Aderohunmu Kazeem
Ninu ibanujẹ nla ni gbajumọ olorin fuji nni, Kareem Ayinde Ọsọba, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Kabiesi Olomide wa bayii, iku ojiji lo pa ọmọ ẹ obinrin, Rachael Ọlamide Ayọka Ọsọba, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja.
Lori ẹrọ ayelujara Facebook ẹ, Kareem Ayinde Kabiesi, lo gbe ọrọ ọhun si, nibi tawọn eeyan ti n ba a kẹdun gidigidi.
Ohun ti ọkunrin naa kọ nipa ọmọ ẹ yii, Rachael Ọlamide Ayọka Ọsọba ko ṣai mu ọpọ eeyan ba a kẹdun gidigidi, ti wọn si n tọrọ wi pe ki Ọlọrun foriji ọmọ naa, ko si ba a da awọn yooku si.
Ohun ti Kabiesi Olomide kọ ree, “Rachael Ọlamide Ayọka Ọsọba, ala rẹ lati jẹ ojulowo ọmọ orilẹ-ede Nigeria yii ninu iṣẹ ọlọpaa ko le pada wa si imuṣẹ mọ.
“Lati le di ọlọpaa to yaranti lọjọ iwaju lo mu ẹ darapọ mọ ileewe Police Force Secondary School, n’Igbo-Ọra, nipinlẹ Ọyọ, nibi to o ti ṣẹṣẹ pari ipele akọkọ ẹkọ girama laipẹ yii. Ọjọ kẹrin, oṣu yii, naa lo pari idanwo rẹ, ti o si pada waa ba wa nile.
“Nigba to di Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii. lọwọ aarọ lo sọ pe ara n ro ẹ, loju ẹsẹ naa la si gbe ẹ lọ si ileewosan ijọba. Nigba to di Furaidee, ọjọ Ẹti, to tẹle e, funra ẹ naa lo ji, o gbadura gẹgẹ bii iṣe rẹ, bẹẹ lo bu omi sara, ti o si tun jẹ awọn eeso ti a ni nile, ṣugbọn lojiji ni gbogbo nnkan daru, ti a si sare gbe ẹ lọ si ileewosan Jẹnẹra n’Ifakọ Ijaye, nibi ti o ti mi eemi ikẹyin.
“Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ ileewosan naa gbiyanju agbara wọn, sibẹ, a fẹ ọ ni o, ṣugbọn Ọlọrun lo fẹ ọ ju, ki Ọlọrun ba mi tẹ ọ safẹfẹ rere, nigba ti a oo tun pade lọjọ ajinde…O daarọ, Ọla mi.”
Ohun ti gbajumọ olorin fuji yii, to tun jẹ ọkan pataki ninu awọn oloye ẹgbẹ PMAN, gbe sori Facebook ẹ ree, ti awọn eeyan bẹrẹ si ki i, ti wọn si n ba a kẹdun gidigidi.