O ma ṣe o, ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa ku lojiji

Jọkẹ Amọri

Ninu ibanujẹ nla ni awọn mọlebi osẹre ilẹ wa nni, Kamal Adebayọ ti gbogbo eeyan mọ si Sir K wa bayii pẹlu bi agba oṣere naa ṣe ku lojiji. Ọkunrin to gbajumọ gidigidi laarin awọn oṣere ilẹ Yoruba to saaba maa n kopa janduku, to tun maa n sọ ede ilẹ okeere loriṣiiriṣii ninu ere, bii ko sọ ede India, ede China ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu fiimu yii lo dagbere faye lẹyin aisan ranpẹ.

Ọkunrin yii ti kọkọ figba kan lọ si orileede Amẹrika, nibi to gbe fun igba diẹ ko too pada wa si Naijiria, ti ko si fi bẹẹ kopa ninu ere mọ.

Sir K, bi gbogbo eeyan ṣe maa n pe e ni baba ọkan ninu awọn adẹrin-in poṣonu to maa n ṣe awọn ere keekekee ti wọn n pe ni (Skit), Abidemi Adebayọ ti wọn n pe ni beyubaebi.

Ko ti i ṣeni to mọ ohun to fa iku ọkunrin naa.

Latigba ti iroyin iku Sir K ti jade ni awọn oṣere ẹgbẹ rẹ ti n daro rẹ, ti wọn si gbe ọrọ aro si abẹ fọto rẹ lori Instagraamu wọn. Lara wọn ni Wumi Toriọla, ẹni to kọ ọ si abẹ aworan ọkunrin naa pe, ‘’Eleyii ba mi lojiji gidigidi, mo ṣi ri i ni ibi apejẹ kan laipẹ yii ti ko si soju pe yoo ku laipẹ rara, Ki Ọlọrun fun ọkan rẹ nisinmi, ko si fun awọn mọlẹbi rẹ ni ọkan lati mu adanu buruku naa mọra. O dun mi gidigidi, ṣugbọn ta lo le ba Ọlọrun wijọ, Alapadupẹ ni.’’

Bakan naa ni Doyin Kukọyi kọ ọ sori ikanni tiẹ pe ‘‘ki Ọlọrun Alagbara fun ọkan rẹ ni isinmi, Sir K. Haa, Oluwa o.

Yọmi Fabiyi kọ ni tiẹ pe, ‘’O digba kan na, Sir K Warrior, Sun un re o, ọga wa. Aarẹ mu ọkan mi.’’

Ninu oṣu Kẹjọ, ọdun to kọja, ni ọmọ re ti wọn n pe ni ọmọ rẹ, Abidemi Adebayọ ṣe ayeyẹ ọjọọbi ati imọyi fun baba rẹ yii.

Leave a Reply