Jọkẹ Amọri
Inu ọfọ nla ni gomina ipinlẹ Nasarawa, Abdullahi Sule, wa bayii, pẹlu bi akọbi rẹ lọkunrin, Hassan Sule, ṣe ku lojiji lẹni ọdun mẹrindinlogoji, lẹyin aisan ranpẹ. Ni nnkan bii aago marun-un aabọ idaji ni wọn ni ọmọkunrin naa dakẹ si ileewosan aladaani kan ni ilu Lafia, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.
Akọwe iroyin gomina, Ibrahim Addra, lo kede iku ọmọ gomina yii ninu atẹjade kan to fi sita nipa iṣẹlẹ naa. Atẹjade naa ka pe, ‘‘Lorukọ gbogbo mọlẹbi ni Ọlọla Gomina Abdullahi A. Sule, ti i ṣe gomina ipinlẹ Nasarawa, fi kede ipapoda ọmọ rẹ, Hassan Sule, ẹni to ku ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lẹni odun mẹrindinlogoji.
‘‘Ni deedee aago mẹwaa ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn yoo sinku rẹ si Gudi, nijọba ibilẹ Akwanga, nipinjlẹ naa’’.
Ọpọ awọn oloṣelu atawọn eeyan nla nla ni wọn ti n ba gomina kẹdun iku ọmọ rẹ yii, ti wọn si n gbadura fun un pe Ọlọrun yoo rọ ọ loju, yoo si fopin si iru ajalu bẹẹ, yoo si tẹ ọmọ naa si alujanna onidẹra.