Monisọla Saka
Oṣiṣẹ ẹṣọ alaabo oju popo ilẹ wa, FRSC meji kan ni wọn ti pade iku ojiji lẹyin ti tirela nla kan gba wọn loju ọna marosẹ Ikot-Ikpene si Aba, nipinlẹ Akwa-Ibom, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Bisi Kazeem ti i ṣe agbẹnusọ ajọ ọhun to fọrọ naa lede ṣalaye pe ere asaju ti awakọ tirela nla DAF naa n sa ni ko jẹ ko tete rina ri koto to wa laarin titi, bo si ṣe n gbiyanju lati pẹ koto naa kọja lo ya bara gba wọn danu, ti wọn si ṣe bẹẹ gbẹmi-in mi.
Adele olori ajọ FRSC, Dauda Biu, banujẹ lori iṣẹlẹ ijamba ojoojumọ to n mu ẹmi awọn eeyan wọn lọ latari iwakuwa ati ere asapajude awọn awakọ.
Lasiko to n kẹdun iku awọn ẹgbẹ ẹ meji yii lo ṣeleri pe gbogbo agbara to wa nikaawọ oun loun maa sa lati ri i daju pe ọwọ ba awọn ti wọn n huwa ọdaju naa, wọn yoo si foju wina ofin.
Ninu atẹjade ọhun ni agbẹnusọ wọn ti ni, “Ere asaju lo fa a ti awakọ naa ko ṣe tete ri koto to wa laarin ọna to n ba lọ, eyi lo si ṣokunfa ijamba naa. Ninu awọn iwadii ta a ṣe la ti mọ pe ijamba to mu ẹmi eeyan da ni yii tun pa ọkọ ti wọn kun ni ọda funfun tawọn ẹṣọ alaabo oju popo fi n yide kiri lara.
Ọkunrin agbalagba mẹjọ ni ọkọ naa rọ lu, awọn meji ninu wọn fara pa yannayanna, meji jade laye, awọn mẹrin yooku ko si fi ibi kankan ṣeṣe bo ti wu ko mọ.
Loju-ẹsẹ ni wọn ti gbe awọn meji ti wọn fara pa lọ sileewosan nla Ikot-Ikpene General Hospital, ti wọn si gbe awọn meji to ṣalaisi sile igbokuu-pamọ-si ile iwosan ọhun”.
Ọga agba ajọ Road Safety waa ranṣẹ ibanikẹdun si mọlẹbi awọn oloogbe ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn n sin ijọba lọwọ, bẹẹ lo rọ awọn araalu pe ileeṣẹ awọn o ni i tẹti, awọn yoo ri i daju pe ọwọ ba awọn awakọ ti wọn maa n wa iwakuwa, ti wọn ti fi iwa aibikita wọn pa ọpọlọpọ idile lẹkun.