Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, nibi ti ọlọpaa kan, Ọgbẹni Sunday, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Freedom, ti fi mọto to fi n le ọlọkada kan kiri nitori ẹgunjẹ to fẹẹ gba lọwọ rẹ pa akẹkọọ kan, Oloogbe Adelẹyẹ Ẹniọla, ti lawọn maa too bẹrẹ iwadii lori ọrọ ọhun, tawọn si maa foju agbofinro ọhun bale-ẹjọ lopin iwadii awọn.
ALAROYE gbọ pe akẹkọọ ọhun to jẹ ọmọ ileewe girama onipele agba kin-in-ni (SSI), nileewe giga kan ti wọn n pe ni ‘Mayigi Community High School’, to wa niluu Ilashe, nijọba ibilẹ Ipokia, nipinlẹ Ogun, pade iku ojiji lakooko ti ọlọpaa naa n fi mọto rẹ le ọlọkada kan nitori to fẹẹ gbowo lọwọ rẹ. Yatọ si oloogbe to ku sinu ijamba naa, awọn ẹlẹgbẹ oloogbe naa meji kan ti wọn wa lẹgbẹẹ rẹ lasiko ti wọn jọ n rin lọ wa nileewosan ijọba to wa lagbegbe naa, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ bayii.
Awọn araalu kan tiṣẹlẹ buruku ọhun ṣoju wọn ṣalaye pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti ọlọpaa ọhun to wa ni teṣan ilu Ilaro, nipinlẹ Ogun, maa fi mọto rẹ le awọn ọlọkada kaakiri igboro nitori owo to fẹẹ gba lọwọ wọn, ṣugbọn eyi to waye gbẹyin yii bu u lọwọ ni.
Ẹgbẹ awọn ọdọ kan, ‘Ipokia Local Government Youth Forum’ (IPYF), nijọba ibilẹ Ipokia, nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbofinro adugbo naa ṣe n ṣi agbara lo nigba gbogbo, paapaa ju lọ, bi wọn ṣe n sọ awọn araalu naa di alaabọ ara lọpọ igba.
Atẹjade kan ti Alukoro ẹgbẹ awọn ọdọ ọhun, Ọgbẹni Adeyẹmi Oluṣẹgun, fi sita nipa ọwọ lile tawọn ọlọpaa agbegbe naa fi maa n mu ọrọ awọn olugbe adugbo naa ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu. Wọn ni ọpọ igba ni wọn maa n fọwọ lile mu awọn ọdọ, ti wọn aa si tun yin taju-taju fun wọn bi nnkan kekere ba ṣẹlẹ laarin ọlọpaa atawọn ọdọ yii, to si jẹ pe ọpọ igba lawọn ọdọ ilu naa maa n ku.
Wọn ni apẹẹrẹ iru rẹ ni bawọn ọlọpaa ọhun ṣe tun kọju ija sawọn ọdọ kan ti wọn n ṣewọde lati fẹhonu han lori bi Freedom ṣe pa akẹkọọ kan laipẹ yii, ṣe ni wọn yin taju-taju saarin wọn, ti wọn si le gbogbo wọn danu pata. ‘‘Eyi ki i ṣe igba akọkọ rara tawọn ọlọpaa agbegbe wa maa ṣe bii pe awọn kọja ofin tabi pe ko sẹni to le ba awọn wijọ rara. Ọpọ igba ni wọn maa n tẹ ofin loju mọlẹ laduugbo wa, ti kinni kan ko si ni i ti idi rẹ yọ. Wọn aa gbegi dina loju titi, oju ki i ti wọn lati gba riba lọwọ onimọto, gbogbo ohun ti wọn n ṣe yii ki i ṣohun to daa rara’’.
Wọn ni niṣe ni ọlọpaa to waa pa akẹkọọ niluu naa kuro niluu Ilaro, nibi to ti n ṣiṣe, o si waa sijọba ibilẹ Ipokia, lati waa hu iwa laabi naa, nitori pe ko sẹni to n yẹ wọn lọwọ wo ni.
Lopin ohun gbogbo, ẹgbẹ yii ni ki wọn ṣawari Freedom, ki wọn foju rẹ bale-ẹjọ, ki wọn si fiya jẹ ẹ bo ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.