Ọrẹoluwa Adedeji
Agbọ-sọgba-nu ni iku arẹwa obinrin olorin Islam to n ṣe daadaa nidii orin naa, Adukẹ Rukayyat Ọlabisi Kawat, ẹni ti awọn eeyan deede gbọ iku rẹ lojiji. Titi di ba a ṣe n sọ yii ni ọpọ eeyan ki si ti i gbagbọ pe ọmọbinrin olorin Islam naa ti ku. Ohun to jẹ ko ya ọpọ eeyan lẹnu, ko si jẹ ijọloju fun wọn ni pe ko sẹni to gbọ pe ọmọbinrin naa n saisan rara, iku rẹ ni wọn kan gbọ lojiji.
Rukayat yii ni ọmọ ọga oniroyin nni, Alaaji Gawat, to maa n ṣeto pataki kan lori tẹlifiṣan lasiko aawẹ. Ninu eto naa ni awọn eeyan ti maa n ko ọpọlọpọ ẹbun wa, to si maa n fun awọn to ba gba ibeere to ba bi wọn lasiko Rammadan.
Ṣugbọn lojiji ni wọn wa ọkunrin naa ti lọjọ kan ni ọdun diẹ sẹyin, ti wọn ko si ri i mọ. Ọkunrin naa jade nile, ṣugbọn alọ rẹ ni wọn ri, wọn ko ri abọ rẹ. Lẹyin ọjọ diẹ ni wọn ri ọkọ rẹ lẹgbẹẹ Third Mainland bridge. Titi di ba a si sẹ n sọ yii, wọn ko ti i ri ọkunrin naa.
Eyi lo mu inu ọpọ eeyan dun nigba ti Rukayat jade, to si n kọrin Islam. Ọkan ninu awọn orin to si gbe e si gbangba ni orin to kọ nipa bi baba rẹ ṣe di eni ti wọn ko ri mọ yii. Ojoojumọ lo si maa n jẹ ẹ lẹnu pe ki Ọlọrun ṣe baba oun ni riri. Afi bi wọn ṣẹ kede iku ọmọbinrin naa pe o ti jade laye.
Ko ti i sẹni to mọ ohun to ṣokunfa iku ọmọbinrin to lohun orin daadaa naa titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.
Lara awọn to ti fidi iku ọmọbinrin naa mulẹ ni Aafaa to fi ilu Ilọrin ṣebugbe nni, Alfaa Aribidesi. Bakan naa ni ọkan ninu awọn mọlẹbi ọmọbinrin olorin yii to tun jẹ oludamọran pataki fun gomina Eko, Jubril Gawat, fidi iku Rukayyat mulẹ pẹlu bo sẹ kọ ọ pe ‘’Ọdọ rẹ ni a ti wa, ọdọ rẹ naa la oo pada si.