O ma ṣe o! Maaluu kan akẹkọọ-jade fasiti pa

Monisọla Saka

Ọmọkunrin akẹkọọjade Fasiti ipinlẹ Kogi, Kogi State University (KSU), to wa niluu Àyìǹgbá, Felix, ti ṣe bẹẹ dagbere faye lẹyin ti maaluu kan an pa lori ọkada to wa.

Lọsẹ to kọja ni wọn ni ọkunrin naa ṣe idanwo aṣekagba nileewe giga KSU, to ti n kawe. Lasiko ajọyọ tawọn akẹkọọ maa n ṣe lẹyin idanwo ipari ẹkọ, ile ni wọn ni ọmọkunrin naa gba lọ lati lọọ yọ ayọ oriire ẹ fun awọn obi ẹ.

Wọn ni gareeji ti baba ẹ ti n ṣiṣẹ ọkada gigun lo gba lọ, niṣe lo si na fẹlẹfẹlẹ silẹ fun baba ẹ laarin awọn ero, to bẹrẹ si i dupẹ lọwọ rẹ fun gbogbo inawo ati igbiyanju baba yii latigba to ti bẹrẹ ẹkọ rẹ, titi to fi pari.

Boya lo ju ọjọ meloo kan lọ lẹyin to pari idanwo, to si lọọ dupẹ lọwọ baba ẹ ni gareeji wọn, ti maaluu kan to ja soju titi lojiji fi lọọ kan oun atawọn ọrẹ rẹ lori ọkada ti wọn n gun lọ.

Bi maaluu ṣe kan wọn yii lo mu ki ọkada wọn ni ijamba, gbogbo igbiyanju ni wọn ṣe lati pe ko gbadun, amọ ti Felix pada ku laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii.

Gẹgẹ bi oniroyin ori ayelujara kan, Ebira4real ṣe wi, o ni idunnu ṣubu lu ayọ fọmọ naa lọjọ to pari idanwo aṣekagba fasiti rẹ debii pe, bo ṣe ra igo waini kan tan lo mori le ibi ti baba ẹ wa. Ati pe iroyin bi ọmọ naa ṣe dọbalẹ to n dupẹ, to si n ṣadura fun baba ẹ gba ori ayelujara kan, ti gbogbo eeyan to ri i n ṣadura fun un pe  ọmọluabi to moore ni.

Amọ ko sẹni to mọ pe dugbẹdugbẹ iku n mi lori ẹ ni gbogbo igba naa.

Gbogbo igbiyanju to yẹ ni wọn ṣe lati du ẹmi Felix, amọ o pada ku.

Leave a Reply