Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ijamba mọto to ṣẹlẹ lagbegbe Iwaraja, loju-ọna Ipetu Ijeṣa lọsan-an ọjọ Aiku ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti gbẹmi eeyan meji.
Alukoro fun ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe aago mẹta ku ogun iṣẹju niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
O ni mọto akoyọyọ kan ati Premia kan to ni nọmba WEN 397 AA, alawọ eeru, ni wọn fori sọra wọn lasiko ti taya ọkan fọ ninu wọn.
Ogungbemi fi kun ọrọ rẹ pe eeyan mẹrin; ọkunrin kan ati obinrin mẹta ti wọn jẹ ọmọde ni wọn fara pa nibi ijamba naa, nigba ti awọn ọmọdebinrin meji ku loju-ẹsẹ.
O sọ siwaju pe awọn ti gbe awọn ti wọn fara pa lọ si Wesley Guild Hospital, niluu Ileṣa, nigba ti awọn ti wọn jade laye wa nile igbokuu-si ileewosan naa.