun wa’’.
Latigba ti Pasuma ti gbe ọrọ iku iya rẹ yii sori ikanni rẹ ni ọpọ eeyan ti n ba a daro, ti wọn si n ki i ku ara fẹra ku ti iya rẹ to faye silẹ ọhun.
Lara awọn to ti ranṣẹ ibanikẹdun si ọmọ iyawo Anọbi yii ni olorin fuji ẹgbẹ ẹ, Malaika, ẹni to kọ ọ pe, ‘Ọdọ rẹ la ti wa, ọdọ rẹ naa la oo pada si, a fẹ ọ, ṣugbọn Ọlọrun fẹ ọ ju wa lọ, ki Ọlọrun fun ọkan rẹ ni isinmi’.
Bakan naa ni aderin-in poṣonu nni, Mr Macaroni, kọ ọ ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ si Pasuma pe, ki Ọlọrun fun dun ọkan wọn ni isinmi, mo ranṣẹ ibanikẹdun si yin, Alabi Pasuma.
Baba Tee kọ ọ ni tiẹ pe, ’Hmmmm, Mama wa, mo dupẹ gidigidi fun adura tẹ ẹ gba fun mi nigba tẹ ẹ ba mi sọrọ gbẹyin lori foonu nipasẹ ọmọ yin. Ẹ maa sinmi ninu alijannah onidẹra. Toyin Adewale kọ ni tiẹ pe, ‘Haa, Ọlọrun o, Mo ba ẹ kaaanu fun ohun to o padanu yii, ki Ọlọrun fun ọkan rẹ ni isinmi’.
Bayii ni awọn alabaaṣiṣẹpọ ọkunrin olorin naa, awọn ọrẹ atawọn alatilẹyin rẹ ti n ki i pe o ku ara fẹra ku pẹlu
adura ati ọrọ iwuri lọlọkan-o-jọkan nipa mama to doloogbe ọhun.