Monisọla Saka
Asiko yii ki i ṣe eyi to daa fun ọkan ninu aọn oṣere ilẹ wa to maa n ṣere oloyinbo, ti baba rẹ naa jẹ oṣere, Yul Edochie, pẹlu bi akọbi ọmọ rẹ lọkunrin, Kambilichukwu, ṣe fo sanlẹ to ku lojiji.
Laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn sare gbe ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogun ti i ṣe ọmọ gbajumọ onitiata naa lọ sileewosan, lẹyin ti wọn lo ṣubu nibi ti wọn ti n gba bọọlu.
ALAROYE gbọ pe ko si nnkan kan to ṣe ọmọkunrin to doloogbe ọhun rara. Wọn ni wọn n ṣedanwo lọwọ, ni oloogbe yii si kawe mọjumọ ni, ni igbaradi fun idanwo ti wọn fẹẹ ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Ẹni kan to sun mọ awọn mọlẹbi naa sọ pe aburo iya ọmọ naa ṣalaye pe lẹyin ti wọn pari idanwo tan loun pẹlu awọn ẹgbẹ ẹ bọ sori papa lati daraya. Ibi ti wọn ti n gba bọọlu lọwọ yii ni wọn lo ti ṣadeede ṣubu lulẹ, to si lọ rangbọndan bii ẹni ti giiri gbe. Loju-ẹsẹ ni wọn si ti gbe e lọ sileewosan ‘Mother and Child Hospital’. Gbogbo ipa tawọn dokita sa, lati ji ọmọ naa pada saye lo ja si pabo.
Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii oṣu meji si isinyii, lọmọ to faye silẹ yii ṣe ayẹyẹ ọjọọbi ọdun mẹrindinlogun laye. Yul ati May to jẹ iya ọmọ naa si ba a dawọọ idunnu lọjọ naa lọhun-un.
Ọpọlọpọ ọrọ ibanikẹdun lawọn ololufẹ tọkọ-taya yii ti kọ sori ẹrọ ayelujara lati ba wọn daro ọmọ wọn to ṣalaisi. Ṣugbọn iya ọmọ naa, May Edochie, ni aanu ọpọ eeyan ṣe ju, wọn lẹni to wa ninu ibanujẹ ti ọkọ ẹ da si i lara pẹlu bo ṣe fẹyawo mi-in le e lọsan-an kan oru kan, lọmọ tun fo ṣanlẹ to tun ku mọ ọn lọwọ yii.