O ma ṣe o, oludije sipo gomina lẹgbẹ LP tẹlẹ, Mike ku lojiji ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Irọ ni, ootọ ni, lo gbẹnu ọpọ olugbe ipinlẹ Kwara lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ yii, nigba ti wọn kede iku oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP), tẹlẹ nipinlẹ naa, Dokita Mike Omotoshọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ “Ọmọ to sure” ti wọn lo ku lẹni ọdun mejilelaaadọta (52), to si fi iya rẹ saye lọ.
ALAROYE gbọ pe alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni ọkunrin naa ku sileewosan kan ti wọn ko darukọ nilẹ Amẹrika, lẹyin aisan ranpẹ.
Mikẹ jẹ ọmọ bibi ilu Obo Ayegunlẹ, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, wọn bi i ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni, ọdun 1970, o ku ni ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Ọdun 2015, lo jade dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, to si gbe ipo kẹta nibi abajade esi idibo lọdun naa. Gbogbo awọn lookọ lookọ, awọn lẹgbẹ-lẹgbẹ, awọn oloṣelu ẹgbẹ rẹ, to fi mọ ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ ni Kwara, ni wọn ti n fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi oloogbe.

Leave a Reply