Monisọla Saka
Ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Mu’azu Garba, ti ku sinu sọkawee ni Jigirya, nijọba ibilẹ Nassarawa, nipinlẹ Kano, lakooko to n gbiyanju lati yọ foonu rẹ to ja bọ nigba to n yagbẹ lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ panapana nipinlẹ naa, Alhaji Saminu Abdullahi, lo fọrọ ọhun lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Abdullahi ni ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, niṣẹlẹ buruku naa waye. “A gba ipe pajawiri latọdọ Abbas Abubakar ni nnkan bii aago meji ku iṣẹju mẹẹẹdọgbọn pe ọkunrin kan ti ko sinu sọkawee.
“Ọkunrin naa n gbiyanju lati yọ foonu rẹ to ja bọ sinu ṣalanga ni.
“Loju-ẹsẹ ni a sare ran awọn eeyan wa lọ sibi iṣẹlẹ ọhun ni nnkan bii aago meji ku iṣẹju mẹẹẹdogun lati doola wọn”.
O ṣalaye pe ọkunrin naa ti ku ki wọn too gbe e jade, wọn si ti gbe oku ọkunrin rẹ lọ si ọdọ olori agbegbe Jigirya, Alhaji Nuhu Adamu.
Abdullahi ṣalaye lẹkun-unrẹrẹ pe Garba n lo foonu rẹ lasiko to n lo ile igbọnsẹ ni, bi foonu ṣe yọ bọ lọwọ ẹ lo wọ inu ṣalanga lọọ mu un, ti ko si ribi jade sita mọ ko too di pe o gbẹmii mi.