Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Iyalẹnu nla lo jẹ fawọn eeyan ipinlẹ Ondo lati gbọ ikede iku kọmisanna mi-in ninu iṣejọba Gomina Rotimi Akeredolu lẹyin bii oṣu marun-un pere ti kọmisanna feto ilera, Dokita Wahab Adegbenro, jade laye.
Ọjọgbọn Bayọnle Ademodi to jẹ kọmisanna to n ri sọrọ ibaṣepọ to wa laarin ipinlẹ Ondo atawọn orilẹ-ede mi-in lagbaaye lo deedee fo sanlẹ, to si gba ọrun lọ nileewosan kan niluu Ọba.
Alaga afunsọ fun ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo tẹlẹ, Wale Akinlọsotu, lo kọkọ tufọ iku agba oloṣelu ọhun lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide.
Lati fidi iṣẹlẹ iku ọmọ bibi ilu Ondo ọhun mulẹ, Kọmisanna feto iroyin, Donald Ọjọgo, ti ranṣẹ ibanikẹdun sawọn ẹbi rẹ lorukọ Gomina Akeredolu.
Ninu ọrọ ibanikẹdun wọn, ẹgbẹ APC, ẹka tipinlẹ Ondo, juwe iku Ọjọgbọn Ademodi bii adanu nla fẹgbẹ wọn.